Thursday, 14 September 2017

Ìjàpá àti ẹyẹ Àdàbà

Èyí ni Àlọ́ àpagbè fún gbogbo olólùfẹ́ ojú ìwé yìí, mọ lérò wípé ẹ ò gbádùn ẹ.

Àlọ́ oooo
Àlọ́ ọọọọ
Àlọ́ yìí dá lórí #ÌjàpáatiẹyẹÀdàbà

Gégé Bí ẹ̀yin náà ti mọ̀, alàgàbàgebè ni Ìjàpá, olè àti ọ̀kánjúwà ni pẹ̀lú. Ní ayé àtijó, Ìjàpá àti Ẹyẹ Àdàbà jọ ń ṣe ọ̀rẹ́. Àdàbà ni ẹṣin kan tí ó máa ń gùn kiri tí Ìjàpá kò sì ní nǹkankan. Ìjàpá ronú lọ́jọ́ kan, ó sì gbèrò bí yóò ti ṣe pa ẹṣin Àdàbà. Ó rí pé Àdàbà gbayì láàrin àwùjọ èyí tí kò dùn mọ̀ Ìjàpá nínú.

Nígbà tí ó di ọjọ́ kan Ìjàpá dá ọgbọ́n àlùmọ̀kọ́rọ́yín, ó pa ẹṣin Àdàbà. Àdàbà kò bínú sí kíkú tí ẹṣin rẹ̀ kú. Ohun tí ó ṣe ni pé ó gé orí ẹṣin náà ó bòó mọ́lẹ̀ ó wá fi ojú ẹṣin si ìta tí ènìyàn leè máa rí dáadáa. Bí Ìjàpá ti ń kọjá lọ ni ó rí ojú tí ó yọ síta. Eléyìí yàá lẹ́nu, kíá ó gbéra ó di ilé ọba. Nígbà tí ó dé ààfin, ó sọ fún ọba pé òun ti rí ibi tí ilé gbé lójú. Eléyìí ya ọba lẹ́nu, ó sì tún bí Ìjàpá bóyá ohun tí ó ń sọ dáa lójú. Ìjàpá sọ fún ọba pé ó dá òun lójú, ó sì tún wá fi dá ọba lójú pé bí kò bá rí bẹ́ẹ̀ kí ọba pa òun. Nígbà yìí ni ọba pe gbogbo àwọn ìjòyè àti ẹmẹ̀wà rẹ̀ pé kí àwọn lọ wo ibi tí ilẹ̀ gbé lójú. Ìjàpá ni ó síwájú tí ó sì bẹ̀rẹ̀ sí kọ orin báyìí pé;

Ìjàpá___________ Mo ti rí ibi ilẹ̀ gbé lójú
Agberin________ Ilẹ̀
Ìjàpá___________ Mo ti rí ibi ilẹ̀ gbé lójú
Agberin________ Ilẹ̀

Báyìí ni gbogbo wọn ń dá reirei lọ sí ibi tí ilẹ̀ gbé lójú. Bí Àdàbà ti gbọ́ ohun tí Ìjàpá ṣe yìí ni ó bá sáré lọ sí ibi tí ó bo orí ẹṣin rẹ̀ tí ó wó sí, ni ó bá wú orí náà kúrò lọ sí ibòmíràn. Nígbà tí ọba ìjòyè àti àwọn ẹmẹ̀wà dé ibi tí Ìjàpá wí, wọn kò rí nǹkan kan Ìjàpá bẹ̀rẹ̀ sí tú ilẹ̀ kiri títí kò rí ojú kankan. Ìgbà yí ni ọba bínú gidigidi pé Ìjàpá pa irú irọ́ tí ó tó báyìí àti pé ó tún da òun, àwọn ìjòyè àti àwọn ẹmẹ̀wà láàmú láti wá wo ohun tí kò sí níbẹ̀. Kíá ni ọba pàṣẹ pé kí wọn ó ti ojú Ìjàpá yọ'dà kí wọn ó ṣì ti ẹ̀yìn rẹ̀ kì í bọ àkọ̀.Eléyìí jásí pé wọn paá. Báyìí ni Ìjàpá fi ìlara pa ara rẹ̀.

