Tuesday, 30 August 2016
Ọba aláyéLúwà
Ìwòfà pàdé ọba lọ́nà,
Ó gbàdúrà kẹ́lẹ́ kẹ́lẹ́,
Pé bóyá orí a ṣé,
Òun náà a dépò ọba,
Láì mọ̀ wípé,
Orí adé ò jẹ́rù ọba o fúyé,
Lotito ipò ọba dára,
Ipò kábíyèsí dára púpọ̀,
Ṣùgbọ́n ìdààmú ìdí rẹ̀ pọ,
Ọba ò lẹ́sìn,
Bọ́dún Mùsùlùmí dé,
Ó dí dandan kó bá wọn ṣe,
Bí àwọn kirisititeni ń sọdún,
Ó gbọdọ̀ báwọn ṣe,
Bí ẹṣin àbáláyé ṣe tiẹ̀ ó gbọdọ̀ kó pá,
Nítorí ó ní ipa pàtàkì láti kó,
Ọ̀pọ̀ nnkan lo wa,
Tí ọba ó gbọdọ̀ ṣe,
Torí ipò ẹlẹgẹ́ tó dì mú,
Gbogbo ojú ni n bẹ lára ọba,
Ọba o lè sẹ̀yọ́ ní gbangba,
Ọba kìí jẹun ní ìta,
Ọba ò gbọdọ̀ sè yí ṣe tọ̀hun,
Bí o tilè jẹ́ pé,
A ó mọ bí wọn tíì ń sìnkú ọba,
Ó dájú wípé ọba kìí sùn bí i mẹ̀kúnnù,
Ipò ọba dára ṣùgbọ́n ohùn tó rọ mọ pọ̀,
Ìdí rẹ ni yìí tí Yorùbá má fi ń sọ wípé
#Ilésanmíwọnlódùnjoyèlọ.
Ẹ jẹ́ kí a má dúpẹ́ ni gbogbo ipò tí a bá ara wa....
Èdùmàrè jẹ́ kí gbogbo ọba ilé Yorùbá pé bí mópé tí ń pé,
Kádé pé lórí gbogbo wọn, kí bàtà pé lẹ́sẹ̀ wọn, kí ìrùkèrè wọn di ọkini....
#ÀmínÀṣẹÈdùmàrè
Sunday, 28 August 2016
Oríkì Ọ̀kà Àkókó
Ọmọ olókàrufè,
Ọ̀kà Àkókó Ọ̀kàrúfé,
Ẹkùn ńlá fi orí òkè ṣe ibùgbé,
Ogunkógun kò le dojú kọ,
Ẹkùn ni bùdó Ogun tó bá dojú kọ Ẹkùn ni bùdó ẹ ní náà yíò dẹni ẹbọra,
Ọmọ ori òkè Afòkúta rigidi bọ ogun jà,
Tó bá yi kú atun yi kéé Ogun,
A sin túká Ọ̀kàrúfé Ayeye bí Èṣù,
Ọ̀kàrúfé ṣe méjì gbogbo Àkókó ṣe mẹ́ta.
Èdùmàrè jọ̀wọ́ jẹ́ ìlú Ọ̀kà Àkókó pé
Àmín Àṣẹ Èdùmàrè
Ìlú Ọ̀kà Àkókó wá ní ìpínlè Òndó
Saturday, 27 August 2016
Oríkì Ede
Ede màpó arógun,
Iyako agbo
Èyin Ọmọ ají lala ọsọ
Ọmọ ají sọsọ
Ọmọ ají f'ọjọ́ gbogbo dára bí egbin,
Ede ọmọ elepo rédé,
Ọmọ ẹwà a dodo,
Èyin lọmọ arohanran,
Ọmọ aje ń ju,
Èyin lọmọ agbale gbira tó l'ede ilé,
Èyin lọmọ alápò tì'emi tì'emi
Èyin lọmọ arógun má fi t'ìbọn se
Ede ìlú timi Ọlọ́fà iná.
