Sunday 6 January 2019

Eégún Aláré


 Apá KINI



OJELARINNAKA ATI DASOFUNJO



Ní ìgbà àtijó,, eégún Alárè méjì kan wà ní Okeho (a kò mọ bí ti àtijó ni tàbí èyí tí ó wà báyìí lónìí) ni ilẹ̀ ìjọba Aláàfin Ọ̀yọ́, ọrẹ timotimo sì ni àwọn méjèèjì. Orúkọ ekinni a máa jẹ Òjé Larinnaka, tí èkejì a sì máa jẹ Dasofunjo. O se ni igba kan, Oje Larinnaka gbó pé are idán pípa kò wọ́pọ̀ ni apa ìlú kan, o si ro pe bí òun ba lo pidan fún wọn ní ibè, ọwọ òun yio ba ẹrú. Nípa bẹ́ẹ̀, ó pinnu ni ọkàn rẹ láti lọ sí ìlú náà dandan. Kí Oje Larinnaka to máa pale ìrìn-àjò maa mọ, ó fi lọ ọrẹ rẹ Dasofunjo, ó si gba a ní ìyànjú pé kí ó jẹ ki awon dijo lọ sí àjò náà:ṣùgbọ́n Dasofunjo so fún un pé òun kò ní lè lọ nitoripe idiwo ilé tí enia kò gbọ́dọ̀ fi silẹ lọ s'ajo poju f'oun. O wa gbàdúrà pé kí Ọlọ́run ṣamọ̀nà ọrẹ òun :kí ó lọ rere, kí ó bo rere Lehin àdúrà yi, Oje Larinnaka so fún ọrẹ pé òun yio tún de odò rẹ kì òun to lọ si àjò naa, òsì dìde lọ sí ilé rẹ. Bí ó ti délé ni ó so fun àwọn ẹbí àti aladugbo rẹ nípa ìrìn-àjò tí ó nlọ, o si tún sọ fún ìyàwó kansoso tí ó ní pelu. Ìyàwó rè náà tí a npe ni iyadunni tí lóyún sinú ni àsìkò yí. Bí ó ti sọ fún wọn tán ni o ba npalemo. Bí Oje Larinnaka tí palemo tán, ó padà lọ sí odò ọrẹ rẹ Dasofunjo láti dagbere fún un. Nigbati o de ọdọ rè tí ó sì dagbere fún un, Dasofunjo ba a damoran dáadáa, o si fún un ní ìwọ̀n nkan díẹ̀ tí ó mọ tí a fi ṣókùnkùn. Ṣùgbọ́n kí Oje Larinnaka to kúrò nílé ọrẹ rẹ, o be ẹ kì ó sójú-sehin f'oun nípa ti toju aya kansoso tí òun ní ti o lóyún sínú títí tí òun yio fi padà wálé wá mú u lọ bi àjò tí òun nlọ naa ba dára. Dasofunjo gbàdúrà kí Ọlọ́run jẹ ki àjò naa dára fún un, ó sì ṣèlérí pé òun yio maa se bí ó ti yẹ fún ìyàwó rẹ :ṣùgbọ́n ó te ẹ mọ ọrẹ rẹ naa létí pé kí ó má gbàgbé ilé, pàápàá kì ó rántí irú ipò tí ìyàwó rẹ wà pé ó lóyún sínú, kí ó sì tìtorí èyí tètè wá bẹ ilé wo bí o ba d'ajo tan. Lehin èyí, Dasofunjo sìn ọrẹ rẹ sónà :nigbati nwọn rìn díè nwọn bó ara wọn lọ́wọ́, onikaluku sì bá ọ̀nà tìrẹ lọ.

Ẹ darapọ̀ ni ọ̀la fún apá kejì.


Ẹnití ó kó jáde nínú ìwé ni Ọ̀gbẹ́ni Obey Adesoji.


