Ìtàn Òrùn Ati Òṣùpá fún àkà gbádùn yín......
nígbà ìwásẹ̀, ọba ọdẹ Ọ̀run níse alákoso ohun gbogbo, ìkáwọ́ rẹ̀ ṣì ni gbogbo ohun tí a dá wà.ọba ọdẹ Ọ̀run ní ìyàwó , ósì tún bí ọmọ méjì. ÒRÙN àti ÒSÙPÁ ni ọmọ méjì tí ọba ode ọ̀run bí. Òrùn àti òsùpá fẹ́ràn ara wọn gidigidi, tí ó jẹ́ wípé bí òsùpá ò bá ṣí nílé òrùn kòní jẹun àfi ìgbà tí òsùpá bá dé ,bẹ́ẹ̀ nọ sì ni òsùpá bí òrùn kò bá dé kò ní jẹun.
Ní ọjọ́ kan ọba ọdẹ ọ̀run ránsé sí òṣùpá àti òrùn ọmọ rẹ wìpè kí wọn wà rí òhun. nígbàti wọn dé bè , ọba ọdẹ ọ̀run sọ fún wọn wípé òhun fẹ rìn irìnàjò kan tí yóò sì pẹ́ kí òhun tó padà , óní kí òṣùpá àti òrùn lọ fi oríkorí kí wọn se àpérò ẹni tí yóò delé de òhun tí òhun bá wà ní ìrìnàjò. Wọ́n dúpé lọ́wọ́ bàbá wọn, wọn sì se ìlérí láti se gẹ́gẹ́ bí bàbá wọn ti sọ.
Ní ọjọ́'rù ọ̀sẹ̀ kan náà, òṣùpá àti òrùn fi ojú kan ra, sùgbón ọ̀rọ̀ ò wọ̀ láàrín àwọn méjèèjì lérí ẹni tí yóò délé nígbàtí bàbá wọn bá lọ. òṣùpá ní òhun ọkọ ẹgbàágbèje ìràwọ̀ ni yóò delé de bàbá àwọn, béèni òrùn tutọ́ sókè fojúgbàá wípé òhun ìmólè ọmọ aráyé ni yóò delé de bàbá àwọn , óní láì sí èmi òrùn inú òkùnkùn biribiri ni ayé kò bá wà,ó ní èmi àfi ojojúmó dára bí egbin, òsùpá sọ wípé tí o bá rí béè ọmọ aráyé òní máà sọ wípé isẹ́ lò òsùpá se lájùlé òrùn, óní òhun ni yóò delé de bàbá wọn.
Bí wọ́n ti ń gba ọ̀rọ̀ náà bí ẹni gba igbá ọtí re ,títí ó fi di ìjà. òsùpá lu òrùn ní ìlú ẹni lu bàrà, òrùn náà sí lu òsùpá bákan náà.
nígbátì bàbá wọn gbọ́ sí ọ̀rọ̀ náà inú rẹ bàjé,óní kí wọ́n pe àwọn méjèèji wá sí àgbàlà olódùmarè,ní ibẹ̀ ló ti jẹ kóyé wọn wípé òhun ọba ọdẹ ọ̀run ní se alákòso ọ̀sán àti òru,óní ní ìdí èyí òhun yóò pin ìlú náà sí méjì,óní kí òṣùpá máà jọba lérí òru , ósì ní kí òrùn máà jọba lóri ọ̀sán wọn kò sì gbọdọ̀ fi ojú kan ra gẹ́gẹ́ bí ìjìyà ẹ̀sẹ̀ wọn.
Ní ọjọ́ yíí inú òṣùpá àti òrùn bàjẹ́ nítorí wọn kòní fo jú kan ra mọ́ àti wípé àyè àti má se bí ẹbí ti dópin. Ìgbà kúgbá tí òrùn àbí òṣùpá báti rántí ìdájó yii ,nínú ọdún wọn a máa sunkún lọ́pọ̀lọpọ̀ ,ekún wọ̀nyí ni àwa ọmọ ènìyàn ńpè ní ÒJÒ.
No comments:
Post a Comment