Monday 6 March 2017

ọmọbìnrin Alaáìgbọ́ràn

Àlọ́ rèé o fún gbogbo olólùfẹ́ èdè Yorùbá, ẹ gbádùn ẹ kí ẹ tó sùn 

Àlọ́ oo
Àlọ̀ 
Àlọ́ yí dá fìrìgbagbo, ó dá lórí ọmọbìnrin Alaáìgbọ́ràn

Ni ayé àtijó,ọmọbìnrin kan wà ní ìlú kan. Ọmọbìnrin yìí rẹwà bí egbin. Gbogbo àwọn ọmọkùnrin ni ó fé fi s'aya ṣùgbọ́n kò gbà fún ẹnì kankan nínú wọn. Àwọn òbí rẹ ni yan ọkọ fún ṣùgbọ́n kò tẹ́lẹ̀ ẹniti wọn yan fún un.

Ní ọjọ́ kan ó ṣe alápàdé ọmọkùnrin kan tí ó rẹwà, ó sì wu ọmọbìnrin yìí dáadáa. Ó sọ fún ọmọkùnrin yìí pé òun nífẹ̀ẹ́ rẹ, òun sì fẹ́ kí ó jé ọkọ òun. Ọmọkùnrin yìí kọ̀ pé òun kò ní fẹ́ ọmọbìnrin yìí, ṣùgbọ́n ó fàáké kọ́rí pé ọmọkùnrin yìí ni òun ni láti fẹ́ láìmọ̀ pé sènìyàn-sẹranko ni ọkùnrin náà, erè inú omi ni, ó paradà láti wá sí ìjọ àwọn adáríhunrun lásán ni. Nígbà tí ọmọbìnrin yìí kò gbà, ni ọmọkùnrin yìí bá sọ pé òun yóò fẹ́ẹ, ó sì sọ fún ọmọbìnrin náà wí pé ilé òun jìnà,ọmọbìnrin sọ fún un pé ibikíbi tí ọmọkùnrin yìí bá ń lọ òun yóò bàa lọ. 



Nígbà tí wọ́n rìn díè tí wọ́n dé ibi tí àwọ̀ ọmọkùnrin yìí wà, ní ọmọkùnrin yìí bá yà sí inú igbó tí ó sì gbé àwọ̀ erè rẹ̀ wọ̀. Bí erè ti fà dé ojú ọ̀nà ni ó fa Ẹsẹ̀ ọmọbìnrin yìí ṣe rí ohun tí ó ń ṣẹlẹ̀ yìí ni ó bá f'ariwo ta pẹ̀lú orin lẹ́nu báyìí pé :

#Ọmọbìnrin: - - - - - - - - - -Nìkún o, Nìkún ninì
#Ègbè: - - - - - - - - - - Ninini, Nìkún ninì
#Ọmọbìnrin: - - - - - - - - - - - Nìkún o, Nìkún ninì
#Ègbè: - - - - - - - - - - - Ninini, Nìkún ninì
#Ọmọbìnrin: - - - - - - - - - - --bàbá fi mí f'ọkọ ẹ̀mí ò gbọ́ o
#Ègbè: - - - - - - - - - - Ninini, Nìkún ninì
#Ọmọbìnrin: - - - - - - - - - - ìyá fi mí f'ọkọ ẹ̀mí ò gbà o
#Ègbè: - - - - - - - - - - Ninini, Nìkún ninì
#Ọmọbìnrin: - - - - - - -ọkọ nìkan tí mo fẹ́ ló bá derè o
#Ègbè: - - - - - - - - Ninini, Nìkún ninì
#Ọmọbìnrin: - - - - - - Nìkún o, Nìkún ninì
#Ègbè: - - - - - - - - Ninini, Nìkún ninì

Bí ọmọbìnrin yìí ṣe ń kọ orin ni erè bẹ̀rẹ̀ sí gbéemi díè díẹ̀. Ṣé orí tí yóò sunwọ̀n nigb'aláwò re ko ni, ọkàn nínú àwọn ọmọkùnrin tí wọ́n tí k'ọnu sí obìnrin yìí láti fi s'aya wà lórí ẹ̀gùn tí ó ń s'ọdẹ. Bí ó ti gbé ojú wo iwájú ni ó rí erè tí ó ń gbé ọmọbìnrin yìí mì. Bí ọkùnrin yìí ṣe ta ìbọn mọ́ erè nìyí tí erè sí kú lẹ́yìn èyí ni ọmọbìnrin náà yọ jáde l'ẹnu erè.

Ìdí àlọ́ yìí ni pé kò yẹ kí á máa ṣe àìgbọràn sí àṣẹ àwọn òbí wa. Kí á sì tún má máa ṣe fáàri àṣejù.

Mo lérò wípé ẹ rí ẹ̀kọ́ kan tàbí méjì kọ́...

Ẹsẹ́ púpọ̀


Saturday 4 March 2017

Aṣọ ńlá kọ́ l'èèyàn ńlá

Gbogbo Onífújà kọ́ l'Ọmọlúàbí,
Gbogbo ènìyàn tí ẹ rí nínú ọkọ̀ aláfẹ́ kọ́ ni wọ́n n sojúse wọn lọ́dẹ̀dẹ̀,
Kìí se gbogbo ẹni tó wọsọ ìgbà ni ènìyàn iyì,
Gbogbo sànmọ̀nrí kó lèèyàn nlá,
Kìí kúkú se gbogbo arẹwà ló níwà,
Èrò kò kúkú mọkọ̀,
Tóbá dára láwọ̀,
só dára dénú irin?
Fàwọ̀rajà gbàlú gbàdúgbò kan,
Gbogbo ẹni tó wọsọ nlá kọ́ ni ènìyàn nlá,
Dẹ̀ngẹ́ tutù lẹ́hìn gbóná nínú,
Gbogbo ohun tó n dán kọ́ni wúrà,
Ọ̀pẹ ọ̀yìnbó fi dídùn sẹwà tí oró inú rẹ̀ lé lérínwó,
Ẹ jẹ́ ká sọ́ra fún ìtànjẹ àwọn alásọdùn,
Gbogbo ológe wúwo kọ́ lèèyan iyì,
Nitóri orí burúkú kìí wú túúlú,
A kìí dá ẹsẹ̀ asiwèrè mọ̀ lọ́nà,
A kìí morí olóyè láwùjọ.

Ẹjẹ́ ká sọ́ra fún àwọn Fàwọ̀rajà, kí a sì má fojú di ẹnikẹ́ni láwùjọ..

#EdeYorubaRewa