Mo kabiyesi fún ọba Timi agbale, ọba Muniru Adesola Lawal Laminisa 1
Ìlú Ede o ni bàjé o
Àmín láṣẹ èdùmàrè
Tedx
A ń ṣe ọ̀pọ̀lọpọ̀ nkan tó ju sísọ ọ̀rọ̀ tí ó móríyá lọ. A ní àwọn ìrírí tí yíò yà yín lẹ́nu, tí yíò si yíì ìgbésí ayé ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn padà. Ẹ má fojú sọ́nà lásán o. Ẹ fi ọjọ́ náà sì inú ìwé ìrántí tí yín.
Ọ̀fẹ́ ni gbogbo àwọn tí ó bá wá ó wọlé, a ṣí àyè iforukosile sílè láìpé. Àyè wá fún ẹnikẹ́ni tí ó bá fẹ́ rán wa lọ́wọ́ àti bá wa ṣe pọ.
Ẹkan sí wa lori sponsorships@tedxisalegeneral.com fún iranlowo.
Emdee Tiamiyu,
Curator, TEDxIsaleGeneral.
Oríkì Ìkàré Àkókò
Ọmọ olókè méje takọtabo,
Omi atan, ọmọ ase Ìkàré ribárìbo,
Osekiti gere
Ìkàré ọmọ igi mẹta ọ̀nà osélé,
Ìkan Udi,
Ìkan ure òṣìṣẹ́ lóni wo,
Owa àlè moru orun òdì,
Ìkàré lọmọ àjùwàjùwà Ìlèkè,
Ótorí ìlèkè níikú royo royo,
Èyin lọmọ igiri òkè
Ọmọ Arésè gbomi gbẹ,
Ṣebí ẹ̀yin le lókùúta, lelapata,
Ìkàré ọmọ àpáta dowo ọtun dolà,
Ọmọ osoro làjòjì sọnu,
Àjòjì forí kó nini òwúrò,
Èdùmàrè báwa dá ìlú Ìkàré sí, ìlú Ìkàré ó ní bàjé (Àmín láṣẹ èdùmàrè)..
Ìkàré jẹ́ ọkàn lára àwọn ìlú tó wà ní ìpínlè Òndó
Oríkì Èjìgbò
Ọmọ kíkan ará Èjìgbò,
Èjìgbò moro,
Ọmọ apa ẹran ńlá bàjé,
Ọmọ onírè Ooni
Ọmọ ọkọ Saki,
Ará ọrun
Ọ̀run mowó,
Ọmọ aṣọlékè gbaariye,
Ọmọ ọkọ kò sani léṣe kaparun
Ọmọ ewú kele maja
Irenimogun ọmọ awúlẹ̀ wúwo
Irenimogun taran l'àgbère
Ògún Onírè ọmọ abúlé sowo
Èèyàn ò bímọ nírẹ̀ kó tosi
Èèyàn ò bímo nírẹ̀ kò rahun ọwọ́ nina..
Èdùmàrè jọ̀wọ́ jẹ́ kí ìlú Èjìgbò dára...
Ìbéèrè ìfẹ́
Ǹjẹ́ tí bá fi àlébù mi hàn ìwo olólùfẹ́?
Ǹjẹ́ o kòní jámi kulè?
Ǹjẹ́ o lè fara da ìwà mí?
Ǹjẹ́ o lè fara da ìṣe mí?
Ǹjẹ́ tí nkò bá lè mú okàn mi le?
Ǹjẹ́ ìwo òní fimísílè bá elégàn lo?
Ǹjẹ́ ìwà àti ìṣe mí dára
Ǹjẹ́ o lè Femi pẹ̀lú ṣùgbọ́n mi?
Ǹjẹ́ o le jè ògbùnró mi?
Ábí ìwo ájámikulè torí àlébù mi?
Ranti Èmi èrò omi,ìwo onílù ìsàlè odò.
#Gbìyànjú kí o nífẹ̀ẹ́ olólùfẹ́ pẹ̀lú ṣùgbọ́n tàbí àléébù tí o ní...
Ìfẹ́ dùn o dára
Thursday, 25 August 2016
Osun State Anthem
Iṣẹ́ wa fún ilẹ̀ wá,
Fún ilẹ̀ ìbí wá,
kagbégá, kagbégá, kagbégá, fáyérí,
Ìgbàgbọ́ wà ní pé ẹ
Báṣé bérú labọmọ,
Káṣiṣẹ́, Káṣiṣẹ́, Káṣiṣẹ́, ká jọlà,
Ìsòkan a'tòmìnira ní kẹjẹ́ ká máa lépaa,
Tẹsiwaju,
Fọpọire àtohun tó dára a
Ọmọ odu'a dìde bósí ipò ètó rẹe
Ìwọ ní , imọ́lè gbogbo adúláwò.
