Sunday 25 June 2017

Àlọ́ Apá kinni

Ọkunrin kan wa láyé àtijọ́, Ògbójú-ọdẹ ni, ṣùgbọ́n bi ó ti pa ẹran tó, kò fi dá nkan ṣe.  Ọ̀pọ̀ igbà, ki ri ẹran ti ó bá pa tà, o ma ńpin fún ará ilú ni.  Nigbati kò ri ẹran pa mọ́, ó di Ọdẹ-apẹyẹ.

Ni ọjọ kan, ògbójú-ọde yi ri ẹyẹ Òfú kan, ṣùgbọ́n ọta ibọn kan ṣoṣo ló kù ninú ibọn rẹ.  Gẹgẹbi Ògbójú-ọdẹ, o yin ẹyẹ Òfú ni ibọn, ọta kan ṣoṣo yi si báa.  Ó bá wọ igbó lọ lati gbé ẹyẹ ti ó pa, lai mọ̀ pé ẹyẹ yi kò kú.  Ó ṣe akitiyan lati ri ẹyẹ́ yi mu, kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀ ó bẹ̀rẹ̀ si wọ igbó lọ titi tó fi ṣi ọ̀nà dé ilẹ̀ àwọn Ará Ọ̀run àwọn ti wọn ńpè ni Abàmi-ẹ̀dá.

Inu bi àwọn Ará Ọ̀run nitori Ògbójú-ọdẹ yi jálu ipàdé wọn.  Wọn gbamú, wọn ni ki ó ṣe àlàyé bi ó ṣe dé ilẹ̀ wọn ki àwọn tó pá.  Ọdẹ ṣe àlàyé ohun ti ojú rẹ ti ri nipa iṣẹ́ àti jẹ àti gbogbo ohun ti ojú rẹ ti ri lẹ́nu iṣẹ́ ọdẹ.  Àwọn Ará-Ọ̀run ṣe àánú rẹ, wọn bèrè pé ṣe ó lè dá ẹmu, ó ni ohun lè dá ẹmu diẹ-diẹ.  Wọn gbaa ni iyànjú pé ki o maṣe fi ojú di iṣẹ kankan, nitori naa, ki ó bẹ̀rẹ̀ si dá ẹmu fún àwọn.

Wọn ṣe ikilọ pe, bi ó bá ti gbé ẹmu wá, kò gbọdọ̀ wo bi àwọn ti ńmu ẹmu, ki ó kàn gbé ẹmu silẹ ki o si yi padà lai wo ẹ̀hin.  Bi ó bá rú òfin yi, àwọn yio pa.  Ọdẹ bẹ̀rẹ̀ si gbé ẹmu lọ fún ara orun.  Bi ó bá gbé ẹmu dé, a bẹ̀rẹ̀ si kọrin báyìí:

Ará Ọ̀run, Ará Ọ̀run------------ Ìnọ̀mbà téré, tere múdè, ìnọ̀mbà

Ará Ọ̀run, Ará Ọ̀run o,---------- Ìnọ̀mbà téré, tere múdè, ìnọ̀mbà

Ki lo wá ṣe n’ilẹ̀ yi o-------------- Ìnọ̀mbà téré, tere múdè, ìnọ̀mbà

Ẹmu ni mo wá dá,----------------- Ìnọ̀mbà téré, tere múdè, ìnọ̀mbà

Èlèló lẹmu rẹ------------------Ìnọ̀mbà téré, tere múdè, ìnọ̀mbà

Ọ̀kànkàn ẹgbẹ̀wá,-----------------Ìnọ̀mbà téré, tere múdè, ìnọ̀mbà

Gbẹ́mu silẹ ko maa lọ------------Ìnọ̀mbà téré, tere múdè, ìnọ̀mbà

Ará Ọ̀run, Ará Ọ̀run o,----------------Ìnọ̀mbà téré, tere múdè, ìnọ̀mbàaa

Lẹ́yìn èyi á gbé ẹmu silẹ á yi padà lai wo ẹ̀hin gẹgẹ bi ikilọ Ará Ọ̀run. Ni ọjọ́ keji, á bá owó ni idi agbè ti ó fi gbé ẹmu tàná wá.
Ẹ kú ojú lọ́nà fún ìyókù.

#EdeYorubaRewa


No comments:

Post a Comment