Fún ìgbádùn gbogbo olólùfẹ́ ojú ìwé yìí. Mo lérò wípé ẹ gbádùn ẹ dáradára.
Àlọ́ oo ,
Àlọ́ ọọ,
Àlọ́ yìí dá lórí #Olúrómbí àti #Olúwéré
Àlọ́ oo ,
Àlọ́ ọọ,
Àlọ́ yìí dá lórí #Olúrómbí àti #Olúwéré
Ní ayé àtijó, obìnrin kan wà tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Olúrómbí. Obìnrin yìí kò sì fi inú soyún, bẹ́ẹ̀ ni kò fẹ̀yin gbọ́mọ pọ̀n, èyí jásí pé ó yàgàn. Ó wá ọmọ títí ṣùgbọ́n pàbó ló ń já sí. Dípò kí ó dúró de iṣẹ́ Olódùmarè, ó gba ọ̀dọ̀ olúwéré lọ. Ó ṣe eléyìí nígbà tí ó rí àwọn tí wọ́n jọ wà nínú ipò báyìí tí wọ́n ń gbọ́mọ pọ̀n. Olúrómbí gbéra ó lọ sí ọ̀dọ̀ olúwéré. Pẹ̀lú ìtara ni Olúrómbí fi jẹ́ ẹ̀jẹ́ pé bí olúwéré bá fún òun lómọ, òun yíò sì fún un ní ọmọ náà. Ẹ̀jẹ́ yìí jẹ́ ọ̀tun nítorí pé, ewúrẹ́ àgùntàn ni àwọn obìnrin ń padà wá fún olúwéré gẹ́gẹ́ bí ẹ̀jẹ́.
Lóòótọ́, Olúrómbí lóyún, ó sì bí ọmọbìnrin kan tí ó sọ orúkọ rẹ̀ ní #Apọ́nbiepo. Apọ́nbiepo ń dàgbà, ìyá rẹ̀ kò sì rántí ẹ̀jẹ́ tí ó bá olúwéré dá.
Nígbà tí olúwéré retí Olúrómbí kí ó wá mú ẹ̀jẹ́ rẹ̀ ṣe tí kò ríi ni òun gan-an bá gbéra ni ọjọ́ kan ó gba ilé Olúrómbí lọ. Bí ó ṣe dé'bẹ̀ tí ó f'ojú kan Apọ́nbiepo ni ó bá lé lọ́wọ́ mú tí ó sì bẹ̀rẹ̀ sí mú lọ. Ọmọ yìí bẹ̀rẹ̀ si sunkún títí tí ìyá rẹ̀ Olúrómbí bẹ̀rẹ̀ sí sáré tẹ́lẹ̀ olúwéré títí olúwéré fi padà wọ inú igi lọ pẹ̀lú Apọ́nbiepo.
Olúrómbí bẹ̀rẹ̀ si bẹ olúwéré pẹ̀lú omijé lójú, ṣùgbọ́n dípò kí olúwéré dá ọmọ padà, orin ni ó bẹ̀rẹ̀ sí fi dáa lóhùn báyìí pé :
Olúwéré oníkálukú ń jẹ̀jẹ́ ewúrẹ́,
Ewúré ewúrẹ́,
oníkálukú ń jẹ̀jẹ́ àgùntàn,
Àgùntàn bọ̀lọ̀jọ̀,
Olúrómbí ń jẹ̀jẹ́ ọmọ rẹ̀,
ọmọ rẹ Apọ́nbiepo
Olúrómbí oo
#Agbeorin janin-janin, ìrókò janin-janin
Olúwéré : Olúrómbí oo
Agbeorin janin-janin, ìrókò janin-janin
Báyìí ni Olúrómbí ṣe pàdánù ọmọ rẹ̀.
Ẹ̀kọ́ tí Àlọ́ yìí kọ́ wa wípé bí a bá jẹ́jẹ̀ẹ́ kí á rí wí pé ẹ̀jẹ́ tí a lè san ni a jẹ́, kí á má máa fi ìwànwara jẹ́ ẹ̀jẹ́. Ní èkejì ó yẹ kí á máa kó gbogbo àníyàn wà tí Olódùmarè. Kí á má máa fi ìwànwara wá nǹkan torí ọba ọ̀kẹ́ t'óṣe fún Táyé kò gbàgbé Kẹ́hìndé, ẹ jẹ́ kí á sọ́ra.
#EdeYorubaRewa
Olúwéré : Olúrómbí oo
Agbeorin janin-janin, ìrókò janin-janin
Báyìí ni Olúrómbí ṣe pàdánù ọmọ rẹ̀.
Ẹ̀kọ́ tí Àlọ́ yìí kọ́ wa wípé bí a bá jẹ́jẹ̀ẹ́ kí á rí wí pé ẹ̀jẹ́ tí a lè san ni a jẹ́, kí á má máa fi ìwànwara jẹ́ ẹ̀jẹ́. Ní èkejì ó yẹ kí á máa kó gbogbo àníyàn wà tí Olódùmarè. Kí á má máa fi ìwànwara wá nǹkan torí ọba ọ̀kẹ́ t'óṣe fún Táyé kò gbàgbé Kẹ́hìndé, ẹ jẹ́ kí á sọ́ra.
#EdeYorubaRewa
No comments:
Post a Comment