Ìpínlẹ̀ Òsun òní dàrú, orílè èdè Nàìjíríà òní bàjé. Àmín láṣẹ èdùmàrè...
Ṣe boo tí mọ ẹlẹ́wà sàpọ́n"
Ìtàn míràn rèé oo fún ìgbádùn yín
Ìtàn "Ṣe boo tí mọ ẹlẹ́wà sàpọ́n"
A má ń gbọ́ tí àwọn ènìyàn má ń sọ pé "ṣe bí o timo ẹlẹ́wà "sàpọ́n" ọ̀pọ̀lọpọ̀ ló rò wípé òwe tàbí àṣàyàn ọ̀rọ̀ àtayébáyé kan ni. Kí ṣe bẹ́ẹ̀ oo, ẹnikan ni ó fi d'àṣà, àṣà náà wá tàn kálékáko ní ilé Yorùbá.
Ojà kan wà ní ìlú Abẹ́òkúta ní ìpínlè Ogun tí orúkọ rẹ ń jẹ "sàpọ́n" ọjà yí gbayì púpò ní ayé àtijó, ó jé ibi tí gbogbo àwọn ọkùnrin tí kò n'ìyàwó ní ilé tí máa ń jẹ àje yó bámú bámú látàrí onírúurú oúnjẹ tí ó wà, òun mímú náà o gbéyìn. Fún ìdí ẹ yí ni wọn fí ń pe ọjà náà ni sàpọ́nloore. Ìyá kan wà nínú ọjà yí tí orúkọ rẹ ń jé Odesola, ẹwà sísè sì ni ohun nta, ìyá yìí ló má d'àṣà wípé "ṣe boo timo".
Ẹwa ìyá yí dùn púpò tó fi jẹ́ pé kíá ló gb’orí l’ọwọ́ gbogbo àwọn ẹlẹ́wà tó wà ní agbègbè náà, tí orúkọ rẹ si gbajúmọ̀ káàkiri. Ìkòkò kékeré kan ló fi bẹrẹ, ṣùgbọ́n kò pẹ púpọ̀ tí òwò náà fi di ńlá, ló bá di'ko máà ṣe odidi àpò ẹwa kan tà l’ọjọ́ kan ṣoṣo. Ìkòkò ẹwa wá pọ lọ bíi rẹrẹ nínú ìsò rẹ pẹ̀lú ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ọmọ iṣẹ́. Ṣe ni ọgọọrọ àwọn ènìyàn a pé leè lórí pitimu, tí wọn aa tò lọ bẹẹrẹ láti ra ẹwa, àfi bíi pé ó fi oyin sí ẹwa rẹ ni.
Bí àwọn kan tí nj’oko jẹẹ ní isọ rẹ l’àwọn míì ràn ń raa lọ s’ilé wọn.
Nínú àkọsílẹ̀ tí a rí kà, ẹja ni ìyá yìí ń tà tẹlẹ. Ó ń kiri ẹja panla rẹ yí lọ l’ọjọ́ kan ló ni k’oun ra ẹwa jẹ l’ làdúgbò kan ní Abẹ́òkúta. Ọbẹ̀ ata tí wọn bù lé orí ẹwa yi fún un ko tẹ l’ọrùn l’òun náà bá pinnu láti bẹrẹ ẹwa tita.
Gbogbo àì ṣe dédé tó ti rí lọdọ àwọn ẹlẹwa tó kú ni òun ṣe àtúnṣe rẹ nígbà tí ó bẹrẹ ẹwa. Òwò tí a bá fi ọgbọ́n iwé pilẹ rẹ a máa yàtọ̀ sí tí ẹni tí kò kà ìwé, nígbà tí òwò ìyá yi gbẹrẹgẹjigẹ tán. Ọ̀nà kìíní tó máa ń gbà dá àṣà yí ni pé ó máa ń sọ fún awọn oníbárà rẹ pé kí wọn ṣe bí wọn tí mọ, kí wọn má jẹ ju iwọn owó tó wà l’àpò wọn lọ, kí wọn má si ra ẹwa ju iwọn ti ikùn wọn leè gbà lọ bí owó tìẹ wà l’àpò .
