Tuesday, 18 April 2017

Ayeye odun kan

ifọrọwanilẹnuwo....
                                                             1) #Kiniorúkọyín?
Orúkọ mi Semiat Olufunke Tiamiyu, ọ̀kan lára àwọn olùdarí ojú ìwé Èdè Yorùbá tí ó rẹwà.
                                                          2) #KíniEńṣelónìí?
A ń ṣe ayẹyẹ wípé ojú ìwé Èdè Yorùbá tí ó rẹwà pé ọdún kan tí a ti gbé kalẹ̀.
                                                         3) #kílegbàléròtíẹfidáojúìwéyìísílè?
Ohun tí mo gbà lérò pò, máa kàn sọ díè nínú è
1) Ní orílẹ̀ èdè Nàìjíríà tí a ti wá ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn òbí àti alágbàtọ́ ni ó jé wípé tí ẹ bá lọ kíwọn tí ẹ ń sọ Yorùbá ohun tí wọ́n àá sọ ní wípé ẹ má sọ Yorùbá sí àwọn ọmọ yìí.
2) Ní orílẹ̀ èdè United Kingdom tí mo wà, tí èmi àti àwọn ọ̀rẹ́ tí wọn jẹ́ Yorùbá bá jọ jáde wọ́n á ní kí n má sọ Yorùbá nítorí pé Yorùbá mi ti kijú (strong Yorùbá accent). Ẹyin máa ń bà mí nínú jẹ́ púpọ̀ débi wípé mo yẹra fún àwọn ọ̀rẹ́ wọ̀nyí.
3) ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ọmọ Yorùbá ti ó jé wípé ó kọ ilà (Tribal mark) sí ojú wọn ní orílẹ̀ èdè United Kingdom ti mo bá kí irú ẹni bẹẹ pẹ̀lú èdè Yorùbá, èdè Gẹ̀ẹ́sì ni wọn a fi dáhùn. Lẹ́yìn tí ó burú jáì. Ìwọ̀nyí àti ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìrírí mi ni ó faa tí a fi dá ojú ìwé yìí sílè.
4) Nígbàtí mo wà ní ilé ìwé alákòbẹ̀rẹ̀ àti gírámà àwọn olùkọ́ wá a máa sọ wípé ẹnikẹ́ni kò gbọdọ̀ sọ Yorùbá wọn àá sì ma pèé ni (Vernacular) ẹnikẹ́ni tí ó bá sọọ wọn fi ìyà jẹ ọmọ bẹẹ.
                                         4) #KíẹléròpéaleṣetíèdèYorùbákòfiníparun?
Ohun tí a lè ṣe pọ̀;
1) Àwọn òbí àti alágbàtọ́ ni wọ́n ní iṣẹ́ láti ṣe látàrí mi má sọ èdè Yorùbá sí àwọn ọmọ wọn.
2) Àwọn ìjọba wa ni láti gbé ètò kan kalẹ pàápàá jù lọ fún àwọn ilé ẹ̀kọ́ aladani láti máa kọ èdè Yorùbá ní ilé ìwé wọn, kí wọn sì tún máa lò ó ti ẹnikẹ́ni bá fẹ́ wo ilé ìwé gíga (University).
3) Èmi àti ìwọ náà ni iṣẹ́ láti ṣe látàrí mi máa wọ aṣọ ilé wa, oúnjẹ ilé wa àti ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn àṣà àti ìṣe ilé Yorùbá.
                                                                       #Ìdúpẹ́:
Àkókò mo dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run ti o fún mi ní iwonba ọgbọ́n àti ìmò nípa èdè Yorùbá, mo tún dúpẹ́ lọ́wọ́ àwọn òbí mi àti mọ̀lébí pàápàá jù lọ ìyá ìyá mi (Grandmother) tí ó ti kú báyìí (kí Ọlọ́run bá mi fi ọ̀run ke), mo tún dúpẹ́ lọ́wọ́ Adé orí mi Mubarak Damilare Tiamiyu fún atileyin àti ìwúrí tí wọ́n ṣe fún. Mo wá dúpẹ́ lọ́wọ́ gbogbo olólùfẹ́ ojú ìwé yìí tí wọ́n tí ń tẹ́lẹ̀ wá láti ọjọ́ kìíní títí di òní, mo gbaa ladura wípé èdùmàrè òní pa iná ìfẹ́ wa, èdè Yorùbá náà o sì ni parun.




Monday, 17 April 2017

Àlọ́ yìí dá lórí Ilẹ̀ Àti Ọlọ́run.

Àlọ́ ooo 
Àlọ́ ọọọ 
Àlọ́ yìí dá lórí Ilẹ̀ Àti Ọlọ́run. 



