Thursday, 20 October 2016

Oríkì Ìkòyí

Oríkì Ìkòyí

Ìkòyí èshó,
Ọmọ agbọn iyùn,
Ogun ajaaiweeyin lọ meso wù mí,
Ogun ojoojumo lo mú kilee wọn sú mí lọ,
èshó kí gba ọfà lẹ́yìn,
Gbangba iwájú ni wọn fí gbaọta,
Ọmọ oni Ìkòyí akoko,
Èyin lọmọ àgbà tín yàrun ọ̀tẹ̀,
Ọmọ ogun lérè jọjà lọ,
Ìkòyí ọmọ Aporogunjo,
Ìkòyí gbéra ń lé ó dìde ogun yá,
Ọjọ́ Kínní tó nìkòyí kú,
Ṣùgbọ́n mo kúrò lọmọ agbekórùn lọ oko,
Wọn gbélé wọn bo onìkòyí
Àgbède gbede onìkòyí lọ sùn ibè,
Àtàrí onìkòyí Kò sún ibè,
Àwọn lọmọ aṣíjú àpò piri dàgbà ọfà sọ fún,pofún yóò yọ dàgbà ọfà sile,
Ọmọ aku fepo tele koto,
Ọmọ igunnugun balẹ̀ wọn a jori akalamagbo balẹ̀ wọn a jẹdọ.

Èdùmàrè dá ìlú Ìkòyí sí oooo.

http://www.facebook.com/edeyoruba26
http://www.twitter.com/edeyoruba26
http://www.instagram.com/edeyoruba26
https://chat.whatsapp.com/Fb7Vz4kj9WlIunYKtIhmwu

Saturday, 15 October 2016

Ìyá

Ìyá ni wúrà

kíni ọmọ le ṣé lálá sì ìyá,
Iyá tí ó lóyún fún oṣù mẹsan,
Ní ìbẹ̀rẹ̀ oyún ìyá o le jẹ, kólé mú, kò lè sún bẹẹ ni ko leè wo,
Bí oyún ṣe ń dàgbà ní òun ti ńṣe ìyá yí padà ní gbà míràn oyún a sọ pé ìwọ ìyá yí jókòó,
 Bí ìyá kọọ ìnira dé, ipa pàtàkì ní ìyá kó lára ọmọ,
Bí ìyá tún bí ọmọ sáyé tán ìṣe ṣẹ̀ṣẹ̀ bẹ̀rẹ̀,
Bí orí fọ ọmọ ìyá lo nfo,
Bí ara dùn ọmọ ìyá lo ndun,
Bí ọmọ bá sunkún lọ gaju òru ìyá gbé sì ibadi yio sí má jo lairi ìlù,
Bi ọmọ sunkún jù wàá gbọ́ tí bàbá a wípé ọmọ rẹ sunkún dáa lóhùn,
ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìyá ní yio gba aaru kí ọmọ lè bá jẹ́ ènìyàn,
Wúrà tí owo kòlè rà ni ìyá jẹ́,
kò sì òun ti o leè ṣẹlẹ̀ ìyá mi ni ìyá mi,
Kódà kí o ma já itó ìyá mi ni ìyá mi,
Kódà bí ó má bu igi jẹ ìyá mi ìyá mi ni gbogbo ìgbà.
Ìyá ni wúrà iyebíye tí owó kò lè rà.
Kí Ẹlẹ́dàá jẹ kí gbogbo ìyá wá pé fún wá Àmín oooo
Àwọn tí wọn kò sì ní ìyá láyé mọ kí Èdùmàrè jogún ẹni tí yíò ṣe ìyá fún wọn. Kí Èdùmàrè fi ọ̀run ké àwọn ìyá tí ó ti kú.

#ÀmínÀṣẹÈdùmàrè





http://www.instagram.com/edeyoruba26
http://www.facebook.com/edeyoruba26
http://www.twitter.com/edeyoruba26
https://chat.whatsapp.com/Fb7Vz4kj9WlIunYKtIhmwu

Saturday, 1 October 2016

Orílè èdè Nàìjíríà

Muso muso muso orílè èdè Nàìjíríà pé ọdún merindilogota aráyé ẹ bá wa jó aráyé ẹ bá wa yọ.
Orílè èdè Nàìjíríà, orílè èdè abínibí mi, ó pé ọdún merindilogota tí a ti gba òmìnira kúrò lọ́wọ́ òyìnbó amúnisìn, nínú to lórí tẹlémù ló ń dùn. Àwọn òyìnbó gbẹ́ ọ̀pá àṣẹ fún ologbe Tafawa Balewa, ṣùgbọ́n pẹ̀lú ẹ̀ta inú àti Áì sọ̀kan gbogbo ọmọ orílè èdè Nàìjíríà a kò fi bẹẹ ni ìlọsíwájú ní orílè èdè wa. Gbogbo àwọn tí wọn ṣe tán láti jẹ kí orílè èdè Nàìjíríà tẹsíwájú pípa ni àwọn ọ̀tá ìlọsíwájú ń pá wọn. Àwọn èèkàn ńlá ńlá tí wọn jẹ kí a gba òmìnira kúrò lọ́wọ́ òyìnbó amúnisìn ni
Ọbafemi Awolowo, Ahmadu Bello, Anthony Enahoro, Nnamdi Azikuwe, Tafawa Balewa pẹ̀lú Sámúẹ́lì Ladoke Akintola àti bẹẹ bẹẹ lọ?
Tí ó jé wípé ohùn tí gbogbo àwọn wọ̀nyí ni lọ́kàn kí a tó gba òmìnira ní gbogbo àwọn tí wọn dárí wá ní gbogbo ohun tí ó ṣẹlẹ̀ sí wa yí kò ní ṣẹlẹ̀, ṣùgbọ́n kò sí ẹnì tí ó ma fi ọbẹ̀ tónu je ìṣù.
Kò ti peju láti yi gbogbo nǹkan padà, ṣùgbọ́n láti yí padà ó wà lọ́wọ́ èmi àti ìwọ, ẹ má jẹ́ kí a má sọ wípé mio fẹ́ràn òsèlú nítorí pé tí àwa ti a rò wípé a lè tún ṣe bá ń sọ wípé mi o fẹ́ràn òṣèlú àwọn tí ó bàjé lá má dibo fún pẹ̀lú èyí kò ní sí ìlọsíwájú ní orílè èdè Nàìjíríà wá.
Láti tún orílè èdè Nàìjíríà ṣe ọwọ́ tèmi àti tiẹ̀ ló wà.
A kú ọdún ayajo òmìnira ọ̀pọ̀lọpọ̀ ẹ laa ṣe ooooo
Dìde ẹ̀yin ará
Wa jepe Nàìjíríà ,
ka fife sinlee wa,
pekókun àtigbagbọ ,
kíṣé àwọn akọni wa,
ko ma se ja sasan,
kà sin tọkàn~tara,
Ilé tòmìnira ,
àlàáfíà sọ dòkan
Mo ṣe ìlérí fún Orílẹ̀ -Èdè mi Nàìjíríà,
Láti jẹ olódodo,
Ẹniti ó ṣeé fọkàn tán,
Àti olotito èniyàn,
Láti sìn pẹ̀lú gbogbo agbára mi,
Láti sa ipá mi gbogbo fún Ìsòkan re,
Àti láti gbe e ga fún iyì àti ògo re.
Kí olúwa kí ó rán mi lọ́wọ́. (Àmín)