Tuesday 22 November 2016

Orin Ìbejì

Ẹepo ńbe
Ẹ̀wà ńbe oo
Ẹepo ńbe
Ẹ̀wà ńbe oo
Àyà mi o já ooo ee
Àyà mi o ja lati b'ìbejì o
Ẹepo ńbe ẹ̀̀wà ńbe oo.

Edun ló ní njó,
Mo jó,
Èmi kò lè torí ijó
Kọ edun
Edun ló ní n jó,
Mo jo

Owó mi méjèèjì mo fí gbé ìbejì,
Owó mi méjèèjì mo fí gbé ìbejì,
Ẹnikan kìí fowó kan gbé ìbejì,
Owó mi méjèèjì mo fí gbé ìbejì.

Èdùmàrè fún wa lọmọ bíi ìbejì bí, kí gbogbo ọmọ tí a bí dàgbà kí wọn dògbó....

Àmín Àṣẹ Èdùmàrè.....

https://chat.whatsapp.com/Fb7Vz4kj9WlIunYKtIhmwu

Thursday 3 November 2016

Bójú Bóra

Ọ̀rọ̀ kan gbé mi nínú,
Tí mo fẹ́ kẹ bámi dá sí,
Kí gbogbo mùtúmùwà fetí gbéyàwó ẹ,
Ọ̀rọ̀ àwọn ọmọge tó ń bójú Bóra,
Ló fa ariwo,
Ìyàwó adúláwọ̀,
Tó fẹ́ para rẹ̀ láwọ̀dà,
Bí wọ́n bá bàwó jẹ́ tán,
Wọ́n á wá fín pátápátá,
Ọsẹ abójú ni wọ́n ń wá kiri,
Atíkè abàwọ̀jẹ́ ni wọ́n ń lò lọ́pọ̀ ìgbà,

Wọ́n kìí dúró bí Ẹlẹ́dàá ṣe dá wọ́n,
Ń ṣe ní wọ́n ń bàwọ̀ jẹ́,
Ọ̀pọ̀lọpọ̀ làwọn òbí ò dà mọ̀ mọ́,
Nítorí ìgbà t'ọmọ ó kúrò nílé,
Ń ṣe ló dúdú bíi kóró isin,
Ìpadàbọ́ Odùduwà rèé,
Ọmọ tí d'òyìnbó atọwọdá,
Ojú lójú "kóòkì" ẹsẹ̀ lẹsẹ̀ "fàntà",
Oòrùn ti ń jáde lára wọn kò lẹ́gbẹ́,

Ní ìgbẹ̀yìn Ayé abójúbóra,
Kii suwòn,
Kí ǹkan má ṣe ara wọn ni
Búté búté ni ara wọn yíò má já,
Mo rọ gbogbo ọmọge adúláwọ̀ kí á wà bí èdùwà ṣe dá wa.

#Mosọyí, #modúrónaa.

Mo sì dúpẹ́ Púpọ̀ lọ́wọ́ #Ẹlẹ́dàá tó dá mi sí ilé #Adúláwọ̀,

#Ìwońkọ

https://instagram.com/edeyorubarewa

https://twitter.com/edeyorubarewa

https://facebook.com/edeyorubarewa

https://chat.whatsapp.com/Fb7Vz4kj9WlIunYKtIhmwu

https://edeyorubatiorewa.blogspot.com.ng/

Wednesday 2 November 2016

Ta ló fẹ́ni dénú

Onílé apá ọ̀tún ò fojú irẹ woni,
Ìmọ̀ràn ìkà ni tòsí ń gbà,
Kájáde Kájáde ni tọ̀ọ́kan ile ń wí,
Ọmọ Adámọ níí fẹ̀jẹ̀ sínú,
Tutọ́ funfun bàláú jáde,
Bí wọn rí o lókèèrè,
Ti wọn pọ́n ọ́ lè tẹ̀ríntẹ̀yẹ̀,
Ohun ti ń bẹ nínú wọn,
Ó kọjá àpèjúwe,
Bí a bá ṣí inú ẹlòmíràn,
Ejò ṣèbé, ọkà, àkeekèé,
Agbọ́n, oyin tamo ṣánkọ,
Pẹ̀lú ọ̀pọ̀ ohun olóró mìíràn,
Là bá níkùn ọmọ ènìyàn,
Ṣùgbọ́n inú kìí ṣegbá,
Ojú lásán la rí,
Ọrẹ ò dénú,
Sàṣà èèyàn ni i féni lẹ́yìn,
"Bá ò sí nílé, tajá tẹran ni i fẹ ni lójú ẹni"
 Inú mi ni mo mọ
Ń ò mọ tẹlòmìíràn...

#Ìwo ń kọ́

https://instagram.com/edeyorubarewa

https://twitter.com/edeyorubarewa

https://facebook.com/edeyorubarewa

https://chat.whatsapp.com/Fb7Vz4kj9WlIunYKtIhmwu

https://edeyorubatiorewa.blogspot.com.ng/

Tuesday 1 November 2016

Ewì ìkìlọ̀

Ikú ń pa alágẹmọ,
Tí ń yọ́ rin lórí ewé,
Ambèlètasé ọ̀pọ̀lọ́,
Tí ń jan ara rẹ̀ mọ́lẹ̀,
Ẹ̀sọ̀, ẹ̀sọ̀ láyé gbà,
Ìgbìn ò lápá,
Bẹẹ ni kò lẹ́sẹ̀,
Ẹ̀sọ̀, ẹ̀sọ̀ n'ìgbìn mà ń gun igi,
Yorùbá bọ̀, wọn ní "ohun a Fẹ̀sọ̀ mú ki í bàjé, ohun a fagbára mú kokoko ni le bí ojú ẹja"
Ẹ jẹ́ ká Fẹ̀sọ̀ ṣe,

Àwa èwe ìwòyí,
Màriwò to yọ láì yọ,
Tó lóhùn o kan ọrùn,
Ẹ jẹ́ ká bí í léèrè,
Bóyá ìran bàbá rẹ ṣe bẹ́ẹ̀ ri,
Ẹ̀sọ̀, ẹ̀sọ̀ láyé gbà,
Nítorí igbá pẹ̀lẹ́ kìí fọ́,
Àwo pẹ̀lẹ́ kìí fàyá,
Ẹ̀sọ̀ láyé gbà,
Ọmọ ìyá à mi tí ó jé Yorùbá ẹ jẹ́ ká máa fi ẹ̀sọ̀ ṣe,
Ìṣó Ọlọ́run a má wà pẹ̀lú wá ní gbogbo ìgbà...

#ÀmínÀṣẹÈdùmàrè

https://instagram.com/edeyorubarewa

https://twitter.com/edeyorubarewa

https://facebook.com/edeyorubarewa

https://chat.whatsapp.com/Fb7Vz4kj9WlIunYKtIhmwu

https://edeyorubatiorewa.blogspot.com.ng/

Thursday 20 October 2016

Oríkì Ìkòyí

Oríkì Ìkòyí

Ìkòyí èshó,
Ọmọ agbọn iyùn,
Ogun ajaaiweeyin lọ meso wù mí,
Ogun ojoojumo lo mú kilee wọn sú mí lọ,
èshó kí gba ọfà lẹ́yìn,
Gbangba iwájú ni wọn fí gbaọta,
Ọmọ oni Ìkòyí akoko,
Èyin lọmọ àgbà tín yàrun ọ̀tẹ̀,
Ọmọ ogun lérè jọjà lọ,
Ìkòyí ọmọ Aporogunjo,
Ìkòyí gbéra ń lé ó dìde ogun yá,
Ọjọ́ Kínní tó nìkòyí kú,
Ṣùgbọ́n mo kúrò lọmọ agbekórùn lọ oko,
Wọn gbélé wọn bo onìkòyí
Àgbède gbede onìkòyí lọ sùn ibè,
Àtàrí onìkòyí Kò sún ibè,
Àwọn lọmọ aṣíjú àpò piri dàgbà ọfà sọ fún,pofún yóò yọ dàgbà ọfà sile,
Ọmọ aku fepo tele koto,
Ọmọ igunnugun balẹ̀ wọn a jori akalamagbo balẹ̀ wọn a jẹdọ.