Ẹwa pọ n’ìgbà náà. Ọ̀nà kejì ni pé ẹwa yi máa ń tètè tán, t’ẹwa ìyá bá tí tán tí àwọn kan bá béèrè pé kílódé tí kò ṣe ẹwa si a wípé ‘emi o le ṣe ju agbára mi lọ o, ṣe boo ti mọ l'ayé gba’.
Ìyẹn já sí pé ìyá ò le sè ju àpò ẹwa kan l’ojúmọ́ , ìwọ̀n ni wàhálà owó gbọdọ mọ.
O le ya yin l’ẹnu pe ìyá ẹlẹwa sàpọ́n yi si wa l’oke eepẹ. Eni ọdun mejidinlaadorunni ìyá bayi , kí Ọlọ́run jẹ́ k’ọjọ́ wọn o dale. Gẹgẹ bi mo se gbọ, a bi ìyá yi ni ọdún 1925. O bẹrẹ ẹwa títà ni 1951, o si fi isẹ yi silẹ nítorí idiwọ inu ẹbi ni ọdún 1996. O wa jẹ pe ọdún márùnlélogójì ní ìyá ẹlẹwa sàpọ́n fi ta ẹwa. Ninu akọsilẹ awọn to ba iya ẹlẹwa sàpọ́n s’ọrọ láìpẹ́ yí, ìyá tí ta ẹwa fun Ọba ilu ri, iyẹn Osilẹ Òkè Ona to wa l’orí itẹ lásìkò náà, Ọba Alimi Adedapo. Won ni bi Ọba yi ba ni àlejò pàtàkì tó sii jẹ pé ẹwa lo wu wọn láti jẹ, iya ẹlẹwa sàpọ́n ni wọn maa nbẹ n’isẹẹ. Wọn tí gbe ojú pópó gba ibi tí ìyá yí tí ń ta ẹwa.
Ipò tí ìyá ẹlẹwa sàpọ́n wa báyìí o fi dára to òkìkí ti wọn ti ni nígbà Sangoòde wọn.
Ìtàn ìyá ẹlẹwa sàpọ́n re o, ìyá wa Odesola ni ìlú Abẹ́òkúta Aráyé ò gbàgbé wọn, ayé a gbàgbé ìjòyè pàtàkì , wọn a gbàgbé olówó ṣùgbọ́n, ó di ọjọ́ ayé bá paré kí èdè Yorùbá ó tó parun, bí èdè Yorùbá ò bá sí parun, a òle gbàgbé ẹlẹwa sàpọ́n láyé kaafata.
Iṣẹ́ ẹni ni Iṣẹ́ ẹni, ma tijú Iṣẹ ́rẹ. Ẹni bá jalè nìkan ló b’ọmọ je. Ìyá ẹlẹwa sàpọ́n o tijú Iṣẹ́ rẹ, ìyá f’isẹ gbé èdè Yorùbá lárugẹ.
#Àwọn ìbéèrè tí tó ṣe pàtàkì.
1) Kíni àwọn ijọba ìpínlè Yorùbá ńṣe ni pá iru àwọn èèyàn báyìí , tí wọn gbaju gbaja nìdí Iṣẹ́ wọn ti ọna ti wọn gbà se Iṣẹ́ wọn di àṣà ati àṣàyàn ọrọ to ngbe èdè Yorùbá lárugẹ titi láé láé?
2) Kíni ayé o mọ iwọ àti èmi si n’igba ayé wa àti nígbà tí a bá p’ẹyinda tán?
3) Ǹjẹ́ Iṣẹ́ ọwọ tiẹ se e fi yangàn ?
#Ẹ̀jẹ̀ ká gbà'ayé ṣe #rere
written by Semiat Olufunke Bello(Wuraola)
Wednesday, 24 August 2016
Ìtàn bàbá alájo sómólú
Ìtàn bàbá alájo sómólú
#alàjọsómólútíógbaowóolówóigbaènìyàntíkòsisekoorúkọwọnsílètíkòsiowókófúnẹnikẹ́ni
Ìtàn bàbá alájo sómólú
Gbogbo la mọ orúkọ náà.
