Tuesday, 6 September 2016

Oríkì Ìjẹ̀bú

Oríkì Ìjẹ̀bú

Ìjẹ̀bú ọmọ alárè,
Ọmọ awujálè,
Ọmọ  arójò joyè,
Ọmọ alágemo Ògún,
Ọmọ aladìye ògògòmógà,
Ọmọ adìye bàlókùn,
Ara òrokùn,
Ara ò radìye,
Ọmọ ohun ṣéní,
òyòyò mayòmo ohun ṣéní,
olèpani, ọmọ dúdú ilé komobe ṣe níJósí,
Ọmọ moreye mamaroko, morokotan ẹyẹ mátìlo,
Ọmọ mo ní isunle mamalobe,
ọbẹ̀ tin be nílé kò mọ ilé baba tó bí wọn lọmọ,
Ọmọ onígbò ma’de,
Ọmọ onígbò mawo mawo,
Ọmọ onígbò ajoji magbodowo,
 Àjòjì tobawo gboro yio di ebora ile baba tobi wan lomo.
Ìjẹ̀bú ọmọ èrè níwà,
Ọmọ olówó ìṣèmbáyé,
Òrìsà jẹ́ ń dàbí onílé yí,
kelebe Ìjẹ̀bú owó,
ìtò Ìjẹ̀bú owó ,
Dúdú Ìjẹ̀bú owó ,
Pupa Ìjẹ̀bú owó,
Kékeré Ìjẹ̀bú owó ,
Àgbà Ìjẹ̀bú owó.
Ìjẹ̀bú òde Ìjẹ̀bú ni,
Ìjẹ̀bú igbó Ìjẹ̀bú ni,
Ìjẹ̀bú isara Ìjẹ̀bú ni,
Ayépé Ìjẹ̀bú,
Ikorodu Ìjẹ̀bú Ìjẹ̀bú ní ṣe,
Ìjẹ̀bú Ọmọ oní Ilé ńlá ,
Ìjẹ̀bú Ọmọ  aláso ńlá.

Awujale  Ọba Sikiru Kayode Adetona Ogbagba II

Ọba kéé pé oo

Ìlú Ìjẹ̀bú ó ní bàjé oooo

Semiat Wúràọlá Bello ló kọọ

No comments:

Post a Comment