Èdùmàrè dá ìlú Ìkòyí sí oooo.

http://www.facebook.com/edeyoruba26
http://www.twitter.com/edeyoruba26
http://www.instagram.com/edeyoruba26
https://chat.whatsapp.com/Fb7Vz4kj9WlIunYKtIhmwu

Saturday 15 October 2016

Ìyá

Ìyá ni wúrà

kíni ọmọ le ṣé lálá sì ìyá,
Iyá tí ó lóyún fún oṣù mẹsan,
Ní ìbẹ̀rẹ̀ oyún ìyá o le jẹ, kólé mú, kò lè sún bẹẹ ni ko leè wo,
Bí oyún ṣe ń dàgbà ní òun ti ńṣe ìyá yí padà ní gbà míràn oyún a sọ pé ìwọ ìyá yí jókòó,
 Bí ìyá kọọ ìnira dé, ipa pàtàkì ní ìyá kó lára ọmọ,
Bí ìyá tún bí ọmọ sáyé tán ìṣe ṣẹ̀ṣẹ̀ bẹ̀rẹ̀,
Bí orí fọ ọmọ ìyá lo nfo,
Bí ara dùn ọmọ ìyá lo ndun,
Bí ọmọ bá sunkún lọ gaju òru ìyá gbé sì ibadi yio sí má jo lairi ìlù,
Bi ọmọ sunkún jù wàá gbọ́ tí bàbá a wípé ọmọ rẹ sunkún dáa lóhùn,
ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìyá ní yio gba aaru kí ọmọ lè bá jẹ́ ènìyàn,
Wúrà tí owo kòlè rà ni ìyá jẹ́,
kò sì òun ti o leè ṣẹlẹ̀ ìyá mi ni ìyá mi,
Kódà kí o ma já itó ìyá mi ni ìyá mi,
Kódà bí ó má bu igi jẹ ìyá mi ìyá mi ni gbogbo ìgbà.
Ìyá ni wúrà iyebíye tí owó kò lè rà.
Kí Ẹlẹ́dàá jẹ kí gbogbo ìyá wá pé fún wá Àmín oooo
Àwọn tí wọn kò sì ní ìyá láyé mọ kí Èdùmàrè jogún ẹni tí yíò ṣe ìyá fún wọn. Kí Èdùmàrè fi ọ̀run ké àwọn ìyá tí ó ti kú.

#ÀmínÀṣẹÈdùmàrè





http://www.instagram.com/edeyoruba26
http://www.facebook.com/edeyoruba26
http://www.twitter.com/edeyoruba26
https://chat.whatsapp.com/Fb7Vz4kj9WlIunYKtIhmwu

Saturday 1 October 2016

Orílè èdè Nàìjíríà

Muso muso muso orílè èdè Nàìjíríà pé ọdún merindilogota aráyé ẹ bá wa jó aráyé ẹ bá wa yọ.
Orílè èdè Nàìjíríà, orílè èdè abínibí mi, ó pé ọdún merindilogota tí a ti gba òmìnira kúrò lọ́wọ́ òyìnbó amúnisìn, nínú to lórí tẹlémù ló ń dùn. Àwọn òyìnbó gbẹ́ ọ̀pá àṣẹ fún ologbe Tafawa Balewa, ṣùgbọ́n pẹ̀lú ẹ̀ta inú àti Áì sọ̀kan gbogbo ọmọ orílè èdè Nàìjíríà a kò fi bẹẹ ni ìlọsíwájú ní orílè èdè wa. Gbogbo àwọn tí wọn ṣe tán láti jẹ kí orílè èdè Nàìjíríà tẹsíwájú pípa ni àwọn ọ̀tá ìlọsíwájú ń pá wọn. Àwọn èèkàn ńlá ńlá tí wọn jẹ kí a gba òmìnira kúrò lọ́wọ́ òyìnbó amúnisìn ni
Ọbafemi Awolowo, Ahmadu Bello, Anthony Enahoro, Nnamdi Azikuwe, Tafawa Balewa pẹ̀lú Sámúẹ́lì Ladoke Akintola àti bẹẹ bẹẹ lọ?
Tí ó jé wípé ohùn tí gbogbo àwọn wọ̀nyí ni lọ́kàn kí a tó gba òmìnira ní gbogbo àwọn tí wọn dárí wá ní gbogbo ohun tí ó ṣẹlẹ̀ sí wa yí kò ní ṣẹlẹ̀, ṣùgbọ́n kò sí ẹnì tí ó ma fi ọbẹ̀ tónu je ìṣù.
Kò ti peju láti yi gbogbo nǹkan padà, ṣùgbọ́n láti yí padà ó wà lọ́wọ́ èmi àti ìwọ, ẹ má jẹ́ kí a má sọ wípé mio fẹ́ràn òsèlú nítorí pé tí àwa ti a rò wípé a lè tún ṣe bá ń sọ wípé mi o fẹ́ràn òṣèlú àwọn tí ó bàjé lá má dibo fún pẹ̀lú èyí kò ní sí ìlọsíwájú ní orílè èdè Nàìjíríà wá.
Láti tún orílè èdè Nàìjíríà ṣe ọwọ́ tèmi àti tiẹ̀ ló wà.
A kú ọdún ayajo òmìnira ọ̀pọ̀lọpọ̀ ẹ laa ṣe ooooo
Dìde ẹ̀yin ará
Wa jepe Nàìjíríà ,
ka fife sinlee wa,
pekókun àtigbagbọ ,
kíṣé àwọn akọni wa,
ko ma se ja sasan,
kà sin tọkàn~tara,
Ilé tòmìnira ,
àlàáfíà sọ dòkan
Mo ṣe ìlérí fún Orílẹ̀ -Èdè mi Nàìjíríà,
Láti jẹ olódodo,
Ẹniti ó ṣeé fọkàn tán,
Àti olotito èniyàn,
Láti sìn pẹ̀lú gbogbo agbára mi,
Láti sa ipá mi gbogbo fún Ìsòkan re,
Àti láti gbe e ga fún iyì àti ògo re.
Kí olúwa kí ó rán mi lọ́wọ́. (Àmín)

Tuesday 27 September 2016

Ìlà

Ẹkasan gbogbo olólùfẹ́ ojú ìwé yìí, kini waa ṣe tí o bá àwọn ọmọ rẹ pẹ̀lú ìlà lójú wọn?

Friday 9 September 2016

Ìbàdàn tí ó jalè ojú ni ó ń rọ́

Ní ayé àtijó bí ìtàn ṣe sọ fún wa, Ìbàdàn jẹ́ ìlú tí ó gba onílé àti àlejò mọ́n, fún ìdí eléyìí àwọn ọrẹ mẹ́ta kan wà, ìkan jẹ́ ọmọ Ìbàdàn àwọn méjì tó kù ọmọ ìlú mìíràn.

Àwọn méjèèjì tó jẹ́ ọmọ ìlú mìíràn lọ ebi pa wọn, wọn si lọ jalè, àṣírí bá tú, wọn mú wọn,àwọn ènìyàn sii bí wọn pé kini wọn rí lóbè ti wọn fí garo ọwọ́, wọn si dáhùn wípé nkan ó senu rẹ fún àwọn, pé ebi pa àwọn, àwọn ènìyàn sii bí wọn pé ẹni kẹta yín ń kó tí ohun je ọmọ Ìbàdàn, wọn si dáhùn wípé ìyà ń jẹ ohun náà ṣùgbọ́n ohun #rójú ni.

Èyí ni wọn sọ súnkì, tí wọn sì sọ di ara oríkì tí wọn fi ń kí Ìbàdàn pé #Ìbàdàntíojalèojúníńrọ́

Oríkì Ìbàdàn

Ní ayé àtijó bí ìtàn ṣe sọ fún wa, Ìbàdàn jẹ́ ìlú tí ó gba onílé àti àlejò mọ́n, fún ìdí eléyìí àwọn ọrẹ mẹ́ta kan wà, ìkan jẹ́ ọmọ Ìbàdàn àwọn méjì tó kù ọmọ ìlú mìíràn. 