Alphaeus ni ọjọ́ kẹrindínlógún oṣù Kẹ̀sán ọdún 1915 ni ìlú kan tí wọn pè ní Isan Oyin (tí wọn pè ní Isonyin lakoko yí) ìlú náà wá létí Ìjẹ̀bú Musin àti Ìjẹ̀bú Ode ni Ìpínlẹ̀ Ógùn. Wọn gbọ́ igbe àwọn ọmọ tuntun láti ọ̀dọ̀ arábìnrin kan tí orúkọ rẹ ǹjẹ́ Grace Okuromiko Olunaike tí o bímọ ọmọ tí a ń pè ní etaoko.
Kété tí wọn sọ fún ohun àti ọkọ rẹ pé ọmọ mẹta lo bí ní ẹkan náà, inu wọn bàjé, wọn sì bu sekun, iporuru gba ọkàn wọn nítorí pé wọn etaoko sí nkan abàmì ni ìlú wọn, ẹni èyí tó jẹ́ wípé wọn a ìkan nínú àwọn ọmọ náà fún ẹbọ.
Nígbàtí tí wọn pé ọmọ ọdún merin bàbá wọn kú, ìyá àti ẹ̀gbọ́n obìnrin tí wọn ní lọ tọju wọn, ṣùgbọ́n laipe laijina ọmọ Kehinde náà kú lèyí tí ó jẹ pé Taye nìkan ló kù.
Kò parí ẹ̀kọ́ rẹ tí ẹ̀gbọ́n baba rẹ Torimoro fi mú lọ sí ìlú Èkó láti Tẹsiwaju nínú ẹ̀kọ́ rẹ.
Orí rẹ ko yọ lọ́wọ́ fífi rúbọ ní ọdún 1927, nígbà tí ó dé ìlú Èkó wọn fi sí ilé ìwé St. Johns School, Aroloya.
Láti ibè ó wọ ilé ìwé Christ Church Cathedral , ní ìlú Èkó Lagos, ó sì ṣe tán ni ọdún 1934.
Lẹ́yìn ọdún méjì tí ó ti parí ẹ̀kọ́, ẹ̀gbọ́n baba rẹ lọ fi sì ẹnu ẹ̀kọ́ ìṣe aṣọ ríran, ó sì kó ìṣe náà fún ọdún mẹsan kí ó tó gbà òmìnira.
Ó bẹ̀rẹ̀ si rán aṣọ ṣùgbọ́n owó tí o un wọlé kéré tí kò sì tó gbọ́ bùkátà látàrí èyí ó wà ọna miran ti owó lè má gba wọlé, ní àkókò yí ẹ̀gbọ́n baba Torimoro fe lọ sí oríle èdè Kamẹrúùnù fún ìṣe Taiwo sì tẹ le lọ bo yà ọ̀nà yí ọ sí.
Oríkì ìbejì
Wíníwíní lójú orogún
Ejìwọ̀rọ̀ lojú ìyá ẹ̀,
Ẹ̀jìrẹ́ ará ìṣokún,
Ẹdúnjobí,
ọmọ a gbórí igi rétẹréte,
Ọkàn ń bá bí méjì ló wọlé tọ míwá,
Ọ́bẹ́kíṣì bẹ́kéṣé,
Ó bé sílé alákìísa,
Ó salákìísà donígba aṣọ.
Gbajúmọ̀ ọmọ tíí gbàkúnlẹ̀ ìyá,
Tíí gbàdọ̀bálẹ̀ lọ́wọ́ baba tó bí í lọmọ.
Bééni, Kehinde ń tó lẹ́yìn,
Táyélolú ni àbúrò,
Kehinde ni ẹ̀gbọ́n,
Táyélolú ni a rán pé kí o ló tó ayé wò,
B'ayé dára , bi ko dára
Ayé dun bi oyin
Táyélolú, Kehinde, ni mo ki
Ejìwọ̀rọ̀ lojú ìyá ẹ̀
O dé ilé ọba tẹ̀rín-tẹ̀rín,
Jẹ́ kí nrí jẹ, kí n rí mú.
èdùmàrè fún gbogbo àwọn tó ń w'ojú rẹ ní ọmọ gbajúmọ̀ bí ìbejì bí oooo...
