Tuesday, 22 November 2016

Orin Ìbejì

Ẹepo ńbe
Ẹ̀wà ńbe oo
Ẹepo ńbe
Ẹ̀wà ńbe oo
Àyà mi o já ooo ee
Àyà mi o ja lati b'ìbejì o
Ẹepo ńbe ẹ̀̀wà ńbe oo.

Edun ló ní njó,
Mo jó,
Èmi kò lè torí ijó
Kọ edun
Edun ló ní n jó,
Mo jo

Owó mi méjèèjì mo fí gbé ìbejì,
Owó mi méjèèjì mo fí gbé ìbejì,
Ẹnikan kìí fowó kan gbé ìbejì,
Owó mi méjèèjì mo fí gbé ìbejì.

Èdùmàrè fún wa lọmọ bíi ìbejì bí, kí gbogbo ọmọ tí a bí dàgbà kí wọn dògbó....

Àmín Àṣẹ Èdùmàrè.....

https://chat.whatsapp.com/Fb7Vz4kj9WlIunYKtIhmwu

Thursday, 3 November 2016

Bójú Bóra

Ọ̀rọ̀ kan gbé mi nínú,
Tí mo fẹ́ kẹ bámi dá sí,
Kí gbogbo mùtúmùwà fetí gbéyàwó ẹ,
Ọ̀rọ̀ àwọn ọmọge tó ń bójú Bóra,
Ló fa ariwo,
Ìyàwó adúláwọ̀,
Tó fẹ́ para rẹ̀ láwọ̀dà,
Bí wọ́n bá bàwó jẹ́ tán,
Wọ́n á wá fín pátápátá,
Ọsẹ abójú ni wọ́n ń wá kiri,
Atíkè abàwọ̀jẹ́ ni wọ́n ń lò lọ́pọ̀ ìgbà,

Wọ́n kìí dúró bí Ẹlẹ́dàá ṣe dá wọ́n,
Ń ṣe ní wọ́n ń bàwọ̀ jẹ́,
Ọ̀pọ̀lọpọ̀ làwọn òbí ò dà mọ̀ mọ́,
Nítorí ìgbà t'ọmọ ó kúrò nílé,
Ń ṣe ló dúdú bíi kóró isin,
Ìpadàbọ́ Odùduwà rèé,
Ọmọ tí d'òyìnbó atọwọdá,
Ojú lójú "kóòkì" ẹsẹ̀ lẹsẹ̀ "fàntà",
Oòrùn ti ń jáde lára wọn kò lẹ́gbẹ́,

Ní ìgbẹ̀yìn Ayé abójúbóra,
Kii suwòn,
Kí ǹkan má ṣe ara wọn ni
Búté búté ni ara wọn yíò má já,
Mo rọ gbogbo ọmọge adúláwọ̀ kí á wà bí èdùwà ṣe dá wa.

#Mosọyí, #modúrónaa.

Mo sì dúpẹ́ Púpọ̀ lọ́wọ́ #Ẹlẹ́dàá tó dá mi sí ilé #Adúláwọ̀,

#Ìwońkọ

https://instagram.com/edeyorubarewa

https://twitter.com/edeyorubarewa

https://facebook.com/edeyorubarewa

https://chat.whatsapp.com/Fb7Vz4kj9WlIunYKtIhmwu

https://edeyorubatiorewa.blogspot.com.ng/

Wednesday, 2 November 2016

Ta ló fẹ́ni dénú

Onílé apá ọ̀tún ò fojú irẹ woni,
Ìmọ̀ràn ìkà ni tòsí ń gbà,
Kájáde Kájáde ni tọ̀ọ́kan ile ń wí,
Ọmọ Adámọ níí fẹ̀jẹ̀ sínú,
Tutọ́ funfun bàláú jáde,
Bí wọn rí o lókèèrè,
Ti wọn pọ́n ọ́ lè tẹ̀ríntẹ̀yẹ̀,
Ohun ti ń bẹ nínú wọn,
Ó kọjá àpèjúwe,
Bí a bá ṣí inú ẹlòmíràn,
Ejò ṣèbé, ọkà, àkeekèé,
Agbọ́n, oyin tamo ṣánkọ,
Pẹ̀lú ọ̀pọ̀ ohun olóró mìíràn,
Là bá níkùn ọmọ ènìyàn,
Ṣùgbọ́n inú kìí ṣegbá,
Ojú lásán la rí,
Ọrẹ ò dénú,
Sàṣà èèyàn ni i féni lẹ́yìn,
"Bá ò sí nílé, tajá tẹran ni i fẹ ni lójú ẹni"
 Inú mi ni mo mọ
Ń ò mọ tẹlòmìíràn...

#Ìwo ń kọ́

https://instagram.com/edeyorubarewa

https://twitter.com/edeyorubarewa

https://facebook.com/edeyorubarewa

https://chat.whatsapp.com/Fb7Vz4kj9WlIunYKtIhmwu

https://edeyorubatiorewa.blogspot.com.ng/

Tuesday, 1 November 2016

Ewì ìkìlọ̀

Ikú ń pa alágẹmọ,
Tí ń yọ́ rin lórí ewé,
Ambèlètasé ọ̀pọ̀lọ́,
Tí ń jan ara rẹ̀ mọ́lẹ̀,
Ẹ̀sọ̀, ẹ̀sọ̀ láyé gbà,
Ìgbìn ò lápá,
Bẹẹ ni kò lẹ́sẹ̀,
Ẹ̀sọ̀, ẹ̀sọ̀ n'ìgbìn mà ń gun igi,
Yorùbá bọ̀, wọn ní "ohun a Fẹ̀sọ̀ mú ki í bàjé, ohun a fagbára mú kokoko ni le bí ojú ẹja"
Ẹ jẹ́ ká Fẹ̀sọ̀ ṣe,

Àwa èwe ìwòyí,
Màriwò to yọ láì yọ,
Tó lóhùn o kan ọrùn,
Ẹ jẹ́ ká bí í léèrè,
Bóyá ìran bàbá rẹ ṣe bẹ́ẹ̀ ri,
Ẹ̀sọ̀, ẹ̀sọ̀ láyé gbà,
Nítorí igbá pẹ̀lẹ́ kìí fọ́,
Àwo pẹ̀lẹ́ kìí fàyá,
Ẹ̀sọ̀ láyé gbà,
Ọmọ ìyá à mi tí ó jé Yorùbá ẹ jẹ́ ká máa fi ẹ̀sọ̀ ṣe,
Ìṣó Ọlọ́run a má wà pẹ̀lú wá ní gbogbo ìgbà...

#ÀmínÀṣẹÈdùmàrè

https://instagram.com/edeyorubarewa

https://twitter.com/edeyorubarewa

https://facebook.com/edeyorubarewa

https://chat.whatsapp.com/Fb7Vz4kj9WlIunYKtIhmwu

https://edeyorubatiorewa.blogspot.com.ng/