Àwọn méjèèjì tó jẹ́ ọmọ ìlú mìíràn lọ ebi pa wọn, wọn si lọ jalè, àṣírí bá tú, wọn mú wọn,àwọn ènìyàn sii bí wọn pé kini wọn rí lóbè ti wọn fí garo ọwọ́, wọn si dáhùn wípé nkan ó senu rẹ fún àwọn, pé ebi pa àwọn, àwọn ènìyàn sii bí wọn pé ẹni kẹta yín ń kó tí ohun je ọmọ Ìbàdàn, wọn si dáhùn wípé ìyà ń jẹ ohun náà ṣùgbọ́n ohun #rójú ni. 

Èyí ni wọn sọ súnkì, tí wọn sì sọ di ara oríkì tí wọn fi ń kí Ìbàdàn pé #Ìbàdàntíojalèojúníńrọ́

Ìdánwò

Ẹkú dédé àsìkò yìí gbogbo olólùfẹ́ èdè Yorùbá

Ìdánwò ránpẹ́ fún ti ọ̀sẹ̀ yìí.

Ẹni àkókó tí ó bá gba ìbéèrè márùn-ún yìí ẹ̀bùn owó ìpè ń bẹ nílè fún ẹni náà ..

#Ìbéèrè

1) Igi wo ni Yorùbá ń pè ẹkẹ́ ilé?

2) Kíni Yorùbá ń pè ní ijẹ̀?

3) àwọn ẹlẹ́sìn ìbílẹ̀ wo ló má ń lu ìlù tí a ń pè ní ìpèsè?

4)orúkọ wo ni a ń pè ọmọ tí a bí tí a kò rí ẹ̀jẹ̀ àti omira

5) Kíni orúkọ miran ti a le pe ẹyẹ ẹtù?

Ìlànà a tẹẹ lé

1) O gbọdọ̀ dáhùn ìbéèrè yí lẹ́ẹ̀ kan náà.

2) Èdè Yorùbá ni o gbọdọ̀ fi dáhùn.

3) Abẹ́ ìbéèrè yìí ni kí o fi ìdáhùn sí..

4) Ẹnikẹ́ni tí kò bá tẹ̀lẹ́ ìlànà yí kò ní ànfàní àti jẹ ẹ̀bùn.

Ire óò.

Tuesday 6 September 2016

Oríkì Ìjẹ̀bú

Oríkì Ìjẹ̀bú

Ìjẹ̀bú ọmọ alárè,
Ọmọ awujálè,
Ọmọ  arójò joyè,
Ọmọ alágemo Ògún,
Ọmọ aladìye ògògòmógà,
Ọmọ adìye bàlókùn,
Ara òrokùn,
Ara ò radìye,
Ọmọ ohun ṣéní,
òyòyò mayòmo ohun ṣéní,
olèpani, ọmọ dúdú ilé komobe ṣe níJósí,
Ọmọ moreye mamaroko, morokotan ẹyẹ mátìlo,
Ọmọ mo ní isunle mamalobe,
ọbẹ̀ tin be nílé kò mọ ilé baba tó bí wọn lọmọ,
Ọmọ onígbò ma’de,
Ọmọ onígbò mawo mawo,
Ọmọ onígbò ajoji magbodowo,
 Àjòjì tobawo gboro yio di ebora ile baba tobi wan lomo.
Ìjẹ̀bú ọmọ èrè níwà,
Ọmọ olówó ìṣèmbáyé,
Òrìsà jẹ́ ń dàbí onílé yí,
kelebe Ìjẹ̀bú owó,
ìtò Ìjẹ̀bú owó ,
Dúdú Ìjẹ̀bú owó ,
Pupa Ìjẹ̀bú owó,
Kékeré Ìjẹ̀bú owó ,
Àgbà Ìjẹ̀bú owó.
Ìjẹ̀bú òde Ìjẹ̀bú ni,
Ìjẹ̀bú igbó Ìjẹ̀bú ni,
Ìjẹ̀bú isara Ìjẹ̀bú ni,
Ayépé Ìjẹ̀bú,
Ikorodu Ìjẹ̀bú Ìjẹ̀bú ní ṣe,
Ìjẹ̀bú Ọmọ oní Ilé ńlá ,
Ìjẹ̀bú Ọmọ  aláso ńlá.

Awujale  Ọba Sikiru Kayode Adetona Ogbagba II

Ọba kéé pé oo

Ìlú Ìjẹ̀bú ó ní bàjé oooo

Semiat Wúràọlá Bello ló kọọ

Thursday 1 September 2016

oríkì Erinlé

Erinlè Aganna àgbò
Ení j'é nímo Ògúnjùbí
Ògúngbolu a bá èrò Òde Kobaye.
Òyò gori ìlú
Oloyè nlá
Arodòdó sé ìgbànú esin
Gbogbo igi gbárijo,
Won fi Ìrokò se baba ninú oko
Gbogbo ilè gbárijo,
Won fi Okítì se baba ninú oko
Gbogbo odò kékéké ti nbe ninú igbó
Ajagusi won gbárijo,
Won fi Erinlè joba ninú omi.
Baba mi lo I’òkun, òkun dáké
O'nlo l’òsà, òsà mì tìtì
Òyó-olá nlo l’òkun,
Òkun mì lègbelègbe omi olólá

#Èdùmàrè jọ̀wọ́ má jẹ ki ìlú Erinlé bàjé

Kí ọba ìlú náà pẹ̀, kádé pé lórí, kí bàtà pé léṣe, kí irukere di okini

#ÀmínláṣẹÈdùmàrè.

Tuesday 30 August 2016

Ọba aláyéLúwà

AláyéLúwà

Ìwòfà pàdé ọba lọ́nà,
Ó gbàdúrà kẹ́lẹ́ kẹ́lẹ́,
Pé bóyá orí a ṣé,
Òun náà a dépò ọba,
Láì mọ̀ wípé,
Orí adé ò jẹ́rù ọba o fúyé,
Lotito ipò ọba dára,
Ipò kábíyèsí dára púpọ̀,
Ṣùgbọ́n ìdààmú ìdí rẹ̀ pọ,
Ọba ò lẹ́sìn,
Bọ́dún Mùsùlùmí dé,
Ó dí dandan kó bá wọn ṣe,
Bí àwọn kirisititeni ń sọdún,
Ó gbọdọ̀ báwọn ṣe,
Bí ẹṣin àbáláyé ṣe tiẹ̀ ó gbọdọ̀ kó pá,
Nítorí ó ní ipa pàtàkì láti kó,
Ọ̀pọ̀ nnkan lo wa,
Tí ọba ó gbọdọ̀ ṣe,
Torí ipò ẹlẹgẹ́ tó dì mú,
Gbogbo ojú ni n bẹ lára ọba,
Ọba o lè sẹ̀yọ́ ní gbangba,
Ọba kìí jẹun ní ìta,
Ọba ò gbọdọ̀ sè yí ṣe tọ̀hun,
Bí o tilè jẹ́ pé,
A ó mọ bí wọn tíì ń sìnkú ọba,
Ó dájú wípé ọba kìí sùn bí i mẹ̀kúnnù,
Ipò ọba dára ṣùgbọ́n ohùn tó rọ mọ pọ̀,
Ìdí rẹ ni yìí tí Yorùbá má fi ń sọ wípé

#Ilésanmíwọnlódùnjoyèlọ.

Ẹ jẹ́ kí a má dúpẹ́ ni gbogbo ipò tí a bá ara wa....

Èdùmàrè jẹ́ kí gbogbo ọba ilé Yorùbá pé bí mópé tí ń pé,
Kádé pé lórí gbogbo wọn, kí bàtà pé lẹ́sẹ̀ wọn, kí ìrùkèrè wọn di ọkini....

#ÀmínÀṣẹÈdùmàrè

Sunday 28 August 2016

Oríkì Ọ̀kà Àkókó

#Oríkì Ọ̀kà Àkókó

Ọmọ olókàrufè,

Ọ̀kà Àkókó Ọ̀kàrúfé,

Ẹkùn ńlá fi orí òkè ṣe ibùgbé,

Ogunkógun kò le dojú kọ,

Ẹkùn ni bùdó Ogun tó bá dojú kọ Ẹkùn ni bùdó ẹ ní náà yíò dẹni ẹbọra,

Ọmọ ori òkè Afòkúta rigidi bọ ogun jà,
Tó bá yi kú atun yi kéé Ogun,

A sin túká Ọ̀kàrúfé Ayeye bí Èṣù,

Ọ̀kàrúfé ṣe méjì gbogbo Àkókó ṣe mẹ́ta.