Tuesday, 23 August 2016
Ajá Ọdẹ
Ọdẹ: Ajáà mi dà
Àwọn ará ìlú: Ajá Ọdẹ
Ọdẹ: Ajáà mi dà
Àwọn ará ìlú: Ajá Ọdẹ
Ọdẹ: Òkémọ kéréú
Àwọn ará ìlú: Ajá Ọdẹ
Ọdẹ: Òsọ sàkà gbe mì
Àwọn ará ìlú: Ajá Ọdẹ
Ọdẹ : Ò gbálẹ̀ gbáràwé
Àwọn ará ìlú: Ajá Ọdẹ
Ọdẹ: Ajáà mi dà
Àwọn ará ìlú: Ajá Ọdẹ
Saturday, 20 August 2016
Òmìnira
#Òmìnira
Òmìnira ṣe pàtàkì,
Òmìnira ṣe koko fún gbogbo ohun elédùmarè dá,
Bí ènìyàn bá nínú ìnira tàbí ìgbèkùn,
Tí ó wá rí ìtúsílẹ̀,
Àyípadà rere a dé,
Ìfọ̀kàbalẹ̀ á wà,
A bọ lọ́wọ́ ìdarí ọ̀gá,
A bọ nínú wàhálà ọ̀gá àti àwọn tí ó kó sódì,
A le gbèrò fúnra rẹ,
A ṣí le tẹ́lẹ̀ ìlànà tó fẹ́,
Lọ́kàn ara rẹ,
Yàtọ̀ sí gbà tó wà làbẹ́ ìtọ́ni amúnísìn,
Bó tilẹ̀ jẹ́ pé òmìnira dára,
Gbogbo ẹ̀dà lo fẹ́ràn ẹ,
Ṣùgbọ́n ọ̀pọ́ òmìnira,
Lò n yọrí sí omi ìnira,
Fáwọn to gb'mìnira,
Ẹ wo orílè èdè Nàìjíríà,
A lòmíràn òṣèlú,
Ṣùgbọ́n abẹ ààbò amúnísìn la wà nínú okòwò,
Bẹ́ẹ̀ náà ni nínú àṣà, nínú ètò ẹ̀kọ́,
Ètò òṣèlú táa láa ni òmìnira rẹ̀,
Ìlànà òṣèlú amúnísìn náà la tún si n tẹ́lẹ̀,
Kí ló ṣe àwa ènìyàn aláwò dúdú,
Ṣe a kò le ronú fúnra wa ni?
Ẹ jẹ ki gbogbo àwa ọmọ orílè èdè Nàìjíríà àti gbogbo orílẹ̀ aláwò dúdú náà já fún ètò wa lọ́wọ́ àwọn tí a fi ṣe olórí,
Ẹ jẹ́ ká bọ àjàgà àwọn funfun sílè,
Ká mohun tí ṣe tiwa ṣe,
Dúdú làṣà, dúdú lẹ̀sìn, dúdú létó òṣèlú kí àwọn amúnísìn tó dé,
Kí ló wá dé tesin wa fọmọ tí ẹ̀ sílè tí n pọnmọ olọmọ.
Mo rọ gbogbo ọmọ orílè èdè Nàìjíríà àti orílẹ̀ aláwò dúdú ti o kú kí a gba ara lọ́wọ́ amúnísìn kí òmíràn má bá di omi ìnira mo wa lọ́wọ́.....
#Èdùmàrè jẹ́ kí àlàáfíà jọba ní gbogbo orilẹ̀ èdè aláwò dúdú, kí a le jọ lá gbéga papọ̀.....
Inú mi dùn pé ilé aláwò dúdú ni mo ti wá
#ìwọ ń kọ?
Ìfẹ́
Ẹyín féràn ẹnu,ofi ṣe ilé,
Irun féràn orí ,ofi ṣe ilé,
Ìràwò òwúrò tèmi nìkan,
Olólùfẹ́ mi,
Nínú aba ayé yìí
Ẹkuro emi mi alabaku ẹwa rẹ,
Ọrọ ìfẹ́ yi n yimi
Mo ni mi o nífẹ̀ẹ́ mon,
Ife ìwọ olólùfẹ́ gbokan mi,
Ìwo ni nkan rere ti o sele sì,
Mo mọ ẹ ìmò mi lékún,
Mo mọ ẹ ó jẹ kí mọ àǹfààní ohun tí ẹdua fún tí mo fi lè ṣe ọmọ aráyé lore...