Ní ayé àtijó, ọ̀rẹ́ ni ilẹ̀ àti Ọlọ́run. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ibùgbé wọn jìnà sí ara wọn, àwọn méjèèjì a máa wá ara wọn. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìgbà ni Ọlọ́run máa ń sọ̀kalẹ̀ láti wá bá ilẹ̀ ṣeré. Ní ọjọ́ kan, àwọn méjèèjì pinnu láti dè'gbẹ́ lọ kí àwo lè pa ẹran. Wọ́n dẹ ìgbẹ́ títí, eku ẹmọ́ kan ni wọ́n rí pa. Ọlọ́run sọ wípé òun lẹ̀gbọ́n, nítorí ìdí èyí, òun ni òun yíò mú èyí tó pọ̀ níbẹ̀. Ilẹ̀ náà fàáké kọ́rí ó ní òun ni àgbà tí ó gbọ́dọ̀ mú èyí tí ó pọ̀. Ìjà yìí pọ̀ títọ tí Ọlọ́run fi bínú lọ sí ọ̀run tí ilẹ̀ náà sì bínú lọ. Kí ló wá ṣẹlẹ̀ ni pé òjò kọ̀ kò rọ̀, àgbàdo pọ̀n'pẹ́ kò gbó,ọmọge lóyún oyún gbẹ mọ́ wọn lára, akérémọdọ̀ w'ẹ̀wù ìràwé. Iyán yìí mú títí tí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn bẹ̀rẹ̀ síí kú.

Nígbà tí ó ṣe, ọba ìlú wá eéjì kún ẹẹ́ta, ó lọ oko aláwò. Babaláwo sọ fún un pé wọn gbọdọ̀ ṣe ètùtù. Ohun tí wọn yíò ṣe náà ni kí wọn gbé ẹbọ ló sí ọ̀run. Kò sí ẹni tí ó yọjú láti gbé ẹbọ yìí bí kò ṣe ẹyẹ Igún. Igún gbé ẹbọ ó di ọ̀nà ọ̀run. Ṣùgbọ́n bí ó ti ń lọ ní ó bẹ̀rẹ̀ sí kọrin báyìí pé:

Igún:_________Olúnréte
Elégbè:_______Àjànréte jàà
Igún:_________Olúnréte
Elégbè:_______Àjànréte jàà
Igún:_________Ilé ohun Ọlọ́run
Elégbè:_______Àjànréte jàà
Igún:_________ Wọ́n p'eku ẹmọ́ kan
Elégbè:_______Àjànréte jàà
Igún:_________Ọlọ́run L'óun l'ẹ̀gbọ́n
Elégbè:_______Àjànréte jàà
Igún:_________Ilé L'óun l'àgbà
Elégbè:_______Àjànréte jàà
Igún:_________Ọlọ́run bínú ó lọ
Elégbè:_______Àjànréte jàà
Igún:_________Ilé bínú ó lọ
Elégbè:_______Àjànréte jàà
Igún:_________ Àgbàdo pọ̀n'pẹ́ kò gbó
Elégbè:_______Àjànréte jàà
Igún:_________ọmọge lóyún oyún gbẹ
Elégbè:_______Àjànréte jàà
Igún:_________Olúnréte
Elégbè:_______Àjànréte jàà

Bí igún ti gbé ẹbọ dé ọ̀run ni Ọlọ́run gba ẹbọ náà. Èyí jásí pé ẹbọ fín, ẹbọ dà. Bí igún tí gbé ẹbọ ṣílẹ̀ tán tí ó ń bọ̀ wá sí ilé ayé ni òjò bá bẹ̀rẹ̀ sí rọ̀. Òjò yìí l'ágbára púpọ̀ tí ó fi jẹ́ pé gbogbo àwọn ẹyẹ ni wọ́n ti ilẹ̀kùn ilé wọn mọ́ orí. Nígbà tí igún dé, òjò ti gbé ilé rẹ, kò sì rí ibi tí yíò yà sí tàbí f'arapamọ́ si. Ohun tí ó tún wá burú ni pé bí ó bá ti fẹ́ yà sí ilé ẹyẹ kan ni ẹyẹ yìí ó saajẹ ní orí. Àwọn ẹyẹ ṣe eléyìí títí orí igún fi pá títí di òní yìí.

Àlọ́ yìí kọ́ wa wípé kò yẹ kí a fi ibi san oore. Oore ni igún ṣe, ibi ni wọ́n fi ṣan fún un.

