Sunday, 25 June 2017

Àlọ́ Apá kejì

Àyipadà dé fún Ògbójú-ọdẹ ti ó di Ẹlẹ́mu tóó bẹ̀ ti àwọn ará ilú ṣe akiyesi àyipadà yi.  Yorùbá ni “ojú larí, ọ̀rẹ́ ò dénú”. Ìjàpá ọlọ́gbọ́n ẹ̀wẹ́ sọ ara rẹ̀ di ọrẹ kòrí kòsùn pẹ̀lú Ògbójú-ọdẹ nitori àti mọ idi ọrọ̀ rẹ.  Laipẹ, àrùn Ṣọ̀pọ̀ná bo Ògbójú-ọdẹ eleyi dá iṣẹ́ àti gbé ẹmu fún àwọn Ará Ọ̀run dúró.  Gẹgẹbi ọ̀rẹ́ ó bẹ Ìjàpá pé ki ó bá ohun bẹ̀rẹ̀ si gbé ẹmu lọ fún àwọn Ará Ọ̀run.  Ó ṣe ikilọ fún Ìjàpá bi ikilọ ti àwọn Ará Ọ̀run fi silẹ̀.  Ìjàpá, bẹ̀rẹ̀ si gbé ẹmu lọ, ni ọjọ́ keji ti ó ri owó rẹpẹtẹ ti àwọn Ará Ọ̀run kó si idi agbè ẹmu àná, ó pinu lati mọ idi abájọ.

Ìjàpá fi ara pamọ́ si igbó lati wo bi àwọn Ará Ọ̀run ti ńmu ẹmu. Ohun ti ó ri yàá lẹ́nu, ó ri Ori, Ẹsẹ̀, Ojú, Apá àti àwọn ẹ̀yà ara miran ti wọn dá dúró, ti wọn si bẹ̀rẹ̀ si mu ẹmu. Ìjàpá  bẹ̀rẹ̀ si fi àwọn Ará Ọ̀run ṣe yẹ̀yẹ́.  Nigbati wọn gbọ, wọ́n le lati pá ṣùgbọ́n, Ìjàpá sá àsálà fún ẹmi rẹ, ó kó wọ inú ihò, wọn kò ri pa.

Ògbójú-ọdẹ reti titi ki Ìjàpá kó owó ẹmu dé.  Nigbati Ìjàpá dé, ó gbé irọ́ kalẹ̀ pé olè dá ohun lọ́nà, wọn gba gbogbo owó ẹmu lọ ni ohun ṣe pẹ́.

Ara Ògbójú-ọdẹ ya, ó gbé ẹmu lọ fún ara-orun gẹgẹbi iṣe rẹ tẹ́lẹ̀ lai mọ iwà àkóbá ti Ìjàpá ti hù silẹ̀.

Àwọn Ará-Ọ̀run wọ ijàkàdi pẹ̀lú Ògbójú-ọdẹ, nitori ó rú òfin ikilọ ti wọn fun.  Nitori imọ̀ ti ó ni lẹ́nu iṣẹ Ọdẹ, Ará-Ọ̀run ko ri Ògbójú-ọdẹ pa.  Lẹhin ijàkàdi, ó ṣe àlàyé pé ara ohun ni kò yá, ó fi àpá han, pé nitori eyi ni ohun ṣe bẹ ọ̀rẹ́ ohun Ìjàpá ki ó bá ohun gbé ẹmu lọ fún wọn.

Wọn ṣe àlàyé ohun ti Ìjàpá ti ó pè ni ọ̀rẹ́ rẹ ṣe fún wọn.  Ará-Ọ̀run dariji Ògbójú-ọdẹ pẹ̀lú ikilọ pé ki o maṣe gbára lé ọ̀rẹ́. Wọn ni ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọ̀rẹ́ ò ṣé fi okùn ọlà han, nítorí ọ̀pọ̀ ọ̀tá ló ńṣe bi ọ̀rẹ́ nitori àti jẹ.