 #ÈdèYorùbáRewà

Tuesday 27 February 2018

ÌDÚPẸ́

Kíni mo jẹ́?
Tani ni mí?
Tí Kò bá sí èyin, kò lè sí ojú ìwé #EdeYorubaRewa. Yorùbá bò wọn ní "Àgbáj'ọwọ́ la fi ń sọ̀'yà, Àjèjí ọwọ́ kan kò gbẹ́'rù dó'rí" Yorùbá tún sọ wípé "ọ̀pọ̀ èèyàn ní jẹ́ janmọ ẹnìkan kìí jẹ́ àwa de"leyi tí ó túmọ̀ sí wípé ọlá Ọlọ́run àti ọlá gbogbo olólùfẹ́ Èdè Yorùbá Rẹwà ni ó fún mi ní agbára láti máa ṣe ohun kékeré tí mò ń ṣe láti gbé èdè Yorùbá lárugẹ.... Mọ wá dúpẹ́ púpọ̀ lọ́wọ́ gbogbo àwọn tí wọ́n fẹ́ràn ojú ìwé #ÈdèYorùbáRewà àti àwọn tí wọ́n tẹ́lẹ̀ wa lórí ẹ̀rọ ayélujára Facebook, Twitter, Instagram, Blog àti WhatsApp,èdùmàrè ò ní paná ìfẹ́ wá.

Ẹ dákún mo rọ gbogbo òbí láti jé kí a fi èdè Yorùbá kó àwọn ọmọ wa láti lè gbé èdè wa lárugẹ, torí mò ń gbọ́ wípé èdè Yorùbá ò ní pé kú àti wípé wón ní àwọn òyìnbó aláwò funfun yíò máa kọ́ wa ni èdè wa leyi tí kò gbọdọ̀ ṣẹlẹ̀, ai mó wá ní ṣẹlẹ̀ rẹ̀ ó wà ní ọwọ́ ÈMI àti ÌWỌ.

Ní tèmi ń ò ní fi ọwọ́ òsì júwe ilé bàbá mi, ìwọ ńkọ́?
Ẹsẹ́ púpọ̀

Www.edeyorubarewa.com
Www.facebook.com/edeyorubarewa

#EdeYorubaRewa

Sunday 7 January 2018

Ìtàn Alarinrin apá kejì

ỌBA LÓ LADE. ÌJÒYÈ NÁÀ LÓ NI ILEKE. ITAN NTE SÍWÁJÚ.
ÀKỌLÉ ITAN: ṢỌ ẸRÚ KO

APÁ KEJÌ

Ibẹru bojo tí bàa gbogbo ara ilu ẹlẹgan, ṣe ogún ó dàbí ẹni ń jiyan, bẹ́ẹ̀ ni ó dàbí ẹni ń jẹka.