Mo nife re...
Èyí wa fín àwọn olólùfẹ́ láti fi ranse sí olólùfẹ́ wọn
Friday, 19 August 2016
Aṣọ wíwò
Aṣọ wíwọ̀
Èèyàn lèyí ni àbí wèrè?
Asínwín lèyí ni àbí abugije?
Ṣé aṣọ lèyí abi kini?
Ha! Ayé tí bàjé,
Gbogbo ọmọ adáríhunrun tí sọ àṣà nù,
A gbé òmíràn,
A fi aṣọ sílè láìwọ̀,
A sọ ìhòòhò rí rìn di ohun gidi,
A rìn ìhòòhò nítorí oge,
Kilode tí á lé wọṣọ iyì,
Taa dáyé bá,
Bí bùbá, sooro, agbádá, kijipa àti bẹẹ bẹẹ lọ,
Aṣọ ilé bàbá wa,
A kì í wọ aṣọ ajòjì,
Ká rí bí ọmọ ìbílẹ̀,
Kí ọmọge wọ bùbá àti ìró,
Kóya gèlè náà haha,
Kó fìborùn lee,
Kó fì ìlèkè iyùn tàbí ṣegi sọrùn,
Ṣùgbọ́n ayé tí di rúdurùdu,
Gbogbo aṣọ tí buyi kún ènìyàn tí di ohun àpati,
bùbá, sọọrọ àti fìlà,
Kii se ohun tí ọkùnrin ń wọ mọ,
Bí ẹlòmíràn de fìlà jáde, kò ni rántí mú wálé,
Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọmọ ode òní ni ó mọ Ṣòkòtò kènbè, fúntan,
Bórókún dìmú débi tí wọn yóò mọ,
Fìlà ìkòrì, lábànkádà, òrígí àti sọgọ,
ẸDákun ẹ̀jẹ̀ ká ronúpìwàdà, ká gbe àṣà àti ìṣe tí ó jẹ tiwa lárugẹ......
Ásà wa kò ní parun ooooooo
EwaEdeYoruba
Thursday, 18 August 2016
Ìtẹ́lọ́rùn
Ìtẹ́lọ́rùn
Ìtẹ́lọ́rùn ni baba ìwà,
Ìtẹ́lọ́rùn ṣe pàtàkì fọ́mọ adamọ,
Ìtẹ́lọ́rùn ṣe kókó,
A gbọdọ̀ ni ìtẹ́lọ́rùn,
Kí a le rí ayé gbé,
Kí a le gbáyé ìrọ̀rùn,
Aìní ni ìtẹ́lọ́rùn le mú ni jalè,
Bí ohun tí a ni kò bá tó wa,
Aìní ìtẹ́lọ́rùn ni mú nisẹ ṣìná,
Ìyàwó rere wà nílè,
Ṣùgbọ́n ojú kòkòrò o je ké gbádùn,
Ìwo ìyàwó ọkọ rere wà nílè ṣùgbọ́n ojú kòkòrò o je ki o gbádùn,
Aṣẹ̀yìnwá àṣẹ̀yìnbọ̀,
Ṣìná kó ọ sìnà,
Àgbèrè gba gbogbo èrè iṣẹ́ ẹ,
Aìní ìtẹ́lọ́rùn ló mú èṣù dẹni ilẹ̀,
Ẹ̀jẹ̀ ká ní ìtẹ́lọ́rùn nínú gbogbo idáwọ́le wa,
Ẹ̀jẹ̀ kí ìtẹ́lọ́rùn jẹ́ àkọmọ̀nà wa..
#Ìtẹ́lọ́rùnṣepàtàkì.
Ìfẹ́ láàárín ara wa
Ìfẹ́ dùn bí a bá pàdé oní tí wá,
Ìfẹ́ jẹ́ òhun tí ó má ń ṣẹlẹ̀ láàrin àwọn ènìyàn,
Obìnrin sí ọkùnrin,
Ìyá sí ọmọ,
Bàbá sí ọmọ,
Ọkọ sí ìyàwó,
Ìlú sí ìlú,
Orílẹ̀ èdè sí orílè èdè,