Thursday, 23 February 2017

obìnrin kan àti àwọn ọmọ rẹ̀ mẹ́ta.

Àlọ́ míràn fún ìgbádùn gbogbo olólùfẹ́ èdè Yorùbá....
Àlọ́ oo
Àlọ̀ ọ ọ
Àlọ́ yí dá fìrìgbagbo, ó dá lórí obìnrin kan àti àwọn ọmọ rẹ̀ mẹ́ta.
Ni ìlú kan orúkọ ìlú náà ni olówó, obìnrin kan wà tí ó bí ọmọ mẹ́ta. Orúkọ àwọn ọmọ náà ni, #Wẹ́rẹ́wẹ́rẹ́ laá ṣẹ́gi, #Wàràwàrà làá wọ̀gbẹ́ àti #Ọmọniyun tí ó jẹ́ àbígbèyìn. Obìnrin yìí wá fẹ́ràn Ọmọniyun ju àwọn ẹ̀gbọ́n rẹ̀ lọ, kò sì fi ìfẹ́ yìí pamọ́ fún àwọn ẹ̀gbọ́n Ọmọniyun.
Nígbà tí ó di ọjọ́ kan, àwọn ọmọ mẹ́tẹ́ẹ́ta jáde nílé, wọn kò sì mọ ọ̀nà ilé mọ́. Obìnrin yìí wá àwọn ọmọ rẹ̀ títí kò rí wọn. Nígbà tí ó ṣe, obìnrin yìí bẹ̀rẹ̀ sí wá àwọn ọmọ rẹ̀ pẹ̀lú orin àti omijé lójú. Obìnrin náà bẹ̀rẹ̀ sí kọ orin báyìí pé:
Obìnrin             Èrò ọjà olówó
Agberin            JàlòlòJàlòlò
Obìnrin             Taa ló bá mi rọ́mọ mi,
Agberin            JàlòlòJàlòlò, Kíni orúkọ t'ọ́mọ rẹ máa ń jẹ? JàlòlòJàlòlò
Obìnrin             Ọ̀kan Wẹ́rẹ́wẹ́rẹ́ laá ṣẹ́gi
Agberin            JàlòlòJàlòlò
Obìnrin             Ọ̀kan Wàràwàrà làá wọ̀gbẹ́
Agberin            JàlòlòJàlòlò
Obìnrin            Ọ̀kan Ọmọniyun kékeré, ọ̀rọ̀ Ọmọniyun ló dùn mí jọjọ
Agberin           JàlòlòJàlòlò
Obìnrin           Èrò ọjà olówó
Agberin          JàlòlòJàlòlò
Bí ó ṣe ń kọ orin yìí, obìnrin yìí kò mọ̀ pé Wọ́n tí gbé àwọn ọmọ òun pamọ́ fẹ́ fi dá obìnrin yìí lára wípé kò yẹ kí á máa fẹ́ràn ọmọ kan ju èkejì lọ nítorí Olódùmarè ló fi àwọn ọmọ yìí ta wá lọ́re.
Obìnrin yìí tún bẹ̀rẹ̀ orin bí tí ìṣáájú. Nígbà tí ó ṣe, wọ́n taari méjì nínú àwọn ọmọ obìnrin yìí síta. Inú obìnrin yìí kò dùn torí pé kò rí Ọmọniyun tííṣe àbígbèyìn ọmọ rẹ̀. Àwọn ènìyàn sì gbìmọ̀ pọ̀ láti dá obìnrin yìí lójú. Ohun tí wọ́n sì ṣe ní wípé wọ́n pa Ọmọniyun wọn sọ sí obìnrin yìí. Bí obìnrin yìí tí ríi ni ó bú sí ẹkùn ni ó tún bẹ̀rẹ̀ sí kọ orin. Kò pẹ́ ni wọn ju òkùtù Ọmọniyun sí ìyá rẹ̀. Inú ìyá Ọmọniyun bàjé gidigidi, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí sunkún lọ sí ilé.
Àlọ́ yìí kọ́ wa wípé kí á máa fẹ́ràn ọmọ kan ju ọmọ èkejì lọ torí a kò mọ irú ohun tí àwọn ọmọ yìí leè dà ní ọjọ́ ọ̀la. Òkúta tí ọ̀mọ̀lé kọ̀ tún lè padà wá di igun ilé ni ọjọ́ ọ̀la.