Èdùmàrè jọ̀wọ́ jẹ́ ìlú Ọ̀kà Àkókó pé

Àmín Àṣẹ Èdùmàrè

Ìlú Ọ̀kà Àkókó wá ní ìpínlè Òndó

Saturday 27 August 2016

Oríkì Ede

Oríkì Ede

Ede màpó arógun,
Iyako agbo
Èyin Ọmọ ají lala ọsọ
Ọmọ ají sọsọ
Ọmọ ají f'ọjọ́ gbogbo dára bí egbin,
Ede ọmọ elepo rédé,
Ọmọ ẹwà a dodo,
Èyin lọmọ arohanran,
Ọmọ aje ń ju,
Èyin lọmọ agbale gbira tó l'ede ilé,
Èyin lọmọ alápò tì'emi tì'emi
Èyin lọmọ arógun má fi t'ìbọn se
Ede ìlú timi Ọlọ́fà iná.

Mo kabiyesi fún ọba Timi agbale, ọba Muniru Adesola Lawal Laminisa 1

Ìlú Ede o ni bàjé o

Àmín láṣẹ èdùmàrè

Tedx

Kí ló wá sí ọkàn rẹ tí o bá gbọ́ nípa TED/TEDx? Ọ̀rọ̀? Gbogbo ibi yíká pẹ̀lú capeti Pupa? Ó wá pẹ̀lú gbogbo ànfàní yìí. Ní #TEDxIsaleGeneral,
A ń ṣe ọ̀pọ̀lọpọ̀ nkan tó ju sísọ ọ̀rọ̀ tí ó móríyá lọ. A ní àwọn ìrírí tí yíò yà yín lẹ́nu, tí yíò si yíì ìgbésí ayé ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn padà. Ẹ má fojú sọ́nà lásán o. Ẹ fi ọjọ́ náà sì inú ìwé ìrántí tí yín.

Ọ̀fẹ́ ni gbogbo àwọn tí ó bá wá ó wọlé,  a ṣí àyè iforukosile sílè láìpé. Àyè wá fún ẹnikẹ́ni tí ó bá fẹ́ rán wa lọ́wọ́ àti bá wa ṣe pọ.
Ẹkan sí wa lori sponsorships@tedxisalegeneral.com fún iranlowo.

Emdee Tiamiyu,
Curator, TEDxIsaleGeneral.

Oríkì Ìkàré Àkókò

Oríkì Ìkàré Àkókó

Ọmọ olókè méje takọtabo,
Omi atan, ọmọ ase Ìkàré ribárìbo,
Osekiti gere
Ìkàré ọmọ igi mẹta ọ̀nà osélé,
Ìkan Udi,
Ìkan ure òṣìṣẹ́ lóni wo,
Owa àlè moru orun òdì,
Ìkàré lọmọ àjùwàjùwà Ìlèkè,
Ótorí ìlèkè níikú royo royo,
Èyin lọmọ igiri òkè
Ọmọ Arésè gbomi gbẹ,
Ṣebí ẹ̀yin le lókùúta, lelapata,
Ìkàré ọmọ àpáta dowo ọtun dolà,
Ọmọ osoro làjòjì sọnu,
Àjòjì forí kó nini òwúrò,

Èdùmàrè báwa dá ìlú Ìkàré sí, ìlú Ìkàré ó ní bàjé (Àmín láṣẹ èdùmàrè)..

Ìkàré jẹ́ ọkàn lára àwọn ìlú tó wà ní ìpínlè Òndó

Oríkì Èjìgbò

Ọmọ kíkan l'èjìgbò,
Ọmọ kíkan ará Èjìgbò,
Èjìgbò moro,
Ọmọ apa ẹran ńlá bàjé,
Ọmọ onírè Ooni
Ọmọ ọkọ Saki,
Ará ọrun
Ọ̀run mowó,
Ọmọ aṣọlékè gbaariye,
Ọmọ ọkọ kò sani léṣe kaparun
Ọmọ ewú kele maja
Irenimogun ọmọ awúlẹ̀ wúwo
Irenimogun taran l'àgbère
Ògún Onírè ọmọ abúlé sowo
Èèyàn ò bímọ nírẹ̀ kó tosi
Èèyàn ò bímo nírẹ̀ kò rahun ọwọ́ nina..

Èdùmàrè jọ̀wọ́ jẹ́ kí ìlú Èjìgbò dára...


Semiat Wuraola Bello ni ó kọ

Ìbéèrè ìfẹ́

Ìbéèrè ìfẹ́

Ǹjẹ́ tí bá fi àlébù mi hàn ìwo olólùfẹ́?
Ǹjẹ́ o kòní jámi kulè?
Ǹjẹ́ o lè fara da ìwà mí?
Ǹjẹ́ o lè fara da ìṣe mí?
Ǹjẹ́ tí nkò bá lè mú okàn mi le?
Ǹjẹ́ ìwo òní fimísílè bá elégàn lo?
Ǹjẹ́ ìwà àti ìṣe mí dára
Ǹjẹ́ o lè Femi pẹ̀lú ṣùgbọ́n mi?
Ǹjẹ́ o le jè ògbùnró mi?
Ábí ìwo ájámikulè torí àlébù mi?
Ranti Èmi èrò omi,ìwo onílù ìsàlè odò.

#Gbìyànjú kí o nífẹ̀ẹ́ olólùfẹ́ pẹ̀lú ṣùgbọ́n tàbí àléébù tí o ní...

Ìfẹ́ dùn o dára

Thursday 25 August 2016

Osun State Anthem

Iṣẹ́ wa fún ilẹ̀ wá,
Fún ilẹ̀ ìbí wá,
kagbégá, kagbégá, kagbégá, fáyérí,
Ìgbàgbọ́ wà ní pé ẹ
Báṣé bérú labọmọ,
Káṣiṣẹ́, Káṣiṣẹ́, Káṣiṣẹ́, ká jọlà,
Ìsòkan a'tòmìnira ní kẹjẹ́ ká máa lépaa,
Tẹsiwaju,
Fọpọire àtohun tó dára a
Ọmọ odu'a dìde bósí ipò ètó rẹe
Ìwọ ní , imọ́lè gbogbo adúláwò.

Ìpínlẹ̀ Òsun òní dàrú, orílè èdè Nàìjíríà òní bàjé. Àmín láṣẹ èdùmàrè...

Ṣe boo tí mọ ẹlẹ́wà sàpọ́n"

Ẹ kú dédé àsìkò yìí gbogbo olólùfẹ́ ojú ìwé yìí,
Ìtàn míràn rèé oo fún ìgbádùn yín

Ìtàn "Ṣe boo tí mọ ẹlẹ́wà sàpọ́n"
A má ń gbọ́ tí àwọn ènìyàn má ń sọ pé "ṣe bí o timo ẹlẹ́wà "sàpọ́n" ọ̀pọ̀lọpọ̀ ló rò wípé òwe tàbí àṣàyàn ọ̀rọ̀ àtayébáyé kan ni.  Kí ṣe bẹ́ẹ̀ oo, ẹnikan ni ó fi d'àṣà, àṣà náà wá tàn  kálékáko ní ilé Yorùbá.

Ojà kan wà ní ìlú Abẹ́òkúta ní ìpínlè Ogun tí orúkọ rẹ ń jẹ "sàpọ́n"  ọjà yí gbayì púpò ní ayé àtijó, ó jé ibi tí gbogbo àwọn ọkùnrin tí kò n'ìyàwó ní ilé tí máa ń jẹ àje yó bámú bámú látàrí onírúurú oúnjẹ tí ó wà, òun mímú náà o gbéyìn. Fún ìdí ẹ yí ni wọn fí ń pe ọjà náà ni sàpọ́nloore. Ìyá kan wà nínú ọjà yí tí orúkọ rẹ ń jé Odesola, ẹwà sísè sì ni ohun nta, ìyá yìí ló má d'àṣà wípé "ṣe boo timo".