#EdeYorubaRewa

Àlọ́ àpagbè

Àlọ́ àpagbè míràn fún gbogbo olólùfẹ́ ojú ìwé yìí. Mo lérò wípé ẹ ò gbàdúrà e
Àlọ́ oooo
Àlọ́ ọọọọ
Àlọ́ yìí dá lórí #ẸkùnàtiIkùn

Ní ìlú àwọn ẹranko, kìnnìún ni Ọba wọn. Nígbà tí ó di ọjọ́ kan, Ọba ẹranko pe gbogbo àwọn ẹranko jọ, ó sọ fún wọn pé òun fẹ́ dá ọjọ́ tí àwọn ẹranko yóò wa ṣe eré fún òun. Ó sọ pé ẹni tí ó bá lu ìlù dáadáa òun yóò da lọ́lá. Nítorí ìdí èyí ó ní kí ẹranko kọ̀ọ̀kan lọ kan ìlù. Gbogbo àwọn ẹranko gbọ́ ọ̀rọ̀ Ọba, wọ́n dárí lọ sí ilé wọn. Ẹni kọ̀ọ̀kan nínú àwọn ẹranko ń gbìyànjú à ti kan ìlù. Ṣùgbọ́n dípò kí ẹranko kan tí orúkọ rẹ ń jẹ ikún ó kan ìlù tie, ní ṣe ni ó lọ gbé ìlú ẹkùn níbi tí ẹkùn gbé e sí. Ẹkùn bẹ̀rẹ̀ sí wa ìlú rẹ, ó wàá títí kò ri. Nígbà tí ó di ọjọ́ aré, ẹkùn jí ni kùtùkùtù ó lọ dúró ní ọ̀nà tí ó lọ sí ilé kìnnìún ọba ẹranko. Bí ẹranko kọ̀ọ̀kan bá ti fe kọjá ni ẹkún yóò yọ sí i tí yóò sì sọ pé kí ó lu ìlù rẹ̀ kí òun gbọ́. Orin ni ẹkún fi ń sọ eléyìí fún wọn tí orin náà sì lọ báyìí :

Ẹkùn________ Ríkíríkijàn
Agberin_____ Àríkijàn
Ẹkùn________Ríkíríkijàn
Agberin_____Àríkijàn
Ẹkùn________ Ọba ló dájọ́ aré
Agberin_____ Àríkijàn
Ẹkùn________ Ọba ló dájọ́ ayò
Agberin_____Àríkijàn
Ẹkùn________Wọ́n ní á kànlù, mo kànlù
Agberin_____Àríkijàn
Ẹkùn________ Mo gbé ìlú mi s'àgbàlá
Agberin_____ Àríkijàn
Ẹkùn________ Ọmọ ẹranko gbé e lọ
Agberin_____Àríkijàn
Ẹkùn________ Lùlù rẹ kí n gbọ́
Agberin_____Àríkijàn
Ẹkùn________Lùlù rẹ kí n mọ
Agberin_____Àríkijàn
Ẹkùn________ Papakúkú rangbọndan
Agberin_____ Àríkijàn
Ẹkùn________ Papakùkù rangbọndan
Agberin_____ Àríkijàn
Ẹkùn________Ìlù mi kọ́ùn ni
Agberin_____Àríkijàn
Ẹkùn________ Rékọjá o máa lọ
Agberin_____Àríkijàn

Báyìí ni ẹranko kọ̀ọ̀kan ṣe ń kọjá tí ẹkùn sì ń kọ orin bákan náà. Nígbà tí ó kan ikùn láti kọjá, ẹ̀rù ti bẹ̀rẹ̀ sí bàa. Ẹkùn tún bẹ̀rẹ̀ orin rẹ̀ :