Are ni ajanimogun nilu ẹlẹgan,ọdẹ ni àmọ́ ọdẹ tí rẹ kì npa ẹkùn bẹ́ẹ̀ ni kí npa àgbọ̀nrín. Ọdẹ etile ló ńṣe bí kò pá Ọya, kò pá emo, kò sì de isa okete. Nígbà tó kú ọjọ marun kí àsìkò tí ìlú tẹrẹ dá fún ìlú ẹlẹgan pé, ajanimogun gbéra lọ bá àwọn ilumoye pé tí wọ́n bá lè gbà òun láyé, òun ṣetan láti lewaju ogún fún wọn, ó sì dájú pé ajaye ni òun yóò jagun náà.
Tika tẹgbìn ni àwọn olóyè wo ajanimogun, wọn ní bóyá ni nkan ó ti tà sì lọpọlọ. Abi báwo ni ọdẹ tí npa ẹmọ, Pa afé ṣe fẹ lọ koju ogún, oogun wo loni tí yóò fi jagun ọhun ni ajaye? Àbí torí kí ajanimogun lè d'oba ló ṣe ni òun fẹ lọ dojú kọ ogún?? Gbogbo ìbéèrè yìí ni àwọn olóyè nro lọ́kàn ara wọn,àmọ́ kò ye wọn.
Wọn ní kí ajanimogun sì máa lọ náà pé tí yóò bá fi di ọjọ́ kejì, àwọn yóò ti mọ̀ ibi tí àwọn yóò bá ìyára ja lórí ọrọ náà.
Lẹ́yìn tí ajanimogun kúrò lọdọ àwọn olóyè, iyalode ni kí wọ́n jẹ́ káwọn gba ajanimogun láàyè láti lọ jagun, bóyá eledua lè gbé ògo fún ọlẹ rẹ. To bá sì ṣe bẹ́ẹ̀ bá ogún lọ, a jẹ pe ohun ojú nwa lójú nri. Àwọn olóyè tó kú fara mọ èrò iyalode, wọn si pinnu láti tẹle aba rẹ.
Ní òwúrọ ọjọ kejì àwọn olóyè rán onise sì ajanimogun pé ìlú tí fara mọ èrò rẹ, wọn si ti gba pe ko lọ dojú kọ ogún fún wọn. Wọn súre fún pé yóò lọ rẹ, yóò sì bo rè. Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n tún fi ikilọ ati àdéhùn tí ọ̀rọ̀ wọ́n lẹ́yìn. Wọn ní bí ajanimogun bá kọ láti ṣẹ́gun pípa ni ilu yóò pá òun àti gbogbo ẹbi rẹ run,àmọ́ bí ó bá lè já ogún náà ni ajaye, àwọn yóò fi jọba ìlú ẹlẹgan tuntun.....
ṢE AJANIMOGUN YÓÒ ṢÍ LỌ SOJU OGUN PẸ̀LÚ ALAKALE TI ÌLÚ GBÉ SI NÍWÁJÚ BÁYÌÍ????
ITAN Ń TẸ ṢÍWÁJÚ

