Ẹ fi alo apagbe yìí ṣe ara rindin Ajá Ọdẹ Ní
ayé àtijó, ọkùnrin kan wà, iṣẹ́ ọdẹ
ni ó yàn láàyò. Ọkùnrin yìí gbóná nínú iṣẹ́ ọdẹ
ṣíṣe.
Ohun tí ó fún ní òkìkí nínú iṣẹ́ ọdẹ
yìí ni ajá. Ọkùnrin ọdẹ yìí sí féràn ajá rẹ̀ púpò wọn kì í sì ya ara wọn nígbà
kan. Àwọn ènìyàn bẹ̀rẹ̀ sí ṣe ìlara ọdẹ yìí àti ajá rẹ. Nígbà tí ó di ọjọ kan, ọdẹ
yìí kò rí ajá rẹ̀ mọ́. Ó bẹ̀rẹ̀ sí wá ajá rẹ kiri. Nígbà tí ó pẹ́ tí ó ti ń wá
ajá rẹ̀ kiri, ó sii gbúròó wípé àwọn kan ni wọn gbé ajá òun pamọ́. Ọkùnrin yìí
gba ọ̀dọ̀ ọba ìlú lọ láti lọ f'ẹjọ́ sùn. Ọba gbọ́, ó si pe gbogbo ìlú jọ ó pe ọdẹ
àti àwọn tí wọ́n gbé ajá ọdẹ yìí. Ọba sọ pé kí wọn ó wá pe ajá náà bí wọn ṣe
máa ń pe tí ó fi máa ń dá wọn lóhùn. Àwọn tí ó jí ajá ni wọn kọ́ jáde, wọn bẹ̀rẹ̀
sí pe ajá yìí. Wọn pèé títí ajá na kò ṣe bí ẹni gbọ́ nǹkankan.
Nígbà tí ó ṣe, ọba
pe ọdẹ kí ó wa pe ajá rẹ̀.
Ọdẹ bá bẹ̀rẹ̀ sí pé ajá rẹ báyìí pé >>
Ọdẹ: Ajáà mi dà
Àwọn ará ìlú: Ajá Ọdẹ
Ọdẹ: Ajáà mi dà
Àwọn ará ìlú: Ajá Ọdẹ
Ọdẹ: Òkémọ kéréú
Àwọn ará ìlú: Ajá Ọdẹ
Ọdẹ: Òsọ sàkà gbe mì
Àwọn ará ìlú: Ajá Ọdẹ
Ọdẹ : Ò gbálẹ̀ gbáràwé
Àwọn ará ìlú: Ajá Ọdẹ
Ọdẹ: Ajáà mi dà
Àwọn ará ìlú: Ajá Ọdẹ
Bí Ọdẹ yìí ti ń kọrin bẹẹ ni ajá bẹ̀rẹ̀ sí gbó tí ó ń ké
tí ó sì ń gbìyànjú àti tú ara rẹ̀ sílẹ̀. Bí Ọdẹ tún ti ń kọ orin yìí lẹ́ẹ̀kan
sí ni ajá já'kùn, tí ó sì ń sá tọ olówó rẹ̀ ọdẹ lọ. Àwọn ènìyàn hó gèè, ọba sì
pàṣẹ pé kí ọdẹ máa mú ajá rẹ lọ, kí wọn ó sì
lọ ti ojú àwọn olè tí wọn jí ajá yọdà, kí wọn ó sì ti ẹ̀yìn wọn tibọ àkọ̀ rẹ̀.
Eléyìí jásí pé wọn pa wọn. Ìtàn yìí kọ́
wa pé kí á mọ́ máa jalè.
Olúkọtàn
Semiat
Wúràọlá
Bello
No comments:
Post a Comment