Ẹwa  ìyá yí dùn púpò tó fi jẹ́ pé kíá ló gb’orí l’ọwọ́ gbogbo àwọn ẹlẹ́wà tó wà ní agbègbè náà, tí orúkọ rẹ si gbajúmọ̀ káàkiri. Ìkòkò kékeré kan ló fi bẹrẹ, ṣùgbọ́n kò pẹ púpọ̀ tí òwò náà fi di ńlá, ló bá di'ko máà ṣe odidi àpò ẹwa kan tà l’ọjọ́ kan ṣoṣo. Ìkòkò ẹwa  wá pọ lọ bíi rẹrẹ nínú ìsò rẹ pẹ̀lú ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ọmọ iṣẹ́. Ṣe ni ọgọọrọ àwọn ènìyàn a pé leè lórí pitimu, tí wọn aa tò lọ bẹẹrẹ láti ra ẹwa, àfi bíi pé ó fi oyin sí ẹwa rẹ ni.
Bí àwọn kan tí nj’oko jẹẹ ní isọ rẹ l’àwọn míì ràn ń raa lọ s’ilé wọn.
Nínú àkọsílẹ̀ tí a rí kà, ẹja ni ìyá yìí ń tà tẹlẹ. Ó ń kiri ẹja panla rẹ yí lọ l’ọjọ́ kan ló ni k’oun ra ẹwa jẹ l’ làdúgbò kan ní Abẹ́òkúta. Ọbẹ̀ ata tí wọn bù lé orí ẹwa yi fún un ko tẹ l’ọrùn l’òun náà bá pinnu láti bẹrẹ ẹwa tita.

Gbogbo àì ṣe dédé tó ti rí lọdọ àwọn ẹlẹwa tó kú ni òun ṣe àtúnṣe rẹ nígbà tí ó bẹrẹ ẹwa. Òwò tí a bá fi ọgbọ́n iwé pilẹ rẹ a máa yàtọ̀ sí tí ẹni tí kò kà ìwé, nígbà tí òwò ìyá yi gbẹrẹgẹjigẹ tán. Ọ̀nà kìíní tó máa ń gbà dá àṣà yí ni pé ó máa ń sọ fún awọn oníbárà rẹ pé kí wọn ṣe bí wọn tí mọ, kí wọn má jẹ ju iwọn owó tó wà l’àpò wọn lọ, kí wọn má si ra ẹwa ju iwọn ti ikùn wọn leè gbà lọ bí owó tìẹ wà l’àpò .

Ẹwa pọ n’ìgbà náà. Ọ̀nà kejì ni pé ẹwa yi máa ń tètè tán, t’ẹwa ìyá bá tí tán tí àwọn kan bá béèrè pé kílódé tí kò ṣe ẹwa si a wípé ‘emi o le ṣe ju agbára mi lọ o, ṣe boo ti mọ l'ayé gba’.

Ìyẹn já sí pé ìyá ò le sè ju àpò ẹwa kan l’ojúmọ́ , ìwọ̀n ni wàhálà owó gbọdọ mọ.
O le ya yin l’ẹnu pe ìyá ẹlẹwa sàpọ́n yi si wa l’oke eepẹ. Eni ọdun mejidinlaadorunni ìyá bayi , kí Ọlọ́run jẹ́ k’ọjọ́ wọn o dale. Gẹgẹ bi mo se gbọ, a bi ìyá yi ni ọdún 1925. O bẹrẹ ẹwa títà ni 1951, o si fi isẹ yi silẹ nítorí idiwọ inu ẹbi ni ọdún 1996. O wa jẹ pe ọdún márùnlélogójì ní ìyá ẹlẹwa sàpọ́n fi ta ẹwa. Ninu akọsilẹ awọn to ba iya ẹlẹwa sàpọ́n s’ọrọ láìpẹ́ yí, ìyá tí ta ẹwa fun Ọba ilu ri, iyẹn Osilẹ Òkè Ona to wa l’orí itẹ lásìkò náà, Ọba Alimi Adedapo. Won ni bi Ọba yi ba ni àlejò pàtàkì tó sii jẹ pé ẹwa lo wu wọn láti jẹ, iya ẹlẹwa sàpọ́n ni wọn maa nbẹ n’isẹẹ. Wọn tí gbe ojú pópó gba ibi tí ìyá yí tí ń ta ẹwa.
 Ipò tí ìyá ẹlẹwa sàpọ́n wa báyìí o fi dára to òkìkí ti wọn ti ni nígbà Sangoòde wọn.
Ìtàn ìyá ẹlẹwa sàpọ́n re o, ìyá wa Odesola ni ìlú Abẹ́òkúta Aráyé ò gbàgbé wọn, ayé a gbàgbé ìjòyè pàtàkì , wọn a gbàgbé olówó ṣùgbọ́n, ó di ọjọ́ ayé bá paré kí èdè Yorùbá ó tó parun, bí èdè Yorùbá ò bá sí parun, a òle gbàgbé ẹlẹwa sàpọ́n láyé kaafata.

Iṣẹ́ ẹni ni Iṣẹ́ ẹni, ma tijú Iṣẹ ́rẹ. Ẹni bá jalè nìkan ló b’ọmọ je. Ìyá ẹlẹwa sàpọ́n o tijú Iṣẹ́ rẹ, ìyá f’isẹ gbé èdè Yorùbá lárugẹ.


#Àwọn ìbéèrè tí tó ṣe pàtàkì.

1) Kíni àwọn ijọba ìpínlè Yorùbá ńṣe ni pá iru àwọn èèyàn báyìí , tí wọn gbaju gbaja nìdí  Iṣẹ́ wọn ti ọna ti wọn gbà se Iṣẹ́ wọn di àṣà ati àṣàyàn ọrọ to ngbe èdè Yorùbá lárugẹ titi láé láé?

2)  Kíni ayé o mọ iwọ àti èmi si n’igba ayé wa àti nígbà tí a bá p’ẹyinda tán?

3) Ǹjẹ́ Iṣẹ́ ọwọ tiẹ se e fi yangàn ?

 #Ẹ̀jẹ̀ ká gbà'ayé ṣe #rere

written by Semiat Olufunke Bello(Wuraola)

Wednesday 24 August 2016

Ìtàn bàbá alájo sómólú

 ìtàn bàbá alàjọ sómólú
Ní bí ti orí bàbá yí pé de awọn ènìyàn a máa sọ wípé "Orí ẹ pé bíi ti alàjọ Sómólú , tó fo didi ọdún mẹ́ta gbàjọ lai ko orúkọ ẹni kánkán sílè , tí kò sì siwo san fẹnikẹ́ni",
Àwọn míràn a sì máa sọ pé"Orí ẹ pé bíi Alàjọ Sómólú , tó ta mótò ,tó fi ra kẹkẹ", Ìdí tí wọn fi sọ èyí ni pé bàbá gba àjọ ó jèrè, ó kọ ilé rẹpẹtẹ, ó sì ra ọkọ̀,
ṣùgbọ́n ti ó bá gun ọkọ̀ naa fún ìgbà díè, tó bá ti wá yọnu, bàbá ó taa yio sì lọ fi owó náa ra kẹkẹ èyí wá jẹ́ ìyàlẹ́nu fún gbogbo àwọn ènìyàn pé irú Àkàndá ẹ̀yán wo rèé tí yíò lọ tá ọkọ̀ tí wá lọ fi ra kẹkẹ, èyí tún mú kí àwọn ènìyàn nífẹ̀ẹ́ bàbá gidigidi. Àwọn òní baara bàbá náà si ti mọ tí wọn ba tí rí kẹkẹ tuntun wọn tí mọ pé bàbá tún ti ta moto nìyẹn,ìdí rẹ rèé tí wọn fi má ń sọ pé "#Orí ẹ pé bíi Alàjọ Sómólú , tó ta mótò ,tó fi ra kẹkẹ",
Bàbá gba àjọ fún bíi ogun ọdún, àgbà dee bàbá ó sile jáde lọ gba àjọ mọ ṣùgbọ́n àwọn oní baara tí ó nífẹ̀ẹ́ bàbá má ń mú owó àjọ wọn wá sí ilé, bàbá kọ ìyàwó ọmọ rẹ bí wọn ṣe ń ṣe iṣẹ́ náà, tí ó sì jẹ pé òhun náà lọ má ń gba àjọ lọ́wọ́ àwọn ni baara wọn.
Bàbá kú ní ẹni ọdún mẹ́tadílọgọrun(97) ni ọjọ́ kọkànlá oṣù kẹjọ ọdún 2012 ni ilé rèé tó wà ní sómólú ni ilu Èkó.
Bàbá alàjọ sómólú je ẹniti a ko gbọdọ̀ gbàgbé ní orílè èdè Nàìjíríà,awa ọdọ òní náà ni lati kọ ẹ̀kọ́ kan tàbí òmíràn nínú igbe ayé bàbá yí