#EdeYorubaRewa

Sunday, 9 April 2017

Ìjàpá àti Àna Rẹ̀



Àlọ́ ooo
Àlọ́ ọọọ
Àlọ́ yìí dá lórí #ÌjàpáàtiÀnaRẹ̀
Gbogbo wa ni a ti mọ Ìjàpátìrókò ọkọ Yánníbo gẹ́gẹ́ bí #ọlọ́gbọ́nẹ̀wẹ́ àti #ọ̀kánjúà tí ó sì tún jẹ́ #Tìfunlọ̀ràn.
Ní ọjọ́ kan Ìjàpá gba ilé àna rẹ̀ lọ láti lọ kí wọn. Nígbà tí ó dé ilé àna rẹ̀, wọ́n ṣe #àpọ́nlé rẹ̀ dáadáa. Ṣùgbọ́n bí wọ́n ṣe ṣe aájò Ìjàpá tó, ìwà rẹ̀ kò padà. Ìjàpá rí pé àwọn àna òun ń ṣe ẹ̀wà lórí iná. Ìjàpá ń rò nínú ara rẹ̀ ọ̀nà tí yíò fi bu díè nínú ẹ̀wà náà lọ sí ilé rẹ̀. Dípò kí Ìjàpá tọrọ ẹ̀wà lọ́wọ́ àna rẹ̀, ṣe ni ó ń rò bí yíò ṣe jí nínú ẹ̀wà náà.
Ìjàpá wo yányànyán kò rí ẹnìkankan ni ó bá rápálá lọ sí ibi tí wọ́n ti ń ṣe ẹ̀wà tí ó sì ń hooru yèèè. Ìjàpá bu díè nínú ẹ̀wà gbígbóná sí inú fìlà rẹ̀, ó sì dée m'órí. Nígbà tí ó ṣe, ẹ̀wà bẹ̀rẹ̀ sí jó Ìjàpá lórí ni ó bá sọ fún àna rẹ̀ pé òun ń lọ sí ilé òun. Àna Ìjàpá sì pinnu láti sìnín sí ojú ọ̀nà Ìjàpá rọ àna rẹ̀ títí kí ó má sin òun ṣùgbọ́n àna rẹ̀ kọ̀ jálẹ̀ pé òun ni lati paá lẹ́sẹ̀ dà.
Bí wọ́n ṣe rìn díè ni ooru ẹ̀wà bẹ̀rẹ̀ sí jó Ìjàpá ní orí. Nígbà tí kò le f'ara dàá mọ́ ni ó bá ti orin bọnu báyìí pé;
Ìjàpá:__________Àna mi mo ní o padà lẹ́yìn mi
Ègbè:__________Ooru ẹ̀wà ń jó mí lórí foofáá
Ìjàpá:__________Àna mi mo ní o padà lẹ́yìn mi
Ègbè:__________Ooru ẹ̀wà ń jó mí lórí foofáá
Ìjàpá:__________Àna mi mo ní o padà lẹ́yìn mi
Ègbè:__________Ooru ẹ̀wà ń jó mí lórí foofáá
Nígbà tí Ìjàpá rí i pé òun kò le mú mọ́ra mọ́ ni ó bá sí fìlà lórí tí ẹ̀wà gbígbóná sì dà sílè fún ìyàlẹ́nu àna Ìjàpá. Ki Ìjàpá tó sí fìlà ooru ẹ̀wà tí bó Ìjàpá lórí. Ojú tí Ìjàpá púpọ̀ ní ọjọ́ yìí.
Èyí ló sì mú kí orí Ìjàpá ó pá títí di òní yìí.
Ìtàn yìí kọ́ wa wípé ojú kòkòrò kò dára.