Tuesday, 21 February 2017

Ilé ayé ilé asán

Ilé ayé!
Ilé asán!
Àfọwọ́bàfiílẹ̀,
Ìmúlẹ̀mófo, Ayé ọ̀hún tí kò tó pọ́n,
A bùú, kò kúnwọ́,
A dàá sílẹ̀, kò seé sà,
Gbogbo ẹ̀ gbògbò ẹ̀, ẹsẹ̀ mẹfa,
Kò sí ohun táa mú wá sáyé,
Kò sì ní sí ohun táá mú lọ,
Gbogbo olówó ayé ń kú gbogbo ilé, ọkọ̀, àti ohun mèremère wọn kò ba rọrùn,
Mélòó ni gbogbo ara wa níwájú ikú?
Ẹ jẹ́ ká gbáyé se rere,
Nítorí ọjọ́ àtisùn ẹni,
Kò sí ohun táa se láyé tó gbé,
Oògùn àsegbé kan kò sí láyé níbi,
Àsepamọ́ ló wà,
Ilé ayé á kúkú tán,
Èwo làá n wayé máyà fún,
Ikú ni yóò gbẹ̀yin oníkálukú wa,
Ohun tí á tán làá pè ní Ayé,
Ẹ jẹ́ ká hùwà tó máa kuni kù ní sààréè,
Ẹ má jẹ̀ẹ́ kẹ́tàn ayé tàn wá mọ́,
Ọba òkè ni ẹ jẹ́ ká rọ̀ mọ́,
Òun ló leeè là wa,
Asán lórí asán layé yìí.
Mo sọ̀ yìí mo dúró náà.

#EdeYorubaRewa

Olúrómbí and Olúwéré

Fún ìgbádùn gbogbo olólùfẹ́ ojú ìwé yìí. Mo lérò wípé ẹ gbádùn ẹ dáradára.

Àlọ́ oo ,
Àlọ́ ọọ,
Àlọ́ yìí dá lórí #Olúrómbí àti #Olúwéré 




Ní ayé àtijó, obìnrin kan wà tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Olúrómbí. Obìnrin yìí kò sì fi inú soyún, bẹ́ẹ̀ ni kò fẹ̀yin gbọ́mọ pọ̀n, èyí jásí pé ó yàgàn. Ó wá ọmọ títí ṣùgbọ́n pàbó ló ń já sí. Dípò kí ó dúró de iṣẹ́ Olódùmarè, ó gba ọ̀dọ̀ olúwéré lọ. Ó ṣe eléyìí nígbà tí ó rí àwọn tí wọ́n jọ wà nínú ipò báyìí tí wọ́n ń gbọ́mọ pọ̀n. Olúrómbí gbéra ó lọ sí ọ̀dọ̀ olúwéré. Pẹ̀lú ìtara ni Olúrómbí fi jẹ́ ẹ̀jẹ́ pé bí olúwéré bá fún òun lómọ, òun yíò sì fún un ní ọmọ náà. Ẹ̀jẹ́ yìí jẹ́ ọ̀tun nítorí pé, ewúrẹ́ àgùntàn ni àwọn obìnrin ń padà wá fún olúwéré gẹ́gẹ́ bí ẹ̀jẹ́.

Lóòótọ́, Olúrómbí lóyún, ó sì bí ọmọbìnrin kan tí ó sọ orúkọ rẹ̀ ní #Apọ́nbiepo. Apọ́nbiepo ń dàgbà, ìyá rẹ̀ kò sì rántí ẹ̀jẹ́ tí ó bá olúwéré dá.