Ẹ fojú sọ́nà fún apá kẹta




Láti ọwọ́ Ọ̀gbẹ́ni Aremo Jah-Akewi


www.facebook.com/EdeYorubaRewa

#EdeYorubaRewa

Thursday 4 January 2018

Àkọlé ìtàn : ṢO ẸRÚ KO

ÀTI SE ÈÉ, Ó TI JINÀ.
Àkọlé ìtàn : ṢO ẸRÚ KO

APÁ KÌÍNÍ

Ojúmọ́ tí n mo, ooye tí bẹ̀rẹ̀ si ni là, ó ti ń bọ̀ sọ wo afemoju. Àwọn aráàlú elegan tí ń gbéra nílé láti gba ẹnu ìṣe wọn lọ, ṣe ìdí isẹ ẹni là tí ń mọni lole.
Bi àwọn èèyàn ti ń jí ni wọn bẹ̀rẹ̀ si ni gbo tí kowe nke labaadi. Bí ojúmọ́ ṣe ń mọ sì bẹẹ nígbè ẹyẹ yìí túbọ̀ n pọ sì. Ara bẹ̀rẹ̀ si fú àwọn aráàlú ohun lè mú kí kowe máa ké lafemoju. Se kowe ó kúkú nke lásán, ó ní láti jẹ pe ohun burúkú kan tí ṣẹlẹ̀ sí lu elegan ni.
Nígbà tí yóò fi di ÒWÚRỌ̀ kukutu, ní alago ọba bẹ̀rẹ̀ si ni lu aago, kaluku ń jáde wá gbọ ìṣe tí alaago náà fẹ jẹ́. Òfò ńlá tí ṣe ìlú elegan, àkùkọ tí kò lẹyin ọmọkùnrin alágbára. Alago jabo fún gbogbo ìlú pé kabiyesi àwọn, tí ńṣe ọba ọlọbẹ tí ìlú ẹlẹ́gan tí waja lóru mójú. Tori náà isede yóò wà fún odindi ọjọ méje láti ṣe oro fún ìsìnkú ọba. Gbogbo ìlú kan gogo nítorí ìròyìn láabi tí wọn gbo.
Àwọn ilumoye ṣeto bí wọn yóò ṣe fi ilẹ bo àṣírí òkú ọba, bí irun ti ń bo àṣírí orí.
Àdánù ńlá gbaa ni ikú ọba ọlọbẹ jẹ́ fún gbogbo ìlú ẹlẹ́gan pátápátá. Ìgbà ìṣàkóso rẹ tú t'onile t'alejo lára, eku nke bí eku, ẹyẹ nke bí ẹyẹ bẹẹ lọmọ ènìyàn ń fohùn bí èèyàn, amo ikú ṣe ká bo se fi ọba ọlọbẹ là gbogbo ìlú ẹlẹ́gan lójú.
Lẹyin oṣù kan tí ọba ọlọbẹ tí waja ni ilu tẹrẹ ranse ogún sì wọn, ṣe fami nfa ọ kúkú ti wá laarin ọba ìlú tẹrẹ yìí pẹlu ọba ọlọbẹ kò tó di pé ó waja. Èrò àwọn ilumoye tẹ́lẹ̀ ni pé bóyá ìlú tẹrẹ yóò jáwọ lórí ọ̀rọ̀ náà nígbà tí ọba ọlọbẹ tí waja, àmọ́ ibi tí wọ́n fojú sì ọ̀nà ó gbà ìbè, ó jọ bí ẹni pé ọrọ ti fẹ́ bá ẹyin yọ.
Ọ̀sẹ̀ mẹta péré ni ilu tẹrẹ fún ìlú ẹlẹ́gan láti lọ múra ogún silẹ, torí ìjà nbo kànnàkànnà ṣe tàn tó fẹ́ bo ẹyẹ ẹga. Àwọn ilumoye ṣètò pé kí àwọn ìdílé tó njẹ ọba fà ọmọ oyè silẹ, kí wọn lé yàn ọba èyí tí yóò lewaju ogún tó nbo lọ́nà. Àmọ́ kò sẹni tó yọjú.
Ọ̀pọ̀ lo wù kó joyè, àmọ́ aile fara ẹni jin ó jẹ ki ẹnikẹ́ni yọjú láti gorí apere bàbà rẹ. Mo ńbọ

ìtàn wá láti ọ̀dọ̀ Ọ̀gbẹ́ni Aremo Jah-Akewi

Ẹ fojú sọ́nà fún apá kejì.

www.facebook.com/EdeYorubaRewa

#EdeYorubaRewa


Thursday 14 September 2017

Ìjàpá àti ẹyẹ Àdàbà

Èyí ni Àlọ́ àpagbè fún gbogbo olólùfẹ́ ojú ìwé yìí, mọ lérò wípé ẹ ò gbádùn ẹ.

Àlọ́ oooo
Àlọ́ ọọọọ
Àlọ́ yìí dá lórí #ÌjàpáatiẹyẹÀdàbà

Gégé Bí ẹ̀yin náà ti mọ̀, alàgàbàgebè ni Ìjàpá, olè àti ọ̀kánjúwà ni pẹ̀lú. Ní ayé àtijó, Ìjàpá àti Ẹyẹ Àdàbà jọ ń ṣe ọ̀rẹ́. Àdàbà ni ẹṣin kan tí ó máa ń gùn kiri tí Ìjàpá kò sì ní nǹkankan. Ìjàpá ronú lọ́jọ́ kan, ó sì gbèrò bí yóò ti ṣe pa ẹṣin Àdàbà. Ó rí pé Àdàbà gbayì láàrin àwùjọ èyí tí kò dùn mọ̀ Ìjàpá nínú.