Ẹsẹ́ púpọ̀ fún ìfojúsọ́nà yín.
#EdeYorubaRewa


Àlọ́ Apá kinni

Ọkunrin kan wa láyé àtijọ́, Ògbójú-ọdẹ ni, ṣùgbọ́n bi ó ti pa ẹran tó, kò fi dá nkan ṣe.  Ọ̀pọ̀ igbà, ki ri ẹran ti ó bá pa tà, o ma ńpin fún ará ilú ni.  Nigbati kò ri ẹran pa mọ́, ó di Ọdẹ-apẹyẹ.

Ni ọjọ kan, ògbójú-ọde yi ri ẹyẹ Òfú kan, ṣùgbọ́n ọta ibọn kan ṣoṣo ló kù ninú ibọn rẹ.  Gẹgẹbi Ògbójú-ọdẹ, o yin ẹyẹ Òfú ni ibọn, ọta kan ṣoṣo yi si báa.  Ó bá wọ igbó lọ lati gbé ẹyẹ ti ó pa, lai mọ̀ pé ẹyẹ yi kò kú.  Ó ṣe akitiyan lati ri ẹyẹ́ yi mu, kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀ ó bẹ̀rẹ̀ si wọ igbó lọ titi tó fi ṣi ọ̀nà dé ilẹ̀ àwọn Ará Ọ̀run àwọn ti wọn ńpè ni Abàmi-ẹ̀dá.

Inu bi àwọn Ará Ọ̀run nitori Ògbójú-ọdẹ yi jálu ipàdé wọn.  Wọn gbamú, wọn ni ki ó ṣe àlàyé bi ó ṣe dé ilẹ̀ wọn ki àwọn tó pá.  Ọdẹ ṣe àlàyé ohun ti ojú rẹ ti ri nipa iṣẹ́ àti jẹ àti gbogbo ohun ti ojú rẹ ti ri lẹ́nu iṣẹ́ ọdẹ.  Àwọn Ará-Ọ̀run ṣe àánú rẹ, wọn bèrè pé ṣe ó lè dá ẹmu, ó ni ohun lè dá ẹmu diẹ-diẹ.  Wọn gbaa ni iyànjú pé ki o maṣe fi ojú di iṣẹ kankan, nitori naa, ki ó bẹ̀rẹ̀ si dá ẹmu fún àwọn.

Wọn ṣe ikilọ pe, bi ó bá ti gbé ẹmu wá, kò gbọdọ̀ wo bi àwọn ti ńmu ẹmu, ki ó kàn gbé ẹmu silẹ ki o si yi padà lai wo ẹ̀hin.  Bi ó bá rú òfin yi, àwọn yio pa.  Ọdẹ bẹ̀rẹ̀ si gbé ẹmu lọ fún ara orun.  Bi ó bá gbé ẹmu dé, a bẹ̀rẹ̀ si kọrin báyìí:

Ará Ọ̀run, Ará Ọ̀run------------ Ìnọ̀mbà téré, tere múdè, ìnọ̀mbà

Ará Ọ̀run, Ará Ọ̀run o,---------- Ìnọ̀mbà téré, tere múdè, ìnọ̀mbà

Ki lo wá ṣe n’ilẹ̀ yi o-------------- Ìnọ̀mbà téré, tere múdè, ìnọ̀mbà

Ẹmu ni mo wá dá,----------------- Ìnọ̀mbà téré, tere múdè, ìnọ̀mbà

Èlèló lẹmu rẹ------------------Ìnọ̀mbà téré, tere múdè, ìnọ̀mbà

Ọ̀kànkàn ẹgbẹ̀wá,-----------------Ìnọ̀mbà téré, tere múdè, ìnọ̀mbà

Gbẹ́mu silẹ ko maa lọ------------Ìnọ̀mbà téré, tere múdè, ìnọ̀mbà

Ará Ọ̀run, Ará Ọ̀run o,----------------Ìnọ̀mbà téré, tere múdè, ìnọ̀mbàaa

Lẹ́yìn èyi á gbé ẹmu silẹ á yi padà lai wo ẹ̀hin gẹgẹ bi ikilọ Ará Ọ̀run. Ni ọjọ́ keji, á bá owó ni idi agbè ti ó fi gbé ẹmu tàná wá.
Ẹ kú ojú lọ́nà fún ìyókù.

#EdeYorubaRewa