Nígbà tí olúwéré retí Olúrómbí kí ó wá mú ẹ̀jẹ́ rẹ̀ ṣe tí kò ríi ni òun gan-an bá gbéra ni ọjọ́ kan ó gba ilé Olúrómbí lọ. Bí ó ṣe dé'bẹ̀ tí ó f'ojú kan Apọ́nbiepo ni ó bá lé lọ́wọ́ mú tí ó sì bẹ̀rẹ̀ sí mú lọ. Ọmọ yìí bẹ̀rẹ̀ si sunkún títí tí ìyá rẹ̀ Olúrómbí bẹ̀rẹ̀ sí sáré tẹ́lẹ̀ olúwéré títí olúwéré fi padà wọ inú igi lọ pẹ̀lú Apọ́nbiepo.

Olúrómbí bẹ̀rẹ̀ si bẹ olúwéré pẹ̀lú omijé lójú, ṣùgbọ́n dípò kí olúwéré dá ọmọ padà, orin ni ó bẹ̀rẹ̀ sí fi dáa lóhùn báyìí pé :

Olúwéré                  oníkálukú ń jẹ̀jẹ́ ewúrẹ́,
                               Ewúré ewúrẹ́,
                               oníkálukú ń jẹ̀jẹ́ àgùntàn,
                                Àgùntàn bọ̀lọ̀jọ̀,
                               Olúrómbí ń jẹ̀jẹ́ ọmọ rẹ̀,
                               ọmọ rẹ Apọ́nbiepo            
                               Olúrómbí oo 
#Agbeorin              janin-janin, ìrókò janin-janin

Olúwéré :              Olúrómbí oo
Agbeorin               janin-janin, ìrókò janin-janin

Báyìí ni Olúrómbí ṣe pàdánù ọmọ rẹ̀.

Ẹ̀kọ́ tí Àlọ́ yìí kọ́ wa wípé bí a bá jẹ́jẹ̀ẹ́ kí á rí wí pé ẹ̀jẹ́ tí a lè san ni a jẹ́, kí á má máa fi ìwànwara jẹ́ ẹ̀jẹ́. Ní èkejì ó yẹ kí á máa kó gbogbo àníyàn wà tí Olódùmarè. Kí á má máa fi ìwànwara wá nǹkan torí ọba ọ̀kẹ́ t'óṣe fún Táyé kò gbàgbé Kẹ́hìndé, ẹ jẹ́ kí á sọ́ra.

#EdeYorubaRewa

Sunday, 5 February 2017

Àforítì lebọ

Àforítì lebọ 

Àforítì lebọ, Òtítọ́ nii o, 
Bẹ́ẹ̀ náà ló rí, 
Kòsí bí omi se lè rú tó, 
ibi kí ó tòrò ni á jásí,
Adìẹ tí ò kú leè j'àgbàdo,
Ìyà tí n jẹ ọmọ fún ogún ọdún,
Òsì tí ń ta ọmọ fún ọgbọ́n oṣù,
Bí ọmọ náà bá leè ní àforítì,
Adùn náà ni gbẹ̀yìn irú wọn,
Ìyà tí n jẹ àwọ̀sùn ológbò kò mọ níwọ̀n, tóbá dàgbà tán, níí bọ́ lọ́wọ́ Ìyà,
Akẹ́kọ̀ọ́ tó ní àforítì, áá ní àṣeyọrí,
Ọmọ isẹ́ tó ní àforítì, áá di ọ̀gá,
Àforítì làkọ́kọ́,
Akíkanjú labí tẹ̀le ẹ,
Ìwà ìrẹ̀lẹ̀ lọmọ ikẹhin,
Ẹni tó bá ní mẹ́tẹ̀ẹ̀ta lamọ̀ léèyàn.
Àforítì lérè púpọ̀,
Ẹjẹ́ kí gbogbo wa ni Ìforítì.....

Èmi Semiat Olufunke Aya Tiamiyu sòyí mo dúró ná oooo

#Akúìmúraọ̀sẹ̀tuntun

#EdeYorubaRewa