Thursday, 3 November 2016

Bójú Bóra

Ọ̀rọ̀ kan gbé mi nínú,
Tí mo fẹ́ kẹ bámi dá sí,
Kí gbogbo mùtúmùwà fetí gbéyàwó ẹ,
Ọ̀rọ̀ àwọn ọmọge tó ń bójú Bóra,
Ló fa ariwo,
Ìyàwó adúláwọ̀,
Tó fẹ́ para rẹ̀ láwọ̀dà,
Bí wọ́n bá bàwó jẹ́ tán,
Wọ́n á wá fín pátápátá,
Ọsẹ abójú ni wọ́n ń wá kiri,
Atíkè abàwọ̀jẹ́ ni wọ́n ń lò lọ́pọ̀ ìgbà,

Wọ́n kìí dúró bí Ẹlẹ́dàá ṣe dá wọ́n,
Ń ṣe ní wọ́n ń bàwọ̀ jẹ́,
Ọ̀pọ̀lọpọ̀ làwọn òbí ò dà mọ̀ mọ́,
Nítorí ìgbà t'ọmọ ó kúrò nílé,
Ń ṣe ló dúdú bíi kóró isin,
Ìpadàbọ́ Odùduwà rèé,
Ọmọ tí d'òyìnbó atọwọdá,
Ojú lójú "kóòkì" ẹsẹ̀ lẹsẹ̀ "fàntà",
Oòrùn ti ń jáde lára wọn kò lẹ́gbẹ́,

Ní ìgbẹ̀yìn Ayé abójúbóra,
Kii suwòn,
Kí ǹkan má ṣe ara wọn ni
Búté búté ni ara wọn yíò má já,
Mo rọ gbogbo ọmọge adúláwọ̀ kí á wà bí èdùwà ṣe dá wa.

#Mosọyí, #modúrónaa.

Mo sì dúpẹ́ Púpọ̀ lọ́wọ́ #Ẹlẹ́dàá tó dá mi sí ilé #Adúláwọ̀,

#Ìwońkọ

https://instagram.com/edeyorubarewa

https://twitter.com/edeyorubarewa

https://facebook.com/edeyorubarewa

https://chat.whatsapp.com/Fb7Vz4kj9WlIunYKtIhmwu

https://edeyorubatiorewa.blogspot.com.ng/

No comments:

Post a Comment