Gbogbo Onífújà kọ́ l'Ọmọlúàbí,
Gbogbo ènìyàn tí ẹ rí nínú ọkọ̀ aláfẹ́ kọ́ ni wọ́n n sojúse wọn lọ́dẹ̀dẹ̀,
Kìí se gbogbo ẹni tó wọsọ ìgbà ni ènìyàn iyì,
Gbogbo sànmọ̀nrí kó lèèyàn nlá,
Kìí kúkú se gbogbo arẹwà ló níwà,
Èrò kò kúkú mọkọ̀,
Tóbá dára láwọ̀,
só dára dénú irin?
Fàwọ̀rajà gbàlú gbàdúgbò kan,
Gbogbo ẹni tó wọsọ nlá kọ́ ni ènìyàn nlá,
Dẹ̀ngẹ́ tutù lẹ́hìn gbóná nínú,
Gbogbo ohun tó n dán kọ́ni wúrà,
Ọ̀pẹ ọ̀yìnbó fi dídùn sẹwà tí oró inú rẹ̀ lé lérínwó,
Ẹ jẹ́ ká sọ́ra fún ìtànjẹ àwọn alásọdùn,
Gbogbo ológe wúwo kọ́ lèèyan iyì,
Nitóri orí burúkú kìí wú túúlú,
A kìí dá ẹsẹ̀ asiwèrè mọ̀ lọ́nà,
A kìí morí olóyè láwùjọ.
Ẹjẹ́ ká sọ́ra fún àwọn Fàwọ̀rajà, kí a sì má fojú di ẹnikẹ́ni láwùjọ..
#EdeYorubaRewa
No comments:
Post a Comment