Wednesday, 24 August 2016

Oríkì ìbejì

Oriki Ibeji:

Wíníwíní lójú orogún
Ejìwọ̀rọ̀ lojú ìyá ẹ̀,
Ẹ̀jìrẹ́ ará ìṣokún,
Ẹdúnjobí, 
ọmọ a gbórí igi rétẹréte,
Ọkàn ń bá bí méjì ló wọlé tọ míwá,
Ọ́bẹ́kíṣì bẹ́kéṣé,
Ó bé sílé alákìísa,
Ó salákìísà donígba aṣọ.
Gbajúmọ̀ ọmọ tíí gbàkúnlẹ̀ ìyá,
Tíí gbàdọ̀bálẹ̀ lọ́wọ́ baba tó bí í lọmọ.
Bi Táyélolú ti nló ni iwájú,
Bééni, Kehinde ń tó lẹ́yìn,
Táyélolú ni àbúrò,
Kehinde ni ẹ̀gbọ́n,
Táyélolú ni a rán pé kí o ló tó ayé wò,
B'ayé dára , bi ko dára
O tọ́ ayé wò,
Ayé dun bi oyin
Táyélolú, Kehinde, ni mo ki
Ejìwọ̀rọ̀ lojú ìyá ẹ̀
O dé ilé ọba tẹ̀rín-tẹ̀rín,
Jẹ́ kí nrí jẹ, kí n rí mú.
Orí mí jẹ́ ń bí ìbejì l'ọ́mọ,
èdùmàrè fún gbogbo àwọn tó ń w'ojú rẹ ní ọmọ gbajúmọ̀ bí ìbejì bí oooo...
Àmín àṣẹ

5 comments: