Sunday, 6 January 2019

Eégún Aláré


 Apá KINI



OJELARINNAKA ATI DASOFUNJO



Ní ìgbà àtijó,, eégún Alárè méjì kan wà ní Okeho (a kò mọ bí ti àtijó ni tàbí èyí tí ó wà báyìí lónìí) ni ilẹ̀ ìjọba Aláàfin Ọ̀yọ́, ọrẹ timotimo sì ni àwọn méjèèjì. Orúkọ ekinni a máa jẹ Òjé Larinnaka, tí èkejì a sì máa jẹ Dasofunjo. O se ni igba kan, Oje Larinnaka gbó pé are idán pípa kò wọ́pọ̀ ni apa ìlú kan, o si ro pe bí òun ba lo pidan fún wọn ní ibè, ọwọ òun yio ba ẹrú. Nípa bẹ́ẹ̀, ó pinnu ni ọkàn rẹ láti lọ sí ìlú náà dandan. Kí Oje Larinnaka to máa pale ìrìn-àjò maa mọ, ó fi lọ ọrẹ rẹ Dasofunjo, ó si gba a ní ìyànjú pé kí ó jẹ ki awon dijo lọ sí àjò náà:ṣùgbọ́n Dasofunjo so fún un pé òun kò ní lè lọ nitoripe idiwo ilé tí enia kò gbọ́dọ̀ fi silẹ lọ s'ajo poju f'oun. O wa gbàdúrà pé kí Ọlọ́run ṣamọ̀nà ọrẹ òun :kí ó lọ rere, kí ó bo rere Lehin àdúrà yi, Oje Larinnaka so fún ọrẹ pé òun yio tún de odò rẹ kì òun to lọ si àjò naa, òsì dìde lọ sí ilé rẹ. Bí ó ti délé ni ó so fun àwọn ẹbí àti aladugbo rẹ nípa ìrìn-àjò tí ó nlọ, o si tún sọ fún ìyàwó kansoso tí ó ní pelu. Ìyàwó rè náà tí a npe ni iyadunni tí lóyún sinú ni àsìkò yí. Bí ó ti sọ fún wọn tán ni o ba npalemo. Bí Oje Larinnaka tí palemo tán, ó padà lọ sí odò ọrẹ rẹ Dasofunjo láti dagbere fún un. Nigbati o de ọdọ rè tí ó sì dagbere fún un, Dasofunjo ba a damoran dáadáa, o si fún un ní ìwọ̀n nkan díẹ̀ tí ó mọ tí a fi ṣókùnkùn. Ṣùgbọ́n kí Oje Larinnaka to kúrò nílé ọrẹ rẹ, o be ẹ kì ó sójú-sehin f'oun nípa ti toju aya kansoso tí òun ní ti o lóyún sínú títí tí òun yio fi padà wálé wá mú u lọ bi àjò tí òun nlọ naa ba dára. Dasofunjo gbàdúrà kí Ọlọ́run jẹ ki àjò naa dára fún un, ó sì ṣèlérí pé òun yio maa se bí ó ti yẹ fún ìyàwó rẹ :ṣùgbọ́n ó te ẹ mọ ọrẹ rẹ naa létí pé kí ó má gbàgbé ilé, pàápàá kì ó rántí irú ipò tí ìyàwó rẹ wà pé ó lóyún sínú, kí ó sì tìtorí èyí tètè wá bẹ ilé wo bí o ba d'ajo tan. Lehin èyí, Dasofunjo sìn ọrẹ rẹ sónà :nigbati nwọn rìn díè nwọn bó ara wọn lọ́wọ́, onikaluku sì bá ọ̀nà tìrẹ lọ.

Ẹ darapọ̀ ni ọ̀la fún apá kejì.


Ẹnití ó kó jáde nínú ìwé ni Ọ̀gbẹ́ni Obey Adesoji.


 #ÈdèYorùbáRewà

Tuesday, 27 February 2018

ÌDÚPẸ́

Kíni mo jẹ́?
Tani ni mí?
Tí Kò bá sí èyin, kò lè sí ojú ìwé #EdeYorubaRewa. Yorùbá bò wọn ní "Àgbáj'ọwọ́ la fi ń sọ̀'yà, Àjèjí ọwọ́ kan kò gbẹ́'rù dó'rí" Yorùbá tún sọ wípé "ọ̀pọ̀ èèyàn ní jẹ́ janmọ ẹnìkan kìí jẹ́ àwa de"leyi tí ó túmọ̀ sí wípé ọlá Ọlọ́run àti ọlá gbogbo olólùfẹ́ Èdè Yorùbá Rẹwà ni ó fún mi ní agbára láti máa ṣe ohun kékeré tí mò ń ṣe láti gbé èdè Yorùbá lárugẹ.... Mọ wá dúpẹ́ púpọ̀ lọ́wọ́ gbogbo àwọn tí wọ́n fẹ́ràn ojú ìwé #ÈdèYorùbáRewà àti àwọn tí wọ́n tẹ́lẹ̀ wa lórí ẹ̀rọ ayélujára Facebook, Twitter, Instagram, Blog àti WhatsApp,èdùmàrè ò ní paná ìfẹ́ wá.

Ẹ dákún mo rọ gbogbo òbí láti jé kí a fi èdè Yorùbá kó àwọn ọmọ wa láti lè gbé èdè wa lárugẹ, torí mò ń gbọ́ wípé èdè Yorùbá ò ní pé kú àti wípé wón ní àwọn òyìnbó aláwò funfun yíò máa kọ́ wa ni èdè wa leyi tí kò gbọdọ̀ ṣẹlẹ̀, ai mó wá ní ṣẹlẹ̀ rẹ̀ ó wà ní ọwọ́ ÈMI àti ÌWỌ.

Ní tèmi ń ò ní fi ọwọ́ òsì júwe ilé bàbá mi, ìwọ ńkọ́?
Ẹsẹ́ púpọ̀

Www.edeyorubarewa.com
Www.facebook.com/edeyorubarewa

#EdeYorubaRewa

Sunday, 7 January 2018

Ìtàn Alarinrin apá kejì

ỌBA LÓ LADE. ÌJÒYÈ NÁÀ LÓ NI ILEKE. ITAN NTE SÍWÁJÚ.
ÀKỌLÉ ITAN: ṢỌ ẸRÚ KO

APÁ KEJÌ

Ibẹru bojo tí bàa gbogbo ara ilu ẹlẹgan, ṣe ogún ó dàbí ẹni ń jiyan, bẹ́ẹ̀ ni ó dàbí ẹni ń jẹka.
Are ni ajanimogun nilu ẹlẹgan,ọdẹ ni àmọ́ ọdẹ tí rẹ kì npa ẹkùn bẹ́ẹ̀ ni kí npa àgbọ̀nrín. Ọdẹ etile ló ńṣe bí kò pá Ọya, kò pá emo, kò sì de isa okete. Nígbà tó kú ọjọ marun kí àsìkò tí ìlú tẹrẹ dá fún ìlú ẹlẹgan pé, ajanimogun gbéra lọ bá àwọn ilumoye pé tí wọ́n bá lè gbà òun láyé, òun ṣetan láti lewaju ogún fún wọn, ó sì dájú pé ajaye ni òun yóò jagun náà.
Tika tẹgbìn ni àwọn olóyè wo ajanimogun, wọn ní bóyá ni nkan ó ti tà sì lọpọlọ. Abi báwo ni ọdẹ tí npa ẹmọ, Pa afé ṣe fẹ lọ koju ogún, oogun wo loni tí yóò fi jagun ọhun ni ajaye? Àbí torí kí ajanimogun lè d'oba ló ṣe ni òun fẹ lọ dojú kọ ogún?? Gbogbo ìbéèrè yìí ni àwọn olóyè nro lọ́kàn ara wọn,àmọ́ kò ye wọn.
Wọn ní kí ajanimogun sì máa lọ náà pé tí yóò bá fi di ọjọ́ kejì, àwọn yóò ti mọ̀ ibi tí àwọn yóò bá ìyára ja lórí ọrọ náà.
Lẹ́yìn tí ajanimogun kúrò lọdọ àwọn olóyè, iyalode ni kí wọ́n jẹ́ káwọn gba ajanimogun láàyè láti lọ jagun, bóyá eledua lè gbé ògo fún ọlẹ rẹ. To bá sì ṣe bẹ́ẹ̀ bá ogún lọ, a jẹ pe ohun ojú nwa lójú nri. Àwọn olóyè tó kú fara mọ èrò iyalode, wọn si pinnu láti tẹle aba rẹ.
Ní òwúrọ ọjọ kejì àwọn olóyè rán onise sì ajanimogun pé ìlú tí fara mọ èrò rẹ, wọn si ti gba pe ko lọ dojú kọ ogún fún wọn. Wọn súre fún pé yóò lọ rẹ, yóò sì bo rè. Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n tún fi ikilọ ati àdéhùn tí ọ̀rọ̀ wọ́n lẹ́yìn. Wọn ní bí ajanimogun bá kọ láti ṣẹ́gun pípa ni ilu yóò pá òun àti gbogbo ẹbi rẹ run,àmọ́ bí ó bá lè já ogún náà ni ajaye, àwọn yóò fi jọba ìlú ẹlẹgan tuntun.....
ṢE AJANIMOGUN YÓÒ ṢÍ LỌ SOJU OGUN PẸ̀LÚ ALAKALE TI ÌLÚ GBÉ SI NÍWÁJÚ BÁYÌÍ????
ITAN Ń TẸ ṢÍWÁJÚ

Ẹ fojú sọ́nà fún apá kẹta




Láti ọwọ́ Ọ̀gbẹ́ni Aremo Jah-Akewi


www.facebook.com/EdeYorubaRewa

#EdeYorubaRewa

Thursday, 4 January 2018

Àkọlé ìtàn : ṢO ẸRÚ KO

ÀTI SE ÈÉ, Ó TI JINÀ.
Àkọlé ìtàn : ṢO ẸRÚ KO

APÁ KÌÍNÍ

Ojúmọ́ tí n mo, ooye tí bẹ̀rẹ̀ si ni là, ó ti ń bọ̀ sọ wo afemoju. Àwọn aráàlú elegan tí ń gbéra nílé láti gba ẹnu ìṣe wọn lọ, ṣe ìdí isẹ ẹni là tí ń mọni lole.
Bi àwọn èèyàn ti ń jí ni wọn bẹ̀rẹ̀ si ni gbo tí kowe nke labaadi. Bí ojúmọ́ ṣe ń mọ sì bẹẹ nígbè ẹyẹ yìí túbọ̀ n pọ sì. Ara bẹ̀rẹ̀ si fú àwọn aráàlú ohun lè mú kí kowe máa ké lafemoju. Se kowe ó kúkú nke lásán, ó ní láti jẹ pe ohun burúkú kan tí ṣẹlẹ̀ sí lu elegan ni.
Nígbà tí yóò fi di ÒWÚRỌ̀ kukutu, ní alago ọba bẹ̀rẹ̀ si ni lu aago, kaluku ń jáde wá gbọ ìṣe tí alaago náà fẹ jẹ́. Òfò ńlá tí ṣe ìlú elegan, àkùkọ tí kò lẹyin ọmọkùnrin alágbára. Alago jabo fún gbogbo ìlú pé kabiyesi àwọn, tí ńṣe ọba ọlọbẹ tí ìlú ẹlẹ́gan tí waja lóru mójú. Tori náà isede yóò wà fún odindi ọjọ méje láti ṣe oro fún ìsìnkú ọba. Gbogbo ìlú kan gogo nítorí ìròyìn láabi tí wọn gbo.
Àwọn ilumoye ṣeto bí wọn yóò ṣe fi ilẹ bo àṣírí òkú ọba, bí irun ti ń bo àṣírí orí.
Àdánù ńlá gbaa ni ikú ọba ọlọbẹ jẹ́ fún gbogbo ìlú ẹlẹ́gan pátápátá. Ìgbà ìṣàkóso rẹ tú t'onile t'alejo lára, eku nke bí eku, ẹyẹ nke bí ẹyẹ bẹẹ lọmọ ènìyàn ń fohùn bí èèyàn, amo ikú ṣe ká bo se fi ọba ọlọbẹ là gbogbo ìlú ẹlẹ́gan lójú.
Lẹyin oṣù kan tí ọba ọlọbẹ tí waja ni ilu tẹrẹ ranse ogún sì wọn, ṣe fami nfa ọ kúkú ti wá laarin ọba ìlú tẹrẹ yìí pẹlu ọba ọlọbẹ kò tó di pé ó waja. Èrò àwọn ilumoye tẹ́lẹ̀ ni pé bóyá ìlú tẹrẹ yóò jáwọ lórí ọ̀rọ̀ náà nígbà tí ọba ọlọbẹ tí waja, àmọ́ ibi tí wọ́n fojú sì ọ̀nà ó gbà ìbè, ó jọ bí ẹni pé ọrọ ti fẹ́ bá ẹyin yọ.
Ọ̀sẹ̀ mẹta péré ni ilu tẹrẹ fún ìlú ẹlẹ́gan láti lọ múra ogún silẹ, torí ìjà nbo kànnàkànnà ṣe tàn tó fẹ́ bo ẹyẹ ẹga. Àwọn ilumoye ṣètò pé kí àwọn ìdílé tó njẹ ọba fà ọmọ oyè silẹ, kí wọn lé yàn ọba èyí tí yóò lewaju ogún tó nbo lọ́nà. Àmọ́ kò sẹni tó yọjú.
Ọ̀pọ̀ lo wù kó joyè, àmọ́ aile fara ẹni jin ó jẹ ki ẹnikẹ́ni yọjú láti gorí apere bàbà rẹ. Mo ńbọ

ìtàn wá láti ọ̀dọ̀ Ọ̀gbẹ́ni Aremo Jah-Akewi

Ẹ fojú sọ́nà fún apá kejì.

www.facebook.com/EdeYorubaRewa

#EdeYorubaRewa


Thursday, 14 September 2017

Ìjàpá àti ẹyẹ Àdàbà

Èyí ni Àlọ́ àpagbè fún gbogbo olólùfẹ́ ojú ìwé yìí, mọ lérò wípé ẹ ò gbádùn ẹ.

Àlọ́ oooo
Àlọ́ ọọọọ
Àlọ́ yìí dá lórí #ÌjàpáatiẹyẹÀdàbà

Gégé Bí ẹ̀yin náà ti mọ̀, alàgàbàgebè ni Ìjàpá, olè àti ọ̀kánjúwà ni pẹ̀lú. Ní ayé àtijó, Ìjàpá àti Ẹyẹ Àdàbà jọ ń ṣe ọ̀rẹ́. Àdàbà ni ẹṣin kan tí ó máa ń gùn kiri tí Ìjàpá kò sì ní nǹkankan. Ìjàpá ronú lọ́jọ́ kan, ó sì gbèrò bí yóò ti ṣe pa ẹṣin Àdàbà. Ó rí pé Àdàbà gbayì láàrin àwùjọ èyí tí kò dùn mọ̀ Ìjàpá nínú.

Nígbà tí ó di ọjọ́ kan Ìjàpá dá ọgbọ́n àlùmọ̀kọ́rọ́yín, ó pa ẹṣin Àdàbà. Àdàbà kò bínú sí kíkú tí ẹṣin rẹ̀ kú. Ohun tí ó ṣe ni pé ó gé orí ẹṣin náà ó bòó mọ́lẹ̀ ó wá fi ojú ẹṣin si ìta tí ènìyàn leè máa rí dáadáa. Bí Ìjàpá ti ń kọjá lọ ni ó rí ojú tí ó yọ síta. Eléyìí yàá lẹ́nu, kíá ó gbéra ó di ilé ọba. Nígbà tí ó dé ààfin, ó sọ fún ọba pé òun ti rí ibi tí ilé gbé lójú. Eléyìí ya ọba lẹ́nu, ó sì tún bí Ìjàpá bóyá ohun tí ó ń sọ dáa lójú. Ìjàpá sọ fún ọba pé ó dá òun lójú, ó sì tún wá fi dá ọba lójú pé bí kò bá rí bẹ́ẹ̀ kí ọba pa òun. Nígbà yìí ni ọba pe gbogbo àwọn ìjòyè àti ẹmẹ̀wà rẹ̀ pé kí àwọn lọ wo ibi tí ilẹ̀ gbé lójú. Ìjàpá ni ó síwájú tí ó sì bẹ̀rẹ̀ sí kọ orin báyìí pé;

Ìjàpá___________ Mo ti rí ibi ilẹ̀ gbé lójú
Agberin________ Ilẹ̀
Ìjàpá___________ Mo ti rí ibi ilẹ̀ gbé lójú
Agberin________ Ilẹ̀

Báyìí ni gbogbo wọn ń dá reirei lọ sí ibi tí ilẹ̀ gbé lójú. Bí Àdàbà ti gbọ́ ohun tí Ìjàpá ṣe yìí ni ó bá sáré lọ sí ibi tí ó bo orí ẹṣin rẹ̀ tí ó wó sí, ni ó bá wú orí náà kúrò lọ sí ibòmíràn. Nígbà tí ọba ìjòyè àti àwọn ẹmẹ̀wà dé ibi tí Ìjàpá wí, wọn kò rí nǹkan kan Ìjàpá bẹ̀rẹ̀ sí tú ilẹ̀ kiri títí kò rí ojú kankan. Ìgbà yí ni ọba bínú gidigidi pé Ìjàpá pa irú irọ́ tí ó tó báyìí àti pé ó tún da òun, àwọn ìjòyè àti àwọn ẹmẹ̀wà láàmú láti wá wo ohun tí kò sí níbẹ̀. Kíá ni ọba pàṣẹ pé kí wọn ó ti ojú Ìjàpá yọ'dà kí wọn ó ṣì ti ẹ̀yìn rẹ̀ kì í bọ àkọ̀.Eléyìí jásí pé wọn paá. Báyìí ni Ìjàpá fi ìlara pa ara rẹ̀.

#EdeYorubaRewa

Àlọ́ àpagbè

Àlọ́ àpagbè míràn fún gbogbo olólùfẹ́ ojú ìwé yìí. Mo lérò wípé ẹ ò gbàdúrà e
Àlọ́ oooo
Àlọ́ ọọọọ
Àlọ́ yìí dá lórí #ẸkùnàtiIkùn

Ní ìlú àwọn ẹranko, kìnnìún ni Ọba wọn. Nígbà tí ó di ọjọ́ kan, Ọba ẹranko pe gbogbo àwọn ẹranko jọ, ó sọ fún wọn pé òun fẹ́ dá ọjọ́ tí àwọn ẹranko yóò wa ṣe eré fún òun. Ó sọ pé ẹni tí ó bá lu ìlù dáadáa òun yóò da lọ́lá. Nítorí ìdí èyí ó ní kí ẹranko kọ̀ọ̀kan lọ kan ìlù. Gbogbo àwọn ẹranko gbọ́ ọ̀rọ̀ Ọba, wọ́n dárí lọ sí ilé wọn. Ẹni kọ̀ọ̀kan nínú àwọn ẹranko ń gbìyànjú à ti kan ìlù. Ṣùgbọ́n dípò kí ẹranko kan tí orúkọ rẹ ń jẹ ikún ó kan ìlù tie, ní ṣe ni ó lọ gbé ìlú ẹkùn níbi tí ẹkùn gbé e sí. Ẹkùn bẹ̀rẹ̀ sí wa ìlú rẹ, ó wàá títí kò ri. Nígbà tí ó di ọjọ́ aré, ẹkùn jí ni kùtùkùtù ó lọ dúró ní ọ̀nà tí ó lọ sí ilé kìnnìún ọba ẹranko. Bí ẹranko kọ̀ọ̀kan bá ti fe kọjá ni ẹkún yóò yọ sí i tí yóò sì sọ pé kí ó lu ìlù rẹ̀ kí òun gbọ́. Orin ni ẹkún fi ń sọ eléyìí fún wọn tí orin náà sì lọ báyìí :

Ẹkùn________ Ríkíríkijàn
Agberin_____ Àríkijàn
Ẹkùn________Ríkíríkijàn
Agberin_____Àríkijàn
Ẹkùn________ Ọba ló dájọ́ aré
Agberin_____ Àríkijàn
Ẹkùn________ Ọba ló dájọ́ ayò
Agberin_____Àríkijàn
Ẹkùn________Wọ́n ní á kànlù, mo kànlù
Agberin_____Àríkijàn
Ẹkùn________ Mo gbé ìlú mi s'àgbàlá
Agberin_____ Àríkijàn
Ẹkùn________ Ọmọ ẹranko gbé e lọ
Agberin_____Àríkijàn
Ẹkùn________ Lùlù rẹ kí n gbọ́
Agberin_____Àríkijàn
Ẹkùn________Lùlù rẹ kí n mọ
Agberin_____Àríkijàn
Ẹkùn________ Papakúkú rangbọndan
Agberin_____ Àríkijàn
Ẹkùn________ Papakùkù rangbọndan
Agberin_____ Àríkijàn
Ẹkùn________Ìlù mi kọ́ùn ni
Agberin_____Àríkijàn
Ẹkùn________ Rékọjá o máa lọ
Agberin_____Àríkijàn

Báyìí ni ẹranko kọ̀ọ̀kan ṣe ń kọjá tí ẹkùn sì ń kọ orin bákan náà. Nígbà tí ó kan ikùn láti kọjá, ẹ̀rù ti bẹ̀rẹ̀ sí bàa. Ẹkùn tún bẹ̀rẹ̀ orin rẹ̀ :

Ẹkùn________ Ríkíríkijàn
Agberin_____ Àríkijàn
Ẹkùn________Ríkíríkijàn
Agberin_____Àríkijàn
Ẹkùn________ Ọba ló dájọ́ aré
Agberin_____ Àríkijàn
Ẹkùn________ Ọba ló dájọ́ ayò
Agberin_____Àríkijàn
Ẹkùn________Wọ́n ní á kànlù, mo kànlù
Agberin_____Àríkijàn
Ẹkùn________ Mo gbé ìlú mi s'àgbàlá
Agberin_____ Àríkijàn
Ẹkùn________ Ọmọ ẹranko gbé e lọ
Agberin_____Àríkijàn
Ẹkùn________ Lùlù rẹ kí n gbọ́
Agberin_____Àríkijàn
Ẹkùn________Lùlù rẹ kí n mọ
Agberin_____Àríkijàn
Ẹkùn________ Papakúkú rangbọndan
Agberin_____ Àríkijàn
Ẹkùn________ Papakùkù rangbọndan
Agberin_____ Àríkijàn
Ẹkùn________ ìlù mi nùnun nì
Agberin_____ Àríkijàn

Bí ikùn tí gbọ́ pé ìlù ẹkùn ni òun gbé lọ́wọ́, pẹ̀ẹ̀ lójú ìlù sílè tí ó bẹ̀rẹ̀ sí sá lọ. Ẹkùn gbá tẹ́lẹ̀e,ṣùgbọ́n bí ẹkùn ṣe ni kí òun ó ki ikùn mọ́lẹ̀ ni ó ṣá wọ inú ihò lọ. Ikùn kò lọ láì f'arapa, èékánná ẹkùn ha ikùn ní ẹ̀gbẹ̀ méjèèjì. Bí ènìyàn bá rí ikùn lónìí, yóò rí pé ilà funfun wà ní ẹ̀gbẹ̀ méjèèjì ikùn di òní olónìí yìí o. Olè jíjà kò dára oooo

#EdeYorubaRewa

Ọfọ̀ Ẹ̀fẹ̀

"Dúró ń bẹ̀"
Ohun tá a wí f'ọ́gbọ́
Lọ́gbọ́ ń gbọ́
Èyí tá a wí f'ọ́gbà
Lọgbà ń gbà
Inú ẹtù kìí dùn
Kó wálé ọdún
Inú àgbọ̀nrín kìí dùn
Kò wálé dìsẹ́nbà
Aṣọ ìbora kìí lápò
Kèké kìí ya ilé epo
Ìgbín kìí fẹ́yìn rìn
Ọ̀kadà kìí ní kọ̀ndọ́
Ijọ́ tí ọmọdé bá gbé'rà lóko
Ní dé ilé
Ijọ́ tókèlé ba dọ́nà ọ̀fun
Ní I de ikùn
Mo pàṣẹ fún ọ
Óyá!!! Fi àtẹ̀jíṣé yìí ránṣé
Ẹ̀fẹ̀ lèyí àbí àwàdà.

#EdeYorubaRewa

Ọ̀RỌ̀ ìṣítí

Iṣu mi ọdún yìí
N kò ní fẹ́nìkan jẹ
Àgbàdo tí mo gbìn yìí
Kò ní kan ẹnìkan l'ẹ́nu
Ẹran ọ̀yà tí mo yìnbọn sí
Tíi mo ba ri
Emi nìkan ni yóò jẹ
Ko mọ̀ pé,
Ìgbẹ lẹran rẹ í gbé sí
Yorùbá bọ̀ wọ́n ní A kìí láhun ká nìyí
Ará ilé ahun ò gb'ádùn ahun
Ahun ọ̀hún
Ọ̀rọ̀ ìjìnlè Yorùbá lèyí
Ọmọ ahun, kò gbádùn ẹ
Ìyàwó ahun kò gbádùn ẹ
Gbogbo atótótu òkè yìí ń sàfihàn aburu
Tí ń bẹ nínú ahun ṣíṣe
Bó ṣe oúnjẹ lo ní, bó ṣe owó dákún ran aláìní lọ́wọ́
Àdáníkànje, ládánìkànku
Ẹni tó lawọ́
Kò tíì rí àánú Olódùmarè
Aánbọ̀sìbọ́sí ahun
Òkè lọ́wọ́ afúnni ń gbé
Ẹ jẹ ká jáwọ́ ahun ṣíṣe.
Ẹ má jee ká láhun nítorí ahun kò dára.
Bí ẹnikẹ́ni bá wá ìrànlọ́wọ́ dé ọ̀dọ̀ dákún gbìyànjú láti ràn wọ́n lọ́wọ́.

#EdeYorubaRewa.

Tuesday, 22 August 2017

Ìkéde tí Ààrẹ Muhammad Buhari ṣe

Èyí ni ìkéde tí Ààrẹ Muhammad Buhari ṣe ní ọjọ́ kọkànlélógún, oṣù kẹjọ ọdún 2017 (21/08/2017).

Gbogbo ọmọ orílè èdè Nàìjíríà,

1) Mo dúpẹ́ fún Ọlọ́run àti gbogbo ọmọ orílè Nàìjíríà fún àdúrà yín, inú mi dùn láti padà sí orílè èdè Nàìjíríà tí mo tí jẹ Ààrẹ.

2) Dídúró mi ní orílè-èdè United Kingdom, gbogbo ohun tí ó ń lọ ní orílè èdè Nàìjíríà ni mo mọ. Àwọn ọmọ orílè èdè Nàìjíríà gbójú gbóyà láti sọ ohunkóhun, ṣùgbọ́n inú mi bàjé láti gbọ́ àwọn ọ̀rọ̀ mìíràn tí wọ́n ń sọ, pàápàá jù lọ lórí ẹ̀rọ ayélujára.

3) Ní ọdún 2003 lẹ́yìn ìgbátí mọ darapọ̀ mọ òṣèlú, Olóògbé olóyè Emeka Ojukwu wá sí ìlú mi ní Daura gẹ́gẹ́bí àlejò. A sọ̀rọ̀ ni kíkún nípa awon ìpèníjà tí orílè èdè Nàìjíríà ń dójú kọ fún ọjọ́ méjì tí Ilé sii sú báwa níbè. Àwa méjèèjì fi orí ọ̀rọ̀ wa kò wípé orílè èdè Nàìjíríà gbọdọ̀ wà ní Ìsòkan.

4) Ìsòkan orílẹ̀ èdè Nàìjíríà ti ní ìyanjú kò sì ní ìdúnàdúrà nínú. Àko ní fi ààyè gba àwọn alaimokan láti dá wàhálà àti rògbòdìyàn sílè nítorí bí nkan bá bàjẹ́ tán, ńṣe ni wọn yíò sálọ tí wọn yíò sì jẹ́ kí ẹ̀jẹ̀ alaise ṣòfò.

5) Gbogbo ọmọ orílè èdè Nàìjíríà ni ó ní aàǹfààní láti gbé ayé àti láti lépa ohun rere tí wọ́n bá fẹ́ ṣe ni ibikíbi ni orílẹ̀ èdè Nàìjíríà láìsí ẹnì kankan tí yíò di wọn lọ́wọ́.


6) Mo nígbàgbọ́ wípé ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọmọ orílè èdè Nàìjíríà ni ó fi ara mọ́ èróngbà yìí.

 7) Eléyìí kìí ṣe láti di àwọn ènìyàn lọ́wọ́ láti má mọ ohun tí ó kàn wón. Ṣùgbọ́n ẹwà àti ifamora orílẹ̀ èdè gbọdọ̀ fi àyè gba onírúurú ẹgbẹ́ láti ṣisẹ́ kí orílè èdè yìí le tẹsiwaju.

8) Àwọn ilé ìgbìmò Asòfin àti ilé ìgbìmò ní àwọn ìlú kọ̀ọ̀kan ni ẹ̀tọ́ láti  gbìmọ̀ àti láti ṣe ìwádìí tí ó dára.

9) Ìlàkàkà àwọn ọmọ ilẹ̀ ìgbìmò náà ni wípé ó dára kí gbogbo wa máa gbé papọ ni ìrépọ̀ kí ó má sí ìpínyà láàrin wa.

10) Mo ń gbìyànjú láti má jẹ́ kí ìrẹ̀wẹ̀sì ọkàn bá  àwọn elétò ààbọ̀ látàrí àṣeyọrí tí wọ́n tí ṣe ni ọdún kan àti oṣù díè sẹ́yìn.

11) Wọ́n gbọdọ̀ lé Ìgbé sùnmọ̀mí àti ìwà ọ̀daràn jìnà kí ó le fún gbogbo wa ni àǹfààní láti gbé ní ayọ̀ àti àlàáfíà.

12) Fún ìdí yìí a gbọdọ̀ tún ṣòkòtò wa ṣán làti gbé ogun tí àwọn wọ̀nyí:

Agbé sùmòmí Boko Haram
Àwọn gbọmọgbọmọ, àwọn Darandaran àti àgbẹ̀ àti
Èdè àiyedè láàrin wa pẹ̀lú iranlọwọ àwọn olóṣèlú. A gbọdọ̀ dojú kọ wón.


13) Gbogbo olólùfẹ́ orílè èdè Nàìjíríà, ìsisẹ́ papọ wa yíò jẹ́ kí á le gbé ogun tí àwọn ìpèníjà wọ̀nyí:

·   Ètò ọrọ̀ ajẹ́

·     Ìdàgbàsókè ètò òṣèlú àwa araawa
·       Àti àlàáfíà tó yè kooro láàrin gbogbo ọmọ Nàìjíríà

14) Máa rí wípé gbogbo àwọn ìpèníjà yìí ni a borí wọn. Inú mi dùn láti padà sí orílè-èdè Nàìjíríà.

15) Ẹsẹ́ púpọ̀, Èdùmàrè a tún orílè èdè Nàìjíríà ṣe.

Àmín.

#EdeYorubaRewa

Tuesday, 11 July 2017

Ọ̀RỌ̀ Ìkìlọ̀ 2

Ẹjẹ́ ká gb'áyé ṣe rere,
Ọjọ́ a kú làá dère,
Ènìyàn ò sunwòn láàyè,
Ǹjẹ́ a lè rí ohun gidi sọ nípa rẹ tó bá kú,
Àbí àwọn ènìyàn a máa sọ wípé àtún kú tún kúù rẹ lọrun,
Ẹjẹ́ ká gb'ayé ṣe rere,
Kí ọmọ aráyé lee rí ohun tó dára sọ,
Ẹjẹ́ ká kó pa láti tún, ilé, ọ̀nà, ìlú, orílè èdè wa ṣe,
Kí a kó ipa pàtàkì láwùjo wa,
kí ọmọ aráyé lee sọ nípa wa dára dára tí a bá kú,
Ní tèmi ooo rere lè mi o ṣe,
N ò ní ṣe ìkà,
kí ọmọ aráyé lee sọ ohun gidi nípa mi.

Ìwo ń kọ?

#EdeYorubaRewa

Ọ̀RỌ̀ Ìkìlọ̀

Ohun tá a ṣe ní kọ̀kọ̀
Táa fẹ́ ká ráyè mọ̀ nípa ẹ̀
Ohun tó dára ní,
Èyí táa ṣe ní kọ̀rọ̀
Táà fẹ́ kí ẹnikẹ́ni ó rí
Ohun burúkú ni
Ṣùgbọ́n bó ò tafà sókè, tó o yídò borí
Bí ọba ayé ò rí ọ, tọ̀run ń wò ọ́
Ìwọ máa gbọ̀nà ẹ̀bùrú
Sọmọ ádámọ lọ́sẹ́
Lójú ilé ni elédùmarè ó gbà mú ọ
Ìwọ tó o ní kú lọ́wọ́
Tó o látaare
Ìwọ tó jẹ́ kìkì ìkà
Tó jẹ́ pẹ́nu to bá kàn ọ o kàn ìjàngbọ̀n
Máa ṣe nìṣó, ẹ̀san ń bọ̀
Rántí pé, ìwà tó o bá hu
Lọmọ máa débá
Ẹni tó gbèbù ìkà ọmọ rẹ yíò je àjeyó ìyà
Yíò je ajẹsẹ́kù dọmọ ọmọ
Ẹ jẹ́ ká gbélé ayé ṣe rere
Ká lè ní gbẹ̀yìn tó dùn.
Kò sí ohun tá a ṣe tí elédùmarè ò rí
Ẹ jẹ ṣe dára ní gbogbo ibikíbi tí a bá wà.



#EdeYorubaRewa

Sunday, 25 June 2017

Àlọ́ Apá kejì

Àyipadà dé fún Ògbójú-ọdẹ ti ó di Ẹlẹ́mu tóó bẹ̀ ti àwọn ará ilú ṣe akiyesi àyipadà yi.  Yorùbá ni “ojú larí, ọ̀rẹ́ ò dénú”. Ìjàpá ọlọ́gbọ́n ẹ̀wẹ́ sọ ara rẹ̀ di ọrẹ kòrí kòsùn pẹ̀lú Ògbójú-ọdẹ nitori àti mọ idi ọrọ̀ rẹ.  Laipẹ, àrùn Ṣọ̀pọ̀ná bo Ògbójú-ọdẹ eleyi dá iṣẹ́ àti gbé ẹmu fún àwọn Ará Ọ̀run dúró.  Gẹgẹbi ọ̀rẹ́ ó bẹ Ìjàpá pé ki ó bá ohun bẹ̀rẹ̀ si gbé ẹmu lọ fún àwọn Ará Ọ̀run.  Ó ṣe ikilọ fún Ìjàpá bi ikilọ ti àwọn Ará Ọ̀run fi silẹ̀.  Ìjàpá, bẹ̀rẹ̀ si gbé ẹmu lọ, ni ọjọ́ keji ti ó ri owó rẹpẹtẹ ti àwọn Ará Ọ̀run kó si idi agbè ẹmu àná, ó pinu lati mọ idi abájọ.

Ìjàpá fi ara pamọ́ si igbó lati wo bi àwọn Ará Ọ̀run ti ńmu ẹmu. Ohun ti ó ri yàá lẹ́nu, ó ri Ori, Ẹsẹ̀, Ojú, Apá àti àwọn ẹ̀yà ara miran ti wọn dá dúró, ti wọn si bẹ̀rẹ̀ si mu ẹmu. Ìjàpá  bẹ̀rẹ̀ si fi àwọn Ará Ọ̀run ṣe yẹ̀yẹ́.  Nigbati wọn gbọ, wọ́n le lati pá ṣùgbọ́n, Ìjàpá sá àsálà fún ẹmi rẹ, ó kó wọ inú ihò, wọn kò ri pa.

Ògbójú-ọdẹ reti titi ki Ìjàpá kó owó ẹmu dé.  Nigbati Ìjàpá dé, ó gbé irọ́ kalẹ̀ pé olè dá ohun lọ́nà, wọn gba gbogbo owó ẹmu lọ ni ohun ṣe pẹ́.

Ara Ògbójú-ọdẹ ya, ó gbé ẹmu lọ fún ara-orun gẹgẹbi iṣe rẹ tẹ́lẹ̀ lai mọ iwà àkóbá ti Ìjàpá ti hù silẹ̀.

Àwọn Ará-Ọ̀run wọ ijàkàdi pẹ̀lú Ògbójú-ọdẹ, nitori ó rú òfin ikilọ ti wọn fun.  Nitori imọ̀ ti ó ni lẹ́nu iṣẹ Ọdẹ, Ará-Ọ̀run ko ri Ògbójú-ọdẹ pa.  Lẹhin ijàkàdi, ó ṣe àlàyé pé ara ohun ni kò yá, ó fi àpá han, pé nitori eyi ni ohun ṣe bẹ ọ̀rẹ́ ohun Ìjàpá ki ó bá ohun gbé ẹmu lọ fún wọn.

Wọn ṣe àlàyé ohun ti Ìjàpá ti ó pè ni ọ̀rẹ́ rẹ ṣe fún wọn.  Ará-Ọ̀run dariji Ògbójú-ọdẹ pẹ̀lú ikilọ pé ki o maṣe gbára lé ọ̀rẹ́. Wọn ni ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọ̀rẹ́ ò ṣé fi okùn ọlà han, nítorí ọ̀pọ̀ ọ̀tá ló ńṣe bi ọ̀rẹ́ nitori àti jẹ.

Ẹsẹ́ púpọ̀ fún ìfojúsọ́nà yín.
#EdeYorubaRewa


Àlọ́ Apá kinni

Ọkunrin kan wa láyé àtijọ́, Ògbójú-ọdẹ ni, ṣùgbọ́n bi ó ti pa ẹran tó, kò fi dá nkan ṣe.  Ọ̀pọ̀ igbà, ki ri ẹran ti ó bá pa tà, o ma ńpin fún ará ilú ni.  Nigbati kò ri ẹran pa mọ́, ó di Ọdẹ-apẹyẹ.

Ni ọjọ kan, ògbójú-ọde yi ri ẹyẹ Òfú kan, ṣùgbọ́n ọta ibọn kan ṣoṣo ló kù ninú ibọn rẹ.  Gẹgẹbi Ògbójú-ọdẹ, o yin ẹyẹ Òfú ni ibọn, ọta kan ṣoṣo yi si báa.  Ó bá wọ igbó lọ lati gbé ẹyẹ ti ó pa, lai mọ̀ pé ẹyẹ yi kò kú.  Ó ṣe akitiyan lati ri ẹyẹ́ yi mu, kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀ ó bẹ̀rẹ̀ si wọ igbó lọ titi tó fi ṣi ọ̀nà dé ilẹ̀ àwọn Ará Ọ̀run àwọn ti wọn ńpè ni Abàmi-ẹ̀dá.

Inu bi àwọn Ará Ọ̀run nitori Ògbójú-ọdẹ yi jálu ipàdé wọn.  Wọn gbamú, wọn ni ki ó ṣe àlàyé bi ó ṣe dé ilẹ̀ wọn ki àwọn tó pá.  Ọdẹ ṣe àlàyé ohun ti ojú rẹ ti ri nipa iṣẹ́ àti jẹ àti gbogbo ohun ti ojú rẹ ti ri lẹ́nu iṣẹ́ ọdẹ.  Àwọn Ará-Ọ̀run ṣe àánú rẹ, wọn bèrè pé ṣe ó lè dá ẹmu, ó ni ohun lè dá ẹmu diẹ-diẹ.  Wọn gbaa ni iyànjú pé ki o maṣe fi ojú di iṣẹ kankan, nitori naa, ki ó bẹ̀rẹ̀ si dá ẹmu fún àwọn.

Wọn ṣe ikilọ pe, bi ó bá ti gbé ẹmu wá, kò gbọdọ̀ wo bi àwọn ti ńmu ẹmu, ki ó kàn gbé ẹmu silẹ ki o si yi padà lai wo ẹ̀hin.  Bi ó bá rú òfin yi, àwọn yio pa.  Ọdẹ bẹ̀rẹ̀ si gbé ẹmu lọ fún ara orun.  Bi ó bá gbé ẹmu dé, a bẹ̀rẹ̀ si kọrin báyìí:

Ará Ọ̀run, Ará Ọ̀run------------ Ìnọ̀mbà téré, tere múdè, ìnọ̀mbà

Ará Ọ̀run, Ará Ọ̀run o,---------- Ìnọ̀mbà téré, tere múdè, ìnọ̀mbà

Ki lo wá ṣe n’ilẹ̀ yi o-------------- Ìnọ̀mbà téré, tere múdè, ìnọ̀mbà

Ẹmu ni mo wá dá,----------------- Ìnọ̀mbà téré, tere múdè, ìnọ̀mbà

Èlèló lẹmu rẹ------------------Ìnọ̀mbà téré, tere múdè, ìnọ̀mbà

Ọ̀kànkàn ẹgbẹ̀wá,-----------------Ìnọ̀mbà téré, tere múdè, ìnọ̀mbà

Gbẹ́mu silẹ ko maa lọ------------Ìnọ̀mbà téré, tere múdè, ìnọ̀mbà

Ará Ọ̀run, Ará Ọ̀run o,----------------Ìnọ̀mbà téré, tere múdè, ìnọ̀mbàaa

Lẹ́yìn èyi á gbé ẹmu silẹ á yi padà lai wo ẹ̀hin gẹgẹ bi ikilọ Ará Ọ̀run. Ni ọjọ́ keji, á bá owó ni idi agbè ti ó fi gbé ẹmu tàná wá.
Ẹ kú ojú lọ́nà fún ìyókù.

#EdeYorubaRewa


Monday, 29 May 2017

Ayẹyẹ ìjọba tiwantiwa

Ó pé ọdún kejìdínlógún tí orílè èdè Nàìjíríà tí ń lo ìjọba tiwantiwa leyin igba ti ológun tí ń darí wá.

Mo kí gbogbo àwọn ọmọ orílè èdè Nàìjíríà nílé lóko àti lẹ́yìn odi wípé a kú ayẹyẹ ìjọba tiwantiwa (Happy Democracy day). Mo mọ wípé inú ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọmọ orílè èdè Nàìjíríà ni o dùn látàrí bí nkan ṣe rí, ẹ jẹ́ kí a nígbàgbọ́ ni àwọn tí ó wà lórí ipò báyìí wípé wọn a mú wa dé èbúté ògo.

"Ọ̀rọ̀ Yorùbá kan ló sọ wípé sùúrù kìí pọ̀ jù àfi tí kò bá ní tó."
Mo mọ wípé ìjọba tí a ní lori ipò báyìí ń gbìyànjú láti jẹ́ kí orílè èdè Nàìjíríà dara,ki o rọrùn fún tolórí telémù,Ǹkan tí ó ti bá jẹ́ fún ọdún mẹ́tadínlógún kólé ṣe ẹ túnṣe láàrin ọdún díè tí àwọn ìjọba yìí dé ibè ìdí nì tí ó fi ye ká ní sùúrù.
Ìjọba  Nàìjíríà,  ẹ bá wà tún orílè èdè wa ṣe, ẹsẹ àtúnṣe sì gbogbo ohun tí oti bàjé kí inú àwọn tí ó dibo fún yín lé dùn.

Iṣẹ́ wa lọ́wọ́ àwa náà tí a jẹ́ ọmọ orílè èdè Nàìjíríà, lábé bí ó ti wù kí ó rí Ẹjẹ́ kí àwa náà rán ìjọba lọ́wọ́ látàrí kí a jẹ́ ọmọ ẹ̀yìn rere

Gbogbo ọmọ orílè èdè Nàìjíríà ẹ jẹ ká ní sùúrù àti èmi ìfaradà fún Ààrẹ Muhammad Buhari àti gbogbo àwọn tí ó kó sódì kí wọn lè mú wa dé èbúté ògo.

Dídára orílè èdè Nàìjíríà ó wà lọ́wọ́ èmi àti ìwọ ẹ jẹ́ kí á jọ ṣe.orílẹ̀ èdè Nàìjíríà yíò dára tí ó bá dára tán kí wọn má fi wa ṣe àwátì

🇳🇬🇳🇬🇳🇬🇳🇬🇳🇬
Semiat Olufunke Tiamiyu
#EdeYorubaRewa



Thursday, 25 May 2017

Ìtàn òwe Yorùbá

Ìtàn tí ó rò mó òwe Yorùbá yìí,

                   "Kí lo rí l'ọ́bẹ̀ tí fi waaro ọwọ́."

Ní bí ọdún díè sẹ́yìn, ìlú kan wà tí wọ́n ń pè ní Kuo, ó wá ní Bode Saadu ni Ìpínlẹ̀ Kwara ṣùgbọ́n ìlú tí à ń sọ yìí jóná ni ọdún 1814.

Gbogbo Yorùbá kó ló máa ń lo òwe yìí tẹ́lẹ̀, ogun ni ó sì fà á tí òwe yìí fi wáyé.
Ìlú tí a ń pè ní Kuo yìí ni olórí tí orúkọ rẹ ń jẹ́ Sholá Gberú. Nígbà tí ìlú Kuo jóná Sholá Gberú kò gbogbo àwọn ọmọ, ẹrú àti gbogbo ohun tí wọ́n ni lọ sí ìlú Ilorin,nígbà náà afonja wa láyé. Ìlú kan wà láàrin Ọ̀yọ́ àti Ilorin,ìlú Gbógun ni ìlú náà ń jẹ́, tí ogún bá sì fẹ́ ja Ọ̀yọ́ wọn gbodo kọ́kọ́ ja ìlú Gbógun tí à ń Wiyi. Nígbà tí wọ́n fẹ́ kogun ja ìlú Gbógun ALÁNÀMÚ ni lèdí àpò pọ̀  láti kogun ja ìlú Gbógun.


Arákùnrin tí wọ́n ń pè Alánàmú Pankere ní o ma ń fi jà, tí ó bá ti fi náà ẹni tí wọ́n dìjọ ń jà fi ń jà, ẹni náà ara rẹ̀ yíò wálè yíò sì na'wọ́ mú ẹni náà ìdí rẹ tí wọ́n fi ń pe ni ALÁNÀMÚ.
Alánàmú sì so ọwọ́ pò mo Ilorin, wọn sì mú orí ìyàwó ọ̀pẹ̀lẹ̀ mó ara, Wọ́n fún ní májẹ̀lé pé kí ó fi si inú oúnjẹ. Wọ́n rán àgbà ọmọ Sholá Gberú sí ọ̀pẹ̀lẹ̀, ìyàwó ọ̀pẹ̀lẹ̀ dáná oúnjẹ, ó sì ti fi májẹ̀lé si inú ounje náà, ọ̀pẹ̀lẹ̀ àti ọmọ Sholá Gberú tí fọ ọwọ́, bí ọmọ Sholá Gberú tí bu òkèlè pé kí ohun fi kan ọbẹ̀
Ó bá wararo ọwọ́. Ọ̀pẹ̀lẹ̀ bíi pé kí lórí l'ọ́bẹ̀ tí ó fi wararo ọwọ́, ló bá ní májẹ̀lé rẹ nínú ọbẹ̀.....
Báyìí ni Ọ̀pẹ̀lẹ̀ ni Bí kú ilé ọ bá pani tode ó lè pani.

Ìtàn tí ó rò mó òwe KÍ LO RÍ L'Ọ́BẸ̀ TÍ Ó FI WAARO ỌWỌ́. májẹ̀lé ni ó rí l'ọ́bẹ̀ tí ó fi Wararo ọwọ́.

Mo lérò wípé ẹ gbádùn ìtàn yìí.

#EdeYorubaRewa


Sunday, 14 May 2017

Ìtàn ránpé.




E bá Ẹfọ̀n l'ábàtà, ẹ yọ Ọ̀bẹ tí, Omi le rò wípé ó mu kú ni?

Ìtùmò Òwe yìí: a kìí kánjú tàbí yára sí àwọn aàǹfààní tí a bá rí nítorí ó lè jẹ́ iṣẹ́ takuntakun tí ẹnìkan tí ṣe.

Ìtàn ránpé tí ó rò mó Òwe yìí.