Tuesday, 4 April 2017

Ìjàpá àti Ajá


Àlọ́ ooo
Àlọ́ ọọọ
Àlọ́ yìí dá fìrìgbagbò
Ó dá lórí #ÌjàpátìrókòọkọYánníbo àti #Ajá
Ní ìlú kan ni ayé àtijó, àwọn ẹranko méjì kan wà tí wọ́n jẹ́ ọ̀rẹ́ tímọ́tímọ́. Àwọn ọ̀rẹ́ méjì náà ni Ìjàpátìrókò ọkọ Yánníbo àti Ajá. Iyàn mú púpọ̀ ní ìlú yìí débi wípé gbogbo igi wọ́wé tán, àgbàdo kọ̀ kò gbó, àwọn ọlọ́mọge lóyún, oyún gbẹ mọ́ wọn lára. Gbogbo akérémọdò wọ ẹ̀wù ìràwé. Iyàn náà mú gan-an ni. Ṣùgbọ́n bí Iyàn tí mú tóo, Ajá kò mọ Iyàn kankan, ṣe ni ara rẹ̀ ń dán yọ̀ọ̀. Bí Ajá ṣe ń dán tí ó tún sanra nínú Iyàn yìí ń kọ Ìjàpá lóminù. Ìjàpá bẹ̀rẹ̀ sí ro ohun tí yíò ṣe.
Nígbà tí ó ṣe Ìjàpá tọ ọ̀rẹ́ rẹ̀ Ajá lọ. Ó bẹ̀ẹ́ pé kí ó dákun ṣàánú òun kí ebi má lu òun àti àwọn ẹbí òun pa. Ajá sọ fún Ìjàpá pé kò wu òun náà kí ebi máa paa ṣùgbọ́n ìwà àgàbàgebè rẹ̀ ni kó jẹ́ kí òun sọ àṣírí ibi tí òun ti ń rí oúnjẹ jẹ. Ìjàpá bẹ Ajá pé òun kò ní dá'lẹ̀, àti pé òun yíò fi ọwọ́ sí ibi tí ọwọ́ gbé.
Nígbà tí ẹ̀bẹ̀ pọ̀, Ajá gbà láti mú Ìjàpá lọ. Ajá mú Ìjàpá lọ sí oko iṣu kan tí a kò mọ ẹni tí ó ni oko náà. Bí wọ́n ṣe dé'bẹ̀ ni Ajá wa iṣu tí ó lerù, ó sì ti múra láti padà sílé. Ṣùgbọ́n ní ti Ìjàpá, ó wa iṣu títí ilẹ̀ fi kún. Nígbà tí ó dìí, ó rí wípé òun kò le gbé, ó ti pọ̀ jù èyí tí òun lè gbé lọ. Ajá bẹ̀rẹ̀ sí pariwo kí ó yára ṣùgbọ́n ọ̀kánjúà ojú rẹ̀ kò jẹ́ kí ó gbọ́ igbe Ajá. Ajá bá bẹ̀rẹ̀ si kọ orin:
Ajá:_________ Ìjàpá dì mọ ń bá
Agbeorin:____ Teremọ́bá-teremọ̀bà tere
Ajá:________ bí ó bá dì mọ́ n ba; Ma súré sẹ́sẹ́ p'oloko; Ma rìnrìn gbẹ̀rẹ̀ pọlọ́jà Ma sòkú ọlọ́jà l'égbèje
Agbeorin:______Teremọ́bá-teremọ̀bà tere
Bí Ajá ṣe ń kọ orin yìí ni ó ń sáré lọ tete, nígbà tí Ìjàpá ń bá iṣu tí ó dì kalẹ̀ yí. Níbi tí Ìjàpá tí ń bá ẹrú iṣu ja ni olóko dé tí ó sì mú Ìjàpá lọ sí ilé Ọba. Ní ilé Ọba, Ìjàpá jẹ́wọ́ pé Ajá ni ó mú òun lọ sí inú oko tí àwọn tí lọ jí iṣu wà. Bí Ajá tí dé ilé ni ó ti mọ̀ pé wàhálà tí dé, ó dá ọgbọ́n, ó di ẹyin adìye sí kọ̀rọ̀ ẹ̀rẹ̀kẹ́ méjèèjì, ó sì ṣe bí ẹni tí ara rẹ̀ kò yá, ó pirọrọ bí ẹni tí ó sùn lọ. Ọba si pàṣẹ pé kí wọ́n lọ mú Ajá tí wọ́n jíṣẹ́ fún un pé ọba ń pè é, ó fi ẹyin tẹ ọkàn nínú ẹyin tí ó fi sí kọ̀rọ̀ ẹ̀rẹ̀kẹ́, ẹyin fọ́, ó sì dà sílè bí ẹni tí èébì gbe. Wọ́n mú Ajá dé ilé ọba ní àpàpàǹdodo. Bí wọ́n ṣe dé ilé ọba tí ọba sì bí léèrè bóyá òun ni ó mú Ìjàpá lọ jí iṣu wà lóko olóko, Ajá ní kí í ṣe òun torí pé òun ti ń ṣe àìsàn fún bíi ọ̀sẹ̀ kan. Bí ó sì ti wí báyìí ni ó tún fi eyín tẹ ẹyin tí ó wà ní kọ̀rọ̀ ẹ̀rẹ̀kẹ́ kejì ó sì dà sílè gọ̀ọ̀rọ̀gọ̀, ó dà bí pé Ajá ń bì. Ọba gba ohun tí Ajá sọ pé ara òun kò yá fún bí ìgbà díè. Ọba wá pàṣẹ pé kí wọ́n ti ojú Ìjàpá yọ idà, kí wọ́n sì ti ẹ̀yìn rẹ̀ ti bọọ.
Ìtàn yìí kọ́ wa wí pé kò yẹ kí á máa ṣe àṣejù sì gbogbo nǹkan.