ìtàn bàbá alàjọ sómólú
Ní bí ti orí bàbá yí pé de awọn ènìyàn a máa sọ wípé "Orí ẹ pé bíi ti alàjọ Sómólú , tó fo didi ọdún mẹ́ta gbàjọ lai ko orúkọ ẹni kánkán sílè , tí kò sì siwo san fẹnikẹ́ni",
Àwọn míràn a sì máa sọ pé"Orí ẹ pé bíi Alàjọ Sómólú , tó ta mótò ,tó fi ra kẹkẹ", Ìdí tí wọn fi sọ èyí ni pé bàbá gba àjọ ó jèrè, ó kọ ilé rẹpẹtẹ, ó sì ra ọkọ̀,
ṣùgbọ́n ti ó bá gun ọkọ̀ naa fún ìgbà díè, tó bá ti wá yọnu, bàbá ó taa yio sì lọ fi owó náa ra kẹkẹ èyí wá jẹ́ ìyàlẹ́nu fún gbogbo àwọn ènìyàn pé irú Àkàndá ẹ̀yán wo rèé tí yíò lọ tá ọkọ̀ tí wá lọ fi ra kẹkẹ, èyí tún mú kí àwọn ènìyàn nífẹ̀ẹ́ bàbá gidigidi. Àwọn òní baara bàbá náà si ti mọ tí wọn ba tí rí kẹkẹ tuntun wọn tí mọ pé bàbá tún ti ta moto nìyẹn,ìdí rẹ rèé tí wọn fi má ń sọ pé "#Orí ẹ pé bíi Alàjọ Sómólú , tó ta mótò ,tó fi ra kẹkẹ",
Bàbá gba àjọ fún bíi ogun ọdún, àgbà dee bàbá ó sile jáde lọ gba àjọ mọ ṣùgbọ́n àwọn oní baara tí ó nífẹ̀ẹ́ bàbá má ń mú owó àjọ wọn wá sí ilé, bàbá kọ ìyàwó ọmọ rẹ bí wọn ṣe ń ṣe iṣẹ́ náà, tí ó sì jẹ pé òhun náà lọ má ń gba àjọ lọ́wọ́ àwọn ni baara wọn.
Bàbá kú ní ẹni ọdún mẹ́tadílọgọrun(97) ni ọjọ́ kọkànlá oṣù kẹjọ ọdún 2012 ni ilé rèé tó wà ní sómólú ni ilu Èkó.
Bàbá alàjọ sómólú je ẹniti a ko gbọdọ̀ gbàgbé ní orílè èdè Nàìjíríà,awa ọdọ òní náà ni lati kọ ẹ̀kọ́ kan tàbí òmíràn nínú igbe ayé bàbá yí
1. Ǹjẹ́ àwọn ènìyàn lee sọ ọ̀rọ̀ rẹ ni dada tóó bá kú?
2. Ǹjẹ́ iṣẹ́ tó ń ṣe lee sọ̀rọ̀ fun o?
3. Ǹjẹ́ iṣẹ́ owó kíkọ wúlò bíi?
#Ẹsẹ́ púpò fún àkókò tí ẹ fi sílè láti ka ìtàn yìí...
#Written by Semiat Olufunke Bello(Wúràọlá)
No comments:
Post a Comment