Nígbà tí ó di ọjọ́ kan Ìjàpá dá ọgbọ́n àlùmọ̀kọ́rọ́yín, ó pa ẹṣin Àdàbà. Àdàbà kò bínú sí kíkú tí ẹṣin rẹ̀ kú. Ohun tí ó ṣe ni pé ó gé orí ẹṣin náà ó bòó mọ́lẹ̀ ó wá fi ojú ẹṣin si ìta tí ènìyàn leè máa rí dáadáa. Bí Ìjàpá ti ń kọjá lọ ni ó rí ojú tí ó yọ síta. Eléyìí yàá lẹ́nu, kíá ó gbéra ó di ilé ọba. Nígbà tí ó dé ààfin, ó sọ fún ọba pé òun ti rí ibi tí ilé gbé lójú. Eléyìí ya ọba lẹ́nu, ó sì tún bí Ìjàpá bóyá ohun tí ó ń sọ dáa lójú. Ìjàpá sọ fún ọba pé ó dá òun lójú, ó sì tún wá fi dá ọba lójú pé bí kò bá rí bẹ́ẹ̀ kí ọba pa òun. Nígbà yìí ni ọba pe gbogbo àwọn ìjòyè àti ẹmẹ̀wà rẹ̀ pé kí àwọn lọ wo ibi tí ilẹ̀ gbé lójú. Ìjàpá ni ó síwájú tí ó sì bẹ̀rẹ̀ sí kọ orin báyìí pé;

Ìjàpá___________ Mo ti rí ibi ilẹ̀ gbé lójú
Agberin________ Ilẹ̀
Ìjàpá___________ Mo ti rí ibi ilẹ̀ gbé lójú
Agberin________ Ilẹ̀

Báyìí ni gbogbo wọn ń dá reirei lọ sí ibi tí ilẹ̀ gbé lójú. Bí Àdàbà ti gbọ́ ohun tí Ìjàpá ṣe yìí ni ó bá sáré lọ sí ibi tí ó bo orí ẹṣin rẹ̀ tí ó wó sí, ni ó bá wú orí náà kúrò lọ sí ibòmíràn. Nígbà tí ọba ìjòyè àti àwọn ẹmẹ̀wà dé ibi tí Ìjàpá wí, wọn kò rí nǹkan kan Ìjàpá bẹ̀rẹ̀ sí tú ilẹ̀ kiri títí kò rí ojú kankan. Ìgbà yí ni ọba bínú gidigidi pé Ìjàpá pa irú irọ́ tí ó tó báyìí àti pé ó tún da òun, àwọn ìjòyè àti àwọn ẹmẹ̀wà láàmú láti wá wo ohun tí kò sí níbẹ̀. Kíá ni ọba pàṣẹ pé kí wọn ó ti ojú Ìjàpá yọ'dà kí wọn ó ṣì ti ẹ̀yìn rẹ̀ kì í bọ àkọ̀.Eléyìí jásí pé wọn paá. Báyìí ni Ìjàpá fi ìlara pa ara rẹ̀.

#EdeYorubaRewa

Àlọ́ àpagbè

Àlọ́ àpagbè míràn fún gbogbo olólùfẹ́ ojú ìwé yìí. Mo lérò wípé ẹ ò gbàdúrà e
Àlọ́ oooo
Àlọ́ ọọọọ
Àlọ́ yìí dá lórí #ẸkùnàtiIkùn

Ní ìlú àwọn ẹranko, kìnnìún ni Ọba wọn. Nígbà tí ó di ọjọ́ kan, Ọba ẹranko pe gbogbo àwọn ẹranko jọ, ó sọ fún wọn pé òun fẹ́ dá ọjọ́ tí àwọn ẹranko yóò wa ṣe eré fún òun. Ó sọ pé ẹni tí ó bá lu ìlù dáadáa òun yóò da lọ́lá. Nítorí ìdí èyí ó ní kí ẹranko kọ̀ọ̀kan lọ kan ìlù. Gbogbo àwọn ẹranko gbọ́ ọ̀rọ̀ Ọba, wọ́n dárí lọ sí ilé wọn. Ẹni kọ̀ọ̀kan nínú àwọn ẹranko ń gbìyànjú à ti kan ìlù. Ṣùgbọ́n dípò kí ẹranko kan tí orúkọ rẹ ń jẹ ikún ó kan ìlù tie, ní ṣe ni ó lọ gbé ìlú ẹkùn níbi tí ẹkùn gbé e sí. Ẹkùn bẹ̀rẹ̀ sí wa ìlú rẹ, ó wàá títí kò ri. Nígbà tí ó di ọjọ́ aré, ẹkùn jí ni kùtùkùtù ó lọ dúró ní ọ̀nà tí ó lọ sí ilé kìnnìún ọba ẹranko. Bí ẹranko kọ̀ọ̀kan bá ti fe kọjá ni ẹkún yóò yọ sí i tí yóò sì sọ pé kí ó lu ìlù rẹ̀ kí òun gbọ́. Orin ni ẹkún fi ń sọ eléyìí fún wọn tí orin náà sì lọ báyìí :

Ẹkùn________ Ríkíríkijàn
Agberin_____ Àríkijàn
Ẹkùn________Ríkíríkijàn
Agberin_____Àríkijàn
Ẹkùn________ Ọba ló dájọ́ aré
Agberin_____ Àríkijàn
Ẹkùn________ Ọba ló dájọ́ ayò
Agberin_____Àríkijàn
Ẹkùn________Wọ́n ní á kànlù, mo kànlù
Agberin_____Àríkijàn
Ẹkùn________ Mo gbé ìlú mi s'àgbàlá
Agberin_____ Àríkijàn
Ẹkùn________ Ọmọ ẹranko gbé e lọ
Agberin_____Àríkijàn
Ẹkùn________ Lùlù rẹ kí n gbọ́
Agberin_____Àríkijàn
Ẹkùn________Lùlù rẹ kí n mọ
Agberin_____Àríkijàn
Ẹkùn________ Papakúkú rangbọndan
Agberin_____ Àríkijàn
Ẹkùn________ Papakùkù rangbọndan
Agberin_____ Àríkijàn
Ẹkùn________Ìlù mi kọ́ùn ni
Agberin_____Àríkijàn
Ẹkùn________ Rékọjá o máa lọ
Agberin_____Àríkijàn

Báyìí ni ẹranko kọ̀ọ̀kan ṣe ń kọjá tí ẹkùn sì ń kọ orin bákan náà. Nígbà tí ó kan ikùn láti kọjá, ẹ̀rù ti bẹ̀rẹ̀ sí bàa. Ẹkùn tún bẹ̀rẹ̀ orin rẹ̀ :

Ẹkùn________ Ríkíríkijàn
Agberin_____ Àríkijàn
Ẹkùn________Ríkíríkijàn
Agberin_____Àríkijàn
Ẹkùn________ Ọba ló dájọ́ aré
Agberin_____ Àríkijàn
Ẹkùn________ Ọba ló dájọ́ ayò
Agberin_____Àríkijàn
Ẹkùn________Wọ́n ní á kànlù, mo kànlù
Agberin_____Àríkijàn
Ẹkùn________ Mo gbé ìlú mi s'àgbàlá
Agberin_____ Àríkijàn
Ẹkùn________ Ọmọ ẹranko gbé e lọ
Agberin_____Àríkijàn
Ẹkùn________ Lùlù rẹ kí n gbọ́
Agberin_____Àríkijàn
Ẹkùn________Lùlù rẹ kí n mọ
Agberin_____Àríkijàn
Ẹkùn________ Papakúkú rangbọndan
Agberin_____ Àríkijàn
Ẹkùn________ Papakùkù rangbọndan
Agberin_____ Àríkijàn
Ẹkùn________ ìlù mi nùnun nì
Agberin_____ Àríkijàn

Bí ikùn tí gbọ́ pé ìlù ẹkùn ni òun gbé lọ́wọ́, pẹ̀ẹ̀ lójú ìlù sílè tí ó bẹ̀rẹ̀ sí sá lọ. Ẹkùn gbá tẹ́lẹ̀e,ṣùgbọ́n bí ẹkùn ṣe ni kí òun ó ki ikùn mọ́lẹ̀ ni ó ṣá wọ inú ihò lọ. Ikùn kò lọ láì f'arapa, èékánná ẹkùn ha ikùn ní ẹ̀gbẹ̀ méjèèjì. Bí ènìyàn bá rí ikùn lónìí, yóò rí pé ilà funfun wà ní ẹ̀gbẹ̀ méjèèjì ikùn di òní olónìí yìí o. Olè jíjà kò dára oooo

#EdeYorubaRewa