Àlọ́ ooo
Àlọ́ ọọọ
Àlọ́ yìí dá lórí Ilẹ̀ Àti Ọlọ́run.
Ní ayé àtijó, ọ̀rẹ́ ni ilẹ̀ àti Ọlọ́run. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ibùgbé wọn jìnà sí ara wọn, àwọn méjèèjì a máa wá ara wọn. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìgbà ni Ọlọ́run máa ń sọ̀kalẹ̀ láti wá bá ilẹ̀ ṣeré. Ní ọjọ́ kan, àwọn méjèèjì pinnu láti dè'gbẹ́ lọ kí àwo lè pa ẹran. Wọ́n dẹ ìgbẹ́ títí, eku ẹmọ́ kan ni wọ́n rí pa. Ọlọ́run sọ wípé òun lẹ̀gbọ́n, nítorí ìdí èyí, òun ni òun yíò mú èyí tó pọ̀ níbẹ̀. Ilẹ̀ náà fàáké kọ́rí ó ní òun ni àgbà tí ó gbọ́dọ̀ mú èyí tí ó pọ̀. Ìjà yìí pọ̀ títọ tí Ọlọ́run fi bínú lọ sí ọ̀run tí ilẹ̀ náà sì bínú lọ. Kí ló wá ṣẹlẹ̀ ni pé òjò kọ̀ kò rọ̀, àgbàdo pọ̀n'pẹ́ kò gbó,ọmọge lóyún oyún gbẹ mọ́ wọn lára, akérémọdọ̀ w'ẹ̀wù ìràwé. Iyán yìí mú títí tí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn bẹ̀rẹ̀ síí kú.
Nígbà tí ó ṣe, ọba ìlú wá eéjì kún ẹẹ́ta, ó lọ oko aláwò. Babaláwo sọ fún un pé wọn gbọdọ̀ ṣe ètùtù. Ohun tí wọn yíò ṣe náà ni kí wọn gbé ẹbọ ló sí ọ̀run. Kò sí ẹni tí ó yọjú láti gbé ẹbọ yìí bí kò ṣe ẹyẹ Igún. Igún gbé ẹbọ ó di ọ̀nà ọ̀run. Ṣùgbọ́n bí ó ti ń lọ ní ó bẹ̀rẹ̀ sí kọrin báyìí pé:
Igún:_________Olúnréte
Elégbè:_______Àjànréte jàà
Igún:_________Olúnréte
Elégbè:_______Àjànréte jàà
Igún:_________Ilé ohun Ọlọ́run
Elégbè:_______Àjànréte jàà
Igún:_________ Wọ́n p'eku ẹmọ́ kan
Elégbè:_______Àjànréte jàà
Igún:_________Ọlọ́run L'óun l'ẹ̀gbọ́n
Elégbè:_______Àjànréte jàà
Igún:_________Ilé L'óun l'àgbà
Elégbè:_______Àjànréte jàà
Igún:_________Ọlọ́run bínú ó lọ
Elégbè:_______Àjànréte jàà
Igún:_________Ilé bínú ó lọ
Elégbè:_______Àjànréte jàà
Igún:_________ Àgbàdo pọ̀n'pẹ́ kò gbó
Elégbè:_______Àjànréte jàà
Igún:_________ọmọge lóyún oyún gbẹ
Elégbè:_______Àjànréte jàà
Igún:_________Olúnréte
Elégbè:_______Àjànréte jàà
Bí igún ti gbé ẹbọ dé ọ̀run ni Ọlọ́run gba ẹbọ náà. Èyí jásí pé ẹbọ fín, ẹbọ dà. Bí igún tí gbé ẹbọ ṣílẹ̀ tán tí ó ń bọ̀ wá sí ilé ayé ni òjò bá bẹ̀rẹ̀ sí rọ̀. Òjò yìí l'ágbára púpọ̀ tí ó fi jẹ́ pé gbogbo àwọn ẹyẹ ni wọ́n ti ilẹ̀kùn ilé wọn mọ́ orí. Nígbà tí igún dé, òjò ti gbé ilé rẹ, kò sì rí ibi tí yíò yà sí tàbí f'arapamọ́ si. Ohun tí ó tún wá burú ni pé bí ó bá ti fẹ́ yà sí ilé ẹyẹ kan ni ẹyẹ yìí ó saajẹ ní orí. Àwọn ẹyẹ ṣe eléyìí títí orí igún fi pá títí di òní yìí.
Àlọ́ yìí kọ́ wa wípé kò yẹ kí a fi ibi san oore. Oore ni igún ṣe, ibi ni wọ́n fi ṣan fún un.
#EdeYorubaRewa
No comments:
Post a Comment