Ìtàn tí ó rò mó òwe Yorùbá yìí,
"Kí lo rí l'ọ́bẹ̀ tí fi waaro ọwọ́."
Ní bí ọdún díè sẹ́yìn, ìlú kan wà tí wọ́n ń pè ní Kuo, ó wá ní Bode Saadu ni Ìpínlẹ̀ Kwara ṣùgbọ́n ìlú tí à ń sọ yìí jóná ni ọdún 1814.
Gbogbo Yorùbá kó ló máa ń lo òwe yìí tẹ́lẹ̀, ogun ni ó sì fà á tí òwe yìí fi wáyé.
Ìlú tí a ń pè ní Kuo yìí ni olórí tí orúkọ rẹ ń jẹ́ Sholá Gberú. Nígbà tí ìlú Kuo jóná Sholá Gberú kò gbogbo àwọn ọmọ, ẹrú àti gbogbo ohun tí wọ́n ni lọ sí ìlú Ilorin,nígbà náà afonja wa láyé. Ìlú kan wà láàrin Ọ̀yọ́ àti Ilorin,ìlú Gbógun ni ìlú náà ń jẹ́, tí ogún bá sì fẹ́ ja Ọ̀yọ́ wọn gbodo kọ́kọ́ ja ìlú Gbógun tí à ń Wiyi. Nígbà tí wọ́n fẹ́ kogun ja ìlú Gbógun ALÁNÀMÚ ni lèdí àpò pọ̀ láti kogun ja ìlú Gbógun.
Arákùnrin tí wọ́n ń pè Alánàmú Pankere ní o ma ń fi jà, tí ó bá ti fi náà ẹni tí wọ́n dìjọ ń jà fi ń jà, ẹni náà ara rẹ̀ yíò wálè yíò sì na'wọ́ mú ẹni náà ìdí rẹ tí wọ́n fi ń pe ni ALÁNÀMÚ.
Alánàmú sì so ọwọ́ pò mo Ilorin, wọn sì mú orí ìyàwó ọ̀pẹ̀lẹ̀ mó ara, Wọ́n fún ní májẹ̀lé pé kí ó fi si inú oúnjẹ. Wọ́n rán àgbà ọmọ Sholá Gberú sí ọ̀pẹ̀lẹ̀, ìyàwó ọ̀pẹ̀lẹ̀ dáná oúnjẹ, ó sì ti fi májẹ̀lé si inú ounje náà, ọ̀pẹ̀lẹ̀ àti ọmọ Sholá Gberú tí fọ ọwọ́, bí ọmọ Sholá Gberú tí bu òkèlè pé kí ohun fi kan ọbẹ̀
Ó bá wararo ọwọ́. Ọ̀pẹ̀lẹ̀ bíi pé kí lórí l'ọ́bẹ̀ tí ó fi wararo ọwọ́, ló bá ní májẹ̀lé rẹ nínú ọbẹ̀.....
Báyìí ni Ọ̀pẹ̀lẹ̀ ni Bí kú ilé ọ bá pani tode ó lè pani.
Ìtàn tí ó rò mó òwe KÍ LO RÍ L'Ọ́BẸ̀ TÍ Ó FI WAARO ỌWỌ́. májẹ̀lé ni ó rí l'ọ́bẹ̀ tí ó fi Wararo ọwọ́.
Mo lérò wípé ẹ gbádùn ìtàn yìí.
#EdeYorubaRewa
No comments:
Post a Comment