Awon ibeere to je yọ
1. Ǹjẹ́ àwọn ènìyàn lee sọ ọ̀rọ̀ rẹ ni dada tóó bá kú?
2. Ǹjẹ́ iṣẹ́ tó ń ṣe lee sọ̀rọ̀ fun o?
3. Ǹjẹ́ iṣẹ́ owó kíkọ wúlò bíi?
#Ẹsẹ́ púpò fún àkókò tí ẹ fi sílè láti ka ìtàn yìí...
#Written by Semiat Olufunke Bello(Wúràọlá)

Ìtàn bàbá alájo sómólú

Apá kejì
Ìtàn bàbá alàjọ sómólú Tẹsiwaju.....
Ní ọdún 1950, Bàbá alàjọ sómólú nígbàti o dé orílè èdè Kamẹrúùnù, bàbá alàjọ sómólú wòó pé kini ohun lè má ṣe, ṣùgbọ́n Ọlọ́run fún bàbá náà ni ẹ̀bùn ìṣe lèyí tí ó sì mú lo. Bàbá náà ṣe onírúurú isẹ ni orílẹ̀ èdè Kamẹrúùnù bí àpẹẹrẹ ó tà ìwé ìròyìn,ó ṣe òwò káràkátà. Bàbá alàjọ sómólú ni aládùúgbò tí jẹ́ wí pé isẹ àjo gbígbé ní ohun ṣe, tí bàbá náà sì fojú sí nítorí pé ó nife sì púpò púpò, ti o sí mọ. Ní ọdún 1954 bàbá sí padà sí orílè èdè Nàìjíríà lèyí tí ó ní lémi láti ma gba àjọ látàrí ohun tí ó kọ ní orílè èdè Kamẹrúùnù, ní gbogbo àkókò yí ọmọ ọdún Mókàndílóogójì ni bàbá jẹ́,
kí ó sì tó kúrò ní orílè èdè Kamẹrúùnù ó ṣe ẹ dá ìwé tí yíò ma ko orúkọ àwọn ènìyàn sì tí ó pe orúkọ rẹ ni alàjọ sómólú ojojumo.
Ṣùgbọ́n kí ó tó bẹ̀rẹ̀ ó lọ fi lọ ẹ̀gbọ́n bàbá tí ó sí sọ pé kí ó má ṣe látàrí àwọn tí ó ti ṣe sẹ́yìn tó jẹ́ wípé gbèsè ni wọn jẹ bo, kò gbo ohun tí ẹni yí sọ, ó tún lọ sọ fún ẹ̀gbọ́n rẹ obìnrin, ẹ̀gbọ́n rẹ yí ni ó mú lọ sí odò olùṣọ́àgùntàn tí wọn sì gba àdúrà tí wọn sì ni ọ̀nà rẹ ni kí má ṣe ṣùgbọ́n wọn kii ni lọọ pé kí ó má fi òtítọ́ inú ṣe.
Nígbà tí ó bẹ̀rẹ̀ ó lọ sí odò àwọn ìyá l'oja gbogbo àwọn ó sì dá lóhùn wọn wípé tí yíò kowó àwọn sá lọ tí ó bá yá, ṣùgbọ́n baba alàjọ sómólú kò ko irewasì ọkàn, nígbà tí ó yá àwọn ìyá l'oja bá fi owó àwọn ọmọ wọn dán wò lèyí tí òsì yege láti ìgbà náà ni wọn ti dá àjọ fún.
Bàbá alàjọ sómólú je akínkanjú ẹni tí ó mú ìṣe lọkunkundun. Ní àkókò yí àwọn igba ènìyàn ni wọn dàjọ fún tí ki si kọ nkan nkan sílè tí ó bá sì di ìpárí oṣù bí wọn ṣe kó owó fún náà ni yio dá padà, nítorí èyí ni wón bá fún ní orúkọ
#alàjọsómólútíógbaowóolówóigbaènìyàntíkòsisekoorúkọwọnsílètíkòsiowókófúnẹnikẹ́ni
# fojú sọ́nà fún ìyókù


Ìtàn bàbá alájo sómólú

Apá kini
tàn bàbá alàjọ Sómólú
Alphaeus Taiwo Olunaike jẹ́ orúkọ tí gbogbo ọmọ orílè èdè Nàìjíríà o mọ, ṣùgbọ́n tí wọn ba gbo Baba Alàjọ Somolu,
Gbogbo la mọ orúkọ náà.
Bàbá Alàjọ Sómólú jẹ́ ẹni tí wọn bí ígbátí ewu ń lá ni ìlú wọn, bí ìtàn ṣe fi yẹ wa. Wọn bí Taiwo Olunaike ọmọ
Alphaeus ni ọjọ́ kẹrindínlógún oṣù Kẹ̀sán ọdún 1915 ni ìlú kan tí wọn pè ní Isan Oyin (tí wọn pè ní Isonyin lakoko yí) ìlú náà wá létí Ìjẹ̀bú Musin àti Ìjẹ̀bú Ode ni Ìpínlẹ̀ Ógùn. Wọn gbọ́ igbe àwọn ọmọ tuntun láti ọ̀dọ̀ arábìnrin kan tí orúkọ rẹ ǹjẹ́ Grace Okuromiko Olunaike tí o bímọ ọmọ tí a ń pè ní etaoko.
Kété tí wọn sọ fún ohun àti ọkọ rẹ pé ọmọ mẹta lo bí ní ẹkan náà, inu wọn bàjé, wọn sì bu sekun, iporuru gba ọkàn wọn nítorí pé wọn etaoko sí nkan abàmì ni ìlú wọn, ẹni èyí tó jẹ́ wípé wọn a ìkan nínú àwọn ọmọ náà fún ẹbọ.
Ṣùgbọ́n ìtàn fi yẹ wá pé gbogbo àwọn tí ó lọ́wọ́ nínú pípa ọkàn lára àwọn ọmọ náà o kije tí wọn fi ta téru ni pa.
Nígbàtí tí wọn pé ọmọ ọdún merin bàbá wọn kú, ìyá àti ẹ̀gbọ́n obìnrin tí wọn ní lọ tọju wọn, ṣùgbọ́n laipe laijina ọmọ Kehinde náà kú lèyí tí ó jẹ pé Taye nìkan ló kù.
Ohun náà sì ni ẹni tí mo fé sọ nipe rẹ.

Taiwo Olunaike jẹ́ ọmọ ọdún merin nígbà tí baba wọn kú, ó bere ilé ìwé alákòbẹ̀rẹ̀ ni Emmanuel Primary School, Ìjẹ̀bú Isonyin.
Kò parí ẹ̀kọ́ rẹ tí ẹ̀gbọ́n baba rẹ Torimoro fi mú lọ sí ìlú Èkó láti Tẹsiwaju nínú ẹ̀kọ́ rẹ.
Orí rẹ ko yọ lọ́wọ́ fífi rúbọ ní ọdún 1927, nígbà tí ó dé ìlú Èkó wọn fi sí ilé ìwé St. Johns School, Aroloya.
Láti ibè ó wọ ilé ìwé Christ Church Cathedral , ní ìlú Èkó Lagos, ó sì ṣe tán ni ọdún 1934.
Lẹ́yìn ọdún méjì tí ó ti parí ẹ̀kọ́, ẹ̀gbọ́n baba rẹ lọ fi sì ẹnu ẹ̀kọ́ ìṣe aṣọ ríran, ó sì kó ìṣe náà fún ọdún mẹsan kí ó tó gbà òmìnira.
Ó bẹ̀rẹ̀ si rán aṣọ ṣùgbọ́n owó tí o un wọlé kéré tí kò sì tó gbọ́ bùkátà látàrí èyí ó wà ọna miran ti owó lè má gba wọlé, ní àkókò yí ẹ̀gbọ́n baba Torimoro fe lọ sí oríle èdè Kamẹrúùnù fún ìṣe Taiwo sì tẹ le lọ bo yà ọ̀nà yí ọ sí.
#Ẹfojú sọ́nà fún ìyókù.....