Ní ayé àtijó bàbá ọdẹ kan wà, bàbá yìí tí ń de ìgbẹ́ fún ọ̀sẹ̀ díè ṣùgbọ́n kò rí ẹran kankan pa. Nígbà tí ó ṣe èdùmàrè jẹ́ kí ó rí ẹran Ẹ̀fọ̀n, ó yin Ẹfọ̀n yìí ni Ìbon ṣùgbọ́n ìbon yìí kò pá Ẹfọ̀n yìí kíákíá leyi tí ó mú kí Ẹfọ̀n yìí sálọ. Bàbá ọdẹ yìí ri ó sì rántí pé ohun kò ní ohun jíjẹ fún ọjọ́ díè sẹ́yìn, èyí sì mu kí bàbá ọdẹ yìí wá Ẹfọ̀n pẹ̀lú ìgbàgbọ́ pé ìbọn tí ó bá ó ti pá. Lẹ́yìn ọjọ́ díè, Ẹfọ̀n yìí kú sí àgbàlá ẹnikẹ́ni nínú abúlé, kí bàbá ọdẹ yìí tó dé ibè àwọn ènìyàn abúlé náà tí rí wípé Ẹfọ̀n tí kú sí inú àgbàlá wọn leyi tí wọ́n rò wípé òrìṣà àti Baba ńlá àwọn ni ó see

Gbogbo ènìyàn sì lọ sí ibi tí Ẹfọ̀n yìí kú sí pẹ̀lú Ọ̀bẹ láti pín láàrin ara wọn, ṣùgbọ́n kí wọ́n tó bẹrẹ si maa ge bàbá Ọdẹ yìí dé ibè ó sì dá wọn dúró ní o bá sọ wípé "E bá Ẹfọ̀n l'ábàtà, ẹ yọ Ọ̀bẹ tí, Omi le rò wípé ó mu kú ni?"

Mo lérò wípé ìtàn ránpé yìí ni ìtumò sí yín.
Ẹsẹ́ púpọ̀
Ẹ kú ojú lọ́nà fún tí ọjọ́ méjo..
#EdeYorubaRewa

Tuesday, 9 May 2017

Òrùn Ati Òṣùpá

Ìtàn Òrùn Ati Òṣùpá fún àkà gbádùn yín......
nígbà ìwásẹ̀, ọba ọdẹ Ọ̀run níse alákoso ohun gbogbo, ìkáwọ́ rẹ̀ ṣì ni gbogbo ohun tí a dá wà.ọba ọdẹ Ọ̀run ní ìyàwó , ósì tún bí ọmọ méjì. ÒRÙN àti ÒSÙPÁ ni ọmọ méjì tí ọba ode ọ̀run bí. Òrùn àti òsùpá fẹ́ràn ara wọn gidigidi, tí ó jẹ́ wípé bí òsùpá ò bá ṣí nílé òrùn kòní jẹun àfi ìgbà tí òsùpá bá dé ,bẹ́ẹ̀ nọ sì ni òsùpá bí òrùn kò bá dé kò ní jẹun.
Ní ọjọ́ kan ọba ọdẹ ọ̀run ránsé sí òṣùpá àti òrùn ọmọ rẹ wìpè kí wọn wà rí òhun. nígbàti wọn dé bè , ọba ọdẹ ọ̀run sọ fún wọn wípé òhun fẹ rìn irìnàjò kan tí yóò sì pẹ́ kí òhun tó padà , óní kí òṣùpá àti òrùn lọ fi oríkorí kí wọn se àpérò ẹni tí yóò delé de òhun tí òhun bá wà ní ìrìnàjò. Wọ́n dúpé lọ́wọ́ bàbá wọn, wọn sì se ìlérí láti se gẹ́gẹ́ bí bàbá wọn ti sọ.
Ní ọjọ́'rù ọ̀sẹ̀ kan náà, òṣùpá àti òrùn fi ojú kan ra, sùgbón ọ̀rọ̀ ò wọ̀ láàrín àwọn méjèèjì lérí ẹni tí yóò délé nígbàtí bàbá wọn bá lọ. òṣùpá ní òhun ọkọ ẹgbàágbèje ìràwọ̀ ni yóò delé de bàbá àwọn, béèni òrùn tutọ́ sókè fojúgbàá wípé òhun ìmólè ọmọ aráyé ni yóò delé de bàbá àwọn , óní láì sí èmi òrùn inú òkùnkùn biribiri ni ayé kò bá wà,ó ní èmi àfi ojojúmó dára bí egbin, òsùpá sọ wípé tí o bá rí béè ọmọ aráyé òní máà sọ wípé isẹ́ lò òsùpá se lájùlé òrùn, óní òhun ni yóò delé de bàbá wọn.
Bí wọ́n ti ń gba ọ̀rọ̀ náà bí ẹni gba igbá ọtí re ,títí ó fi di ìjà. òsùpá lu òrùn ní ìlú ẹni lu bàrà, òrùn náà sí lu òsùpá bákan náà.
nígbátì bàbá wọn gbọ́ sí ọ̀rọ̀ náà inú rẹ bàjé,óní kí wọ́n pe àwọn méjèèji wá sí àgbàlà olódùmarè,ní ibẹ̀ ló ti jẹ kóyé wọn wípé òhun ọba ọdẹ ọ̀run ní se alákòso ọ̀sán àti òru,óní ní ìdí èyí òhun yóò pin ìlú náà sí méjì,óní kí òṣùpá máà jọba lérí òru , ósì ní kí òrùn máà jọba lóri ọ̀sán wọn kò sì gbọdọ̀ fi ojú kan ra gẹ́gẹ́ bí ìjìyà ẹ̀sẹ̀ wọn.
Ní ọjọ́ yíí inú òṣùpá àti òrùn bàjẹ́ nítorí wọn kòní fo jú kan ra mọ́ àti wípé àyè àti má se bí ẹbí ti dópin. Ìgbà kúgbá tí òrùn àbí òṣùpá báti rántí ìdájó yii ,nínú ọdún wọn a máa sunkún lọ́pọ̀lọpọ̀ ,ekún wọ̀nyí ni àwa ọmọ ènìyàn ńpè ní ÒJÒ.
#Ìbéèrè
Kíni Èkó Inú Ìtàn Yìí?
#EdeYorubaRewa




Ọ̀RỌ̀ ÌDÚPẸ́

Kíni mo jẹ́? Tani ni mí? Tí Kò bá sí èyin, kò lè sí ojú ìwé #EdeYorubaRewa. Yorùbá bò wọn ní "Àgbáj'ọwọ́ la fi ń sọ̀'yà, Àjèjí ọwọ́ kan kò gbẹ́'rù dó'rí" leyi tí ó túmọ̀ sí wípé ọlá Ọlọ́run àti ọlá gbogbo olólùfẹ́ Èdè Yorùbá Rẹwà ni ó fún mi ní agbára láti máa ṣe ohun kékeré tí mò ń ṣe láti gbé èdè Yorùbá lárugẹ.... Mọ wá dúpẹ́ púpọ̀ lọ́wọ́ gbogbo àwọn tí wọ́n fẹ́ràn àti àwọn tí wọ́n tẹ́lẹ̀ wa lórí ẹ̀rọ ayélujára Facebook, Twitter, Instagram, Blog àti WhatsApp,èdùmàrè ò ní paná ìfẹ́ wá.
Mo sì tún fi àsìkò yìí dúpẹ́ lọwọ gbogbo àwọn tí wọ́n ni ìgbẹ́kẹ̀lé dáadáa nínú wa ti wọ́n sì fi ìfẹ́ báwa ra aṣọ tí a ṣe láti fi ṣe ayẹyẹ ọdún kan, elédùmarè a nífẹ̀ẹ́ gbogbo yín ooo.
Mo wá ro gbogbo àwọn tí wọ́n ra aṣọ náà kì wọn ó fi àwòrán wọn ránṣé sí mi láti lè fi sì ojú ìwé EdeYorubaRewa
Ẹsẹ́ púpọ̀
#EdeYorubaRewa