Wednesday, 2 November 2016

Ta ló fẹ́ni dénú

Onílé apá ọ̀tún ò fojú irẹ woni,
Ìmọ̀ràn ìkà ni tòsí ń gbà,
Kájáde Kájáde ni tọ̀ọ́kan ile ń wí,
Ọmọ Adámọ níí fẹ̀jẹ̀ sínú,
Tutọ́ funfun bàláú jáde,
Bí wọn rí o lókèèrè,
Ti wọn pọ́n ọ́ lè tẹ̀ríntẹ̀yẹ̀,
Ohun ti ń bẹ nínú wọn,
Ó kọjá àpèjúwe,
Bí a bá ṣí inú ẹlòmíràn,
Ejò ṣèbé, ọkà, àkeekèé,
Agbọ́n, oyin tamo ṣánkọ,
Pẹ̀lú ọ̀pọ̀ ohun olóró mìíràn,
Là bá níkùn ọmọ ènìyàn,
Ṣùgbọ́n inú kìí ṣegbá,
Ojú lásán la rí,
Ọrẹ ò dénú,
Sàṣà èèyàn ni i féni lẹ́yìn,
"Bá ò sí nílé, tajá tẹran ni i fẹ ni lójú ẹni"
 Inú mi ni mo mọ
Ń ò mọ tẹlòmìíràn...

#Ìwo ń kọ́

https://instagram.com/edeyorubarewa

https://twitter.com/edeyorubarewa

https://facebook.com/edeyorubarewa

https://chat.whatsapp.com/Fb7Vz4kj9WlIunYKtIhmwu

https://edeyorubatiorewa.blogspot.com.ng/

No comments:

Post a Comment