Oríkì ìbejì

Oriki Ibeji:

Wíníwíní lójú orogún
Ejìwọ̀rọ̀ lojú ìyá ẹ̀,
Ẹ̀jìrẹ́ ará ìṣokún,
Ẹdúnjobí, 
ọmọ a gbórí igi rétẹréte,
Ọkàn ń bá bí méjì ló wọlé tọ míwá,
Ọ́bẹ́kíṣì bẹ́kéṣé,
Ó bé sílé alákìísa,
Ó salákìísà donígba aṣọ.
Gbajúmọ̀ ọmọ tíí gbàkúnlẹ̀ ìyá,
Tíí gbàdọ̀bálẹ̀ lọ́wọ́ baba tó bí í lọmọ.
Bi Táyélolú ti nló ni iwájú,
Bééni, Kehinde ń tó lẹ́yìn,
Táyélolú ni àbúrò,
Kehinde ni ẹ̀gbọ́n,
Táyélolú ni a rán pé kí o ló tó ayé wò,
B'ayé dára , bi ko dára
O tọ́ ayé wò,
Ayé dun bi oyin
Táyélolú, Kehinde, ni mo ki
Ejìwọ̀rọ̀ lojú ìyá ẹ̀
O dé ilé ọba tẹ̀rín-tẹ̀rín,
Jẹ́ kí nrí jẹ, kí n rí mú.
Orí mí jẹ́ ń bí ìbejì l'ọ́mọ,
èdùmàrè fún gbogbo àwọn tó ń w'ojú rẹ ní ọmọ gbajúmọ̀ bí ìbejì bí oooo...
Àmín àṣẹ

Òwe Yorùbá

#Òwe fún t'òní.
Ẹjẹ́ ká sọ ìtumò òwe yìí

Tuesday 23 August 2016

Ajá Ọdẹ

Ẹ fi alo apagbe yìí e ara rindin Ajá Ọdẹ Ní ayé àtijó, ọkùnrin kan wà, í ọdẹ ni ó yàn láàyò. Ọkùnrin yìí gbóná nínú í ọdẹ íe. Ohun tí ó fún ní òkìkí nínú í ọdẹ yìí ni ajá. Ọkùnrin ọdẹ yìí sí féràn ajá rẹ̀ púpò wọn kì í sì ya ara wọn nígbà kan. Àwọn ènìyàn bẹ̀rẹ̀ sí e ìlara ọdẹ yìí àti ajá rẹ. Nígbà tí ó di ọjọ kan, ọdẹ yìí kò rí ajá rẹ̀ mọ́. Ó bẹ̀rẹ̀ sí wá ajá rẹ kiri. Nígbà tí ó pẹ́ tí ó ti ń wá ajá rẹ̀ kiri, ó sii gbúròó wípé àwọn kan ni wọn gbé ajá òun pamọ́. Ọkùnrin yìí gba ọ̀dọ̀ ọba ìlú lọ láti lọ f'ẹjọ́ sùn. Ọba gbọ́, ó si pe gbogbo ìlú jọ ó pe ọdẹ àti àwọn tí wọ́n gbé ajá ọdẹ yìí. Ọba sọ pé kí wọn ó wá pe ajá náà bí wọn e máa ń pe tí ó fi máa ń dá wọn lóhùn. Àwọn tí ó jí ajá ni wọn kọ́ jáde, wọn bẹ̀rẹ̀ sí pe ajá yìí. Wọn pèé títí ajá na kò e bí ẹni gbọ́ nǹkankan. Nígbà tí ó e, ọba pe ọdẹ kí ó wa pe ajá rẹ̀.



Ọdẹ bá bẹ̀rẹ̀ sí pé ajá rẹ báyìí pé >>

Ọdẹ: Ajáà mi dà
         Àwọn ará ìlú: Ajá Ọdẹ
Ọdẹ: Ajáà mi dà
Àwọn ará ìlú: Ajá Ọdẹ
Ọdẹ: Òkémọ kéréú
Àwọn ará ìlú: Ajá Ọdẹ
Ọdẹ: Òsọ sàkà gbe mì
Àwọn ará ìlú: Ajá Ọdẹ
Ọdẹ : Ò gbálẹ̀ gbáràwé
Àwọn ará ìlú: Ajá Ọdẹ
Ọdẹ: Ajáà mi dà
Àwọn ará ìlú: Ajá Ọdẹ

Bí Ọdẹ yìí ti ń kọrin bẹẹ ni ajá bẹ̀rẹ̀ sí gbó tí ó ń ké tí ó sì ń gbìyànjú àti tú ara rẹ̀ sílẹ̀. Bí Ọdẹ tún ti ń kọ orin yìí lẹ́ẹ̀kan sí ni ajá já'kùn, tí ó sì ń sá tọ olówó rẹ̀ ọdẹ lọ. Àwọn ènìyàn hó gèè, ọba sì pà pé kí ọdẹ máa mú ajá rẹ lọ, kí wọn ó sì lọ ti ojú àwọn olè tí wọn jí ajá yọdà, kí wọn ó sì ti ẹ̀yìn wọn tibọ àkọ̀ rẹ̀. Eléyìí jásí pé wọn pa wọn. Ìtàn yìí kọ́ wa pé kí á mọ́ máa jalè.


Olúkọtàn Semiat Wúràọlá Bello

Saturday 20 August 2016

Òmìnira

#Òmìnira

Òmìnira ṣe pàtàkì,
Òmìnira ṣe koko fún gbogbo ohun elédùmarè dá,
Bí ènìyàn bá nínú ìnira tàbí ìgbèkùn,
Tí ó wá rí ìtúsílẹ̀,
Àyípadà rere a dé,
Ìfọ̀kàbalẹ̀ á wà,
A bọ lọ́wọ́ ìdarí ọ̀gá,
A bọ nínú wàhálà ọ̀gá àti àwọn tí ó kó sódì,
A le gbèrò fúnra rẹ,
A ṣí le tẹ́lẹ̀ ìlànà tó fẹ́,
Lọ́kàn ara rẹ,
Yàtọ̀ sí gbà tó wà làbẹ́ ìtọ́ni amúnísìn,
Bó tilẹ̀ jẹ́ pé òmìnira dára,
Gbogbo ẹ̀dà lo fẹ́ràn ẹ,
Ṣùgbọ́n ọ̀pọ́ òmìnira,
Lò n yọrí sí omi ìnira,
Fáwọn to gb'mìnira,
Ẹ wo orílè èdè Nàìjíríà,
A lòmíràn òṣèlú,
Ṣùgbọ́n abẹ ààbò amúnísìn la wà nínú okòwò,
Bẹ́ẹ̀ náà ni nínú àṣà, nínú ètò ẹ̀kọ́,
Ètò òṣèlú táa láa ni òmìnira rẹ̀,
Ìlànà òṣèlú amúnísìn náà la tún si n tẹ́lẹ̀,
Kí ló ṣe àwa ènìyàn aláwò dúdú,
Ṣe a kò le ronú fúnra wa ni?
Ẹ jẹ ki gbogbo àwa ọmọ orílè èdè Nàìjíríà àti gbogbo orílẹ̀ aláwò dúdú náà já fún ètò wa lọ́wọ́ àwọn tí a fi ṣe olórí,
Ẹ jẹ́ ká bọ àjàgà àwọn funfun sílè,
Ká mohun tí ṣe tiwa ṣe,
Dúdú làṣà, dúdú lẹ̀sìn, dúdú létó òṣèlú kí àwọn amúnísìn tó dé,
Kí ló wá dé tesin wa fọmọ tí ẹ̀ sílè tí n pọnmọ olọmọ.

