Muso muso muso orílè èdè Nàìjíríà pé ọdún merindilogota aráyé ẹ bá wa jó aráyé ẹ bá wa yọ.
Orílè èdè Nàìjíríà, orílè èdè abínibí mi, ó pé ọdún merindilogota tí a ti gba òmìnira kúrò lọ́wọ́ òyìnbó amúnisìn, nínú to lórí tẹlémù ló ń dùn. Àwọn òyìnbó gbẹ́ ọ̀pá àṣẹ fún ologbe Tafawa Balewa, ṣùgbọ́n pẹ̀lú ẹ̀ta inú àti Áì sọ̀kan gbogbo ọmọ orílè èdè Nàìjíríà a kò fi bẹẹ ni ìlọsíwájú ní orílè èdè wa. Gbogbo àwọn tí wọn ṣe tán láti jẹ kí orílè èdè Nàìjíríà tẹsíwájú pípa ni àwọn ọ̀tá ìlọsíwájú ń pá wọn. Àwọn èèkàn ńlá ńlá tí wọn jẹ kí a gba òmìnira kúrò lọ́wọ́ òyìnbó amúnisìn ni
Ọbafemi Awolowo, Ahmadu Bello, Anthony Enahoro, Nnamdi Azikuwe, Tafawa Balewa pẹ̀lú Sámúẹ́lì Ladoke Akintola àti bẹẹ bẹẹ lọ?
Tí ó jé wípé ohùn tí gbogbo àwọn wọ̀nyí ni lọ́kàn kí a tó gba òmìnira ní gbogbo àwọn tí wọn dárí wá ní gbogbo ohun tí ó ṣẹlẹ̀ sí wa yí kò ní ṣẹlẹ̀, ṣùgbọ́n kò sí ẹnì tí ó ma fi ọbẹ̀ tónu je ìṣù.
Ọbafemi Awolowo, Ahmadu Bello, Anthony Enahoro, Nnamdi Azikuwe, Tafawa Balewa pẹ̀lú Sámúẹ́lì Ladoke Akintola àti bẹẹ bẹẹ lọ?
Tí ó jé wípé ohùn tí gbogbo àwọn wọ̀nyí ni lọ́kàn kí a tó gba òmìnira ní gbogbo àwọn tí wọn dárí wá ní gbogbo ohun tí ó ṣẹlẹ̀ sí wa yí kò ní ṣẹlẹ̀, ṣùgbọ́n kò sí ẹnì tí ó ma fi ọbẹ̀ tónu je ìṣù.
Kò ti peju láti yi gbogbo nǹkan padà, ṣùgbọ́n láti yí padà ó wà lọ́wọ́ èmi àti ìwọ, ẹ má jẹ́ kí a má sọ wípé mio fẹ́ràn òsèlú nítorí pé tí àwa ti a rò wípé a lè tún ṣe bá ń sọ wípé mi o fẹ́ràn òṣèlú àwọn tí ó bàjé lá má dibo fún pẹ̀lú èyí kò ní sí ìlọsíwájú ní orílè èdè Nàìjíríà wá.
Láti tún orílè èdè Nàìjíríà ṣe ọwọ́ tèmi àti tiẹ̀ ló wà.
A kú ọdún ayajo òmìnira ọ̀pọ̀lọpọ̀ ẹ laa ṣe ooooo
Dìde ẹ̀yin ará
Wa jepe Nàìjíríà ,
ka fife sinlee wa,
pekókun àtigbagbọ ,
kíṣé àwọn akọni wa,
ko ma se ja sasan,
kà sin tọkàn~tara,
Ilé tòmìnira ,
àlàáfíà sọ dòkan
Wa jepe Nàìjíríà ,
ka fife sinlee wa,
pekókun àtigbagbọ ,
kíṣé àwọn akọni wa,
ko ma se ja sasan,
kà sin tọkàn~tara,
Ilé tòmìnira ,
àlàáfíà sọ dòkan
Mo ṣe ìlérí fún Orílẹ̀ -Èdè mi Nàìjíríà,
Láti jẹ olódodo,
Ẹniti ó ṣeé fọkàn tán,
Àti olotito èniyàn,
Láti sìn pẹ̀lú gbogbo agbára mi,
Láti sa ipá mi gbogbo fún Ìsòkan re,
Àti láti gbe e ga fún iyì àti ògo re.
Kí olúwa kí ó rán mi lọ́wọ́. (Àmín)
Láti jẹ olódodo,
Ẹniti ó ṣeé fọkàn tán,
Àti olotito èniyàn,
Láti sìn pẹ̀lú gbogbo agbára mi,
Láti sa ipá mi gbogbo fún Ìsòkan re,
Àti láti gbe e ga fún iyì àti ògo re.
Kí olúwa kí ó rán mi lọ́wọ́. (Àmín)
No comments:
Post a Comment