Ikú ń pa alágẹmọ,
Tí ń yọ́ rin lórí ewé,
Ambèlètasé ọ̀pọ̀lọ́,
Tí ń jan ara rẹ̀ mọ́lẹ̀,
Ẹ̀sọ̀, ẹ̀sọ̀ láyé gbà,
Ìgbìn ò lápá,
Bẹẹ ni kò lẹ́sẹ̀,
Ẹ̀sọ̀, ẹ̀sọ̀ n'ìgbìn mà ń gun igi,
Yorùbá bọ̀, wọn ní "ohun a Fẹ̀sọ̀ mú ki í bàjé, ohun a fagbára mú kokoko ni le bí ojú ẹja"
Ẹ jẹ́ ká Fẹ̀sọ̀ ṣe,
Àwa èwe ìwòyí,
Màriwò to yọ láì yọ,
Tó lóhùn o kan ọrùn,
Ẹ jẹ́ ká bí í léèrè,
Bóyá ìran bàbá rẹ ṣe bẹ́ẹ̀ ri,
Ẹ̀sọ̀, ẹ̀sọ̀ láyé gbà,
Nítorí igbá pẹ̀lẹ́ kìí fọ́,
Àwo pẹ̀lẹ́ kìí fàyá,
Ẹ̀sọ̀ láyé gbà,
Ọmọ ìyá à mi tí ó jé Yorùbá ẹ jẹ́ ká máa fi ẹ̀sọ̀ ṣe,
Ìṣó Ọlọ́run a má wà pẹ̀lú wá ní gbogbo ìgbà...
#ÀmínÀṣẹÈdùmàrè
https://instagram.com/edeyorubarewa
https://twitter.com/edeyorubarewa
https://facebook.com/edeyorubarewa
https://chat.whatsapp.com/Fb7Vz4kj9WlIunYKtIhmwu
https://edeyorubatiorewa.blogspot.com.ng/
No comments:
Post a Comment