Mo rọ gbogbo ọmọ orílè èdè Nàìjíríà àti orílẹ̀ aláwò dúdú ti o kú kí a gba ara lọ́wọ́ amúnísìn kí òmíràn má bá di omi ìnira mo wa lọ́wọ́.....

#Èdùmàrè jẹ́ kí àlàáfíà jọba ní gbogbo orilẹ̀ èdè aláwò dúdú, kí a le jọ lá gbéga papọ̀.....

Inú mi dùn pé ilé aláwò dúdú ni mo ti wá

#ìwọ ń kọ?

Ìfẹ́

Ẹyín féràn ẹnu,ofi ṣe ilé,
Irun féràn orí ,ofi ṣe ilé,
Ìràwò òwúrò tèmi nìkan,
Olólùfẹ́ mi,
Nínú aba ayé yìí
Ẹkuro emi mi alabaku ẹwa rẹ,
Ọrọ ìfẹ́ yi n yimi
Mo ni mi o nífẹ̀ẹ́ mon,
Ife ìwọ olólùfẹ́ gbokan mi,
Ìwo ni nkan rere ti o sele sì,
Mo mọ ẹ ìmò mi lékún,
Mo mọ ẹ ó jẹ kí mọ àǹfààní ohun tí ẹdua fún tí mo fi lè ṣe ọmọ aráyé lore... 

Mo nife re...

Èyí wa fín àwọn olólùfẹ́ láti fi ranse sí olólùfẹ́ wọn

Friday 19 August 2016

Aṣọ wíwò

Aṣọ wíwọ̀

Èèyàn lèyí ni àbí wèrè?
Asínwín lèyí ni àbí abugije?
Ṣé aṣọ lèyí abi kini?
Ha! Ayé tí bàjé,
Gbogbo ọmọ adáríhunrun tí sọ àṣà nù,
A gbé òmíràn,
A fi aṣọ sílè láìwọ̀,
A sọ ìhòòhò rí rìn di ohun gidi,
A rìn ìhòòhò nítorí oge,
Kilode tí á lé wọṣọ iyì,
Taa dáyé bá,
Bí bùbá, sooro, agbádá, kijipa àti bẹẹ bẹẹ lọ,
Aṣọ ilé bàbá wa,
A kì í wọ aṣọ ajòjì,
Ká rí bí ọmọ ìbílẹ̀,
Kí ọmọge wọ bùbá àti ìró,
Kóya gèlè náà haha,
Kó fìborùn lee,
Kó fì ìlèkè iyùn tàbí ṣegi sọrùn,
Ṣùgbọ́n ayé tí di rúdurùdu,
Gbogbo aṣọ tí buyi kún ènìyàn tí di ohun àpati,
bùbá, sọọrọ àti fìlà,
Kii se ohun tí ọkùnrin ń wọ mọ,
Bí ẹlòmíràn de fìlà jáde, kò ni rántí mú wálé,
Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọmọ ode òní ni ó mọ Ṣòkòtò kènbè, fúntan,
Bórókún dìmú débi tí wọn yóò mọ,
Fìlà ìkòrì, lábànkádà, òrígí àti sọgọ,
ẸDákun ẹ̀jẹ̀ ká ronúpìwàdà, ká gbe àṣà àti ìṣe tí ó jẹ tiwa lárugẹ......

Ásà wa kò ní parun ooooooo

EwaEdeYoruba

Thursday 18 August 2016

Ìtẹ́lọ́rùn

Ìtẹ́lọ́rùn

Ìtẹ́lọ́rùn ni baba ìwà,
Ìtẹ́lọ́rùn ṣe pàtàkì fọ́mọ adamọ,
Ìtẹ́lọ́rùn ṣe kókó,
A gbọdọ̀ ni ìtẹ́lọ́rùn,
Kí a le rí ayé gbé,
Kí a le gbáyé ìrọ̀rùn,
Aìní ni ìtẹ́lọ́rùn le mú ni jalè,
Bí ohun tí a ni kò bá tó wa,
Aìní ìtẹ́lọ́rùn ni mú nisẹ ṣìná,
Ìyàwó rere wà nílè,
Ṣùgbọ́n ojú kòkòrò o je ké gbádùn,
Ìwo ìyàwó ọkọ rere wà nílè ṣùgbọ́n ojú kòkòrò o je ki o gbádùn,
Aṣẹ̀yìnwá àṣẹ̀yìnbọ̀,
Ṣìná kó ọ sìnà,
Àgbèrè gba gbogbo èrè iṣẹ́ ẹ,
Aìní ìtẹ́lọ́rùn ló mú èṣù dẹni ilẹ̀,
Ẹ̀jẹ̀ ká ní ìtẹ́lọ́rùn nínú gbogbo idáwọ́le wa,
Ẹ̀jẹ̀ kí ìtẹ́lọ́rùn jẹ́ àkọmọ̀nà wa..

#Ìtẹ́lọ́rùnṣepàtàkì.

Ìfẹ́ láàárín ara wa

Ìfẹ́ láàrin ara wa
Ìfẹ́ dára,
Ìfẹ́ dùn bí a bá pàdé oní tí wá,
Ìfẹ́ jẹ́ òhun tí ó má ń ṣẹlẹ̀ láàrin àwọn ènìyàn,
Yálà ọkùnrin sí obìnrin,
Obìnrin sí ọkùnrin,
Ìyá sí ọmọ,
Bàbá sí ọmọ,
Ọkọ sí ìyàwó,
Ìlú sí ìlú,
Orílẹ̀ èdè sí orílè èdè,
Yálà o dúdú tàbí o pupa,
Eje ká nífẹ̀ẹ́ ara wa.
Ìwo ọkọ nífẹ̀ẹ́ ìyàwó re,
Ìwo ìyàwó nífẹ̀ẹ́ ọkọ rẹ,
Bàbá àti ìyá ẹ̀ fẹ́ràn gbogbo àwọn ọmọ yín dọ́gba,
Ìwo oga fẹ́ràn ọmọ ìṣe rẹ dáradára,
Ìwo ọmọ ìṣe mọn jẹ oga rẹ lẹsẹ.
Ìfẹ́ là kó já òfin,
Ibi tí ìfẹ́ bá wà,
Ayò, ìdùnnú, ìgbéga, orire kìí jìnà sí bẹ,
Eje ká nífẹ̀ẹ́ ara wa,
Ìfẹ́ dùn ó dára ó ṣì dùn ju oyin lọ.....


Oríkì Ẹ̀rìn Òsun


Ẹ̀rìn moje ọmọ saaja,
Ọmọ eléwé ladogba òróró maro,
Ẹ̀rìn wagunwagun 
Ewá w'Ẹ̀rìn logun eniti yíò wá Ẹ̀rìn logun kowa àpò ide kolowa ọfà,
Bàbá kòníbon ajíperin nílé,
karo ń lè mọ wọn lójú ogun ẹni Ẹ̀rìn mọ jẹ́ ta l'ọfà tikoku titi ọjọ́ ale afori wowe lobisu Ẹ̀rìn mọ jẹ́ lọmọ
Igi kan igi kan toya dina l'Ẹ̀rìn,
Nipopo olowe koje ki ọmọ elẸ̀rìn,
oroko kòjé kí Ìwòfà elẸ̀rìn orodò,
Ènìyàn mélòó nani yio gegi oro naa,
Olowe wọn ní kí wọn wá,
Abuké méje,
Arọ méje,
Adití méje,
Abuké ngegi lọ apá kan ń dùn karara,
Apá kan ń dùn kororo,
kinni kan ndun winrinwinrin níkùn igi,
oro naa ja nipopo olowe arara ngegi lọ apá kan ń dùn karara, Apá kan ń dùn kororo,
kinni kan ndun winrinwinrin níkùn igi arara base dùn le lomori wogbo, Owadi elékẹta ototo adití tí kò gbó t'ayé tí kò gbó tọrùn sebi oun logegi ọ̀rọ̀ náà nipopo olowe,
kinni wọn ba nínú igi wọn ba osahin wọn ba ọkà bàbà ìbọn oje eku eyan tokanrin nílé tápà nílé ọmọ afowuro dáná kúlíkúlí....
Èdùmàrè jọ̀wọ́ jẹ́ kí ìlú Ẹ̀rìn Òsun pé oooo