Àyipadà dé fún Ògbójú-ọdẹ ti ó di Ẹlẹ́mu tóó bẹ̀ ti àwọn ará ilú ṣe akiyesi àyipadà yi. Yorùbá ni “ojú larí, ọ̀rẹ́ ò dénú”. Ìjàpá ọlọ́gbọ́n ẹ̀wẹ́ sọ ara rẹ̀ di ọrẹ kòrí kòsùn pẹ̀lú Ògbójú-ọdẹ nitori àti mọ idi ọrọ̀ rẹ. Laipẹ, àrùn Ṣọ̀pọ̀ná bo Ògbójú-ọdẹ eleyi dá iṣẹ́ àti gbé ẹmu fún àwọn Ará Ọ̀run dúró. Gẹgẹbi ọ̀rẹ́ ó bẹ Ìjàpá pé ki ó bá ohun bẹ̀rẹ̀ si gbé ẹmu lọ fún àwọn Ará Ọ̀run. Ó ṣe ikilọ fún Ìjàpá bi ikilọ ti àwọn Ará Ọ̀run fi silẹ̀. Ìjàpá, bẹ̀rẹ̀ si gbé ẹmu lọ, ni ọjọ́ keji ti ó ri owó rẹpẹtẹ ti àwọn Ará Ọ̀run kó si idi agbè ẹmu àná, ó pinu lati mọ idi abájọ.
Ìjàpá fi ara pamọ́ si igbó lati wo bi àwọn Ará Ọ̀run ti ńmu ẹmu. Ohun ti ó ri yàá lẹ́nu, ó ri Ori, Ẹsẹ̀, Ojú, Apá àti àwọn ẹ̀yà ara miran ti wọn dá dúró, ti wọn si bẹ̀rẹ̀ si mu ẹmu. Ìjàpá bẹ̀rẹ̀ si fi àwọn Ará Ọ̀run ṣe yẹ̀yẹ́. Nigbati wọn gbọ, wọ́n le lati pá ṣùgbọ́n, Ìjàpá sá àsálà fún ẹmi rẹ, ó kó wọ inú ihò, wọn kò ri pa.
Ògbójú-ọdẹ reti titi ki Ìjàpá kó owó ẹmu dé. Nigbati Ìjàpá dé, ó gbé irọ́ kalẹ̀ pé olè dá ohun lọ́nà, wọn gba gbogbo owó ẹmu lọ ni ohun ṣe pẹ́.
Ara Ògbójú-ọdẹ ya, ó gbé ẹmu lọ fún ara-orun gẹgẹbi iṣe rẹ tẹ́lẹ̀ lai mọ iwà àkóbá ti Ìjàpá ti hù silẹ̀.
Àwọn Ará-Ọ̀run wọ ijàkàdi pẹ̀lú Ògbójú-ọdẹ, nitori ó rú òfin ikilọ ti wọn fun. Nitori imọ̀ ti ó ni lẹ́nu iṣẹ Ọdẹ, Ará-Ọ̀run ko ri Ògbójú-ọdẹ pa. Lẹhin ijàkàdi, ó ṣe àlàyé pé ara ohun ni kò yá, ó fi àpá han, pé nitori eyi ni ohun ṣe bẹ ọ̀rẹ́ ohun Ìjàpá ki ó bá ohun gbé ẹmu lọ fún wọn.
Wọn ṣe àlàyé ohun ti Ìjàpá ti ó pè ni ọ̀rẹ́ rẹ ṣe fún wọn. Ará-Ọ̀run dariji Ògbójú-ọdẹ pẹ̀lú ikilọ pé ki o maṣe gbára lé ọ̀rẹ́. Wọn ni ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọ̀rẹ́ ò ṣé fi okùn ọlà han, nítorí ọ̀pọ̀ ọ̀tá ló ńṣe bi ọ̀rẹ́ nitori àti jẹ.
Ẹsẹ́ púpọ̀ fún ìfojúsọ́nà yín.
#EdeYorubaRewa
No comments:
Post a Comment