Ẹkùn________ Ríkíríkijàn
Agberin_____ Àríkijàn
Ẹkùn________Ríkíríkijàn
Agberin_____Àríkijàn
Ẹkùn________ Ọba ló dájọ́ aré
Agberin_____ Àríkijàn
Ẹkùn________ Ọba ló dájọ́ ayò
Agberin_____Àríkijàn
Ẹkùn________Wọ́n ní á kànlù, mo kànlù
Agberin_____Àríkijàn
Ẹkùn________ Mo gbé ìlú mi s'àgbàlá
Agberin_____ Àríkijàn
Ẹkùn________ Ọmọ ẹranko gbé e lọ
Agberin_____Àríkijàn
Ẹkùn________ Lùlù rẹ kí n gbọ́
Agberin_____Àríkijàn
Ẹkùn________Lùlù rẹ kí n mọ
Agberin_____Àríkijàn
Ẹkùn________ Papakúkú rangbọndan
Agberin_____ Àríkijàn
Ẹkùn________ Papakùkù rangbọndan
Agberin_____ Àríkijàn
Ẹkùn________ ìlù mi nùnun nì
Agberin_____ Àríkijàn

Bí ikùn tí gbọ́ pé ìlù ẹkùn ni òun gbé lọ́wọ́, pẹ̀ẹ̀ lójú ìlù sílè tí ó bẹ̀rẹ̀ sí sá lọ. Ẹkùn gbá tẹ́lẹ̀e,ṣùgbọ́n bí ẹkùn ṣe ni kí òun ó ki ikùn mọ́lẹ̀ ni ó ṣá wọ inú ihò lọ. Ikùn kò lọ láì f'arapa, èékánná ẹkùn ha ikùn ní ẹ̀gbẹ̀ méjèèjì. Bí ènìyàn bá rí ikùn lónìí, yóò rí pé ilà funfun wà ní ẹ̀gbẹ̀ méjèèjì ikùn di òní olónìí yìí o. Olè jíjà kò dára oooo

#EdeYorubaRewa

Ọfọ̀ Ẹ̀fẹ̀

"Dúró ń bẹ̀"
Ohun tá a wí f'ọ́gbọ́
Lọ́gbọ́ ń gbọ́
Èyí tá a wí f'ọ́gbà
Lọgbà ń gbà
Inú ẹtù kìí dùn
Kó wálé ọdún
Inú àgbọ̀nrín kìí dùn
Kò wálé dìsẹ́nbà
Aṣọ ìbora kìí lápò
Kèké kìí ya ilé epo
Ìgbín kìí fẹ́yìn rìn
Ọ̀kadà kìí ní kọ̀ndọ́
Ijọ́ tí ọmọdé bá gbé'rà lóko
Ní dé ilé
Ijọ́ tókèlé ba dọ́nà ọ̀fun
Ní I de ikùn
Mo pàṣẹ fún ọ
Óyá!!! Fi àtẹ̀jíṣé yìí ránṣé
Ẹ̀fẹ̀ lèyí àbí àwàdà.

#EdeYorubaRewa

Ọ̀RỌ̀ ìṣítí

Iṣu mi ọdún yìí
N kò ní fẹ́nìkan jẹ
Àgbàdo tí mo gbìn yìí
Kò ní kan ẹnìkan l'ẹ́nu
Ẹran ọ̀yà tí mo yìnbọn sí
Tíi mo ba ri
Emi nìkan ni yóò jẹ
Ko mọ̀ pé,
Ìgbẹ lẹran rẹ í gbé sí
Yorùbá bọ̀ wọ́n ní A kìí láhun ká nìyí
Ará ilé ahun ò gb'ádùn ahun
Ahun ọ̀hún
Ọ̀rọ̀ ìjìnlè Yorùbá lèyí
Ọmọ ahun, kò gbádùn ẹ
Ìyàwó ahun kò gbádùn ẹ
Gbogbo atótótu òkè yìí ń sàfihàn aburu
Tí ń bẹ nínú ahun ṣíṣe
Bó ṣe oúnjẹ lo ní, bó ṣe owó dákún ran aláìní lọ́wọ́
Àdáníkànje, ládánìkànku
Ẹni tó lawọ́
Kò tíì rí àánú Olódùmarè
Aánbọ̀sìbọ́sí ahun
Òkè lọ́wọ́ afúnni ń gbé
Ẹ jẹ ká jáwọ́ ahun ṣíṣe.
Ẹ má jee ká láhun nítorí ahun kò dára.
Bí ẹnikẹ́ni bá wá ìrànlọ́wọ́ dé ọ̀dọ̀ dákún gbìyànjú láti ràn wọ́n lọ́wọ́.

#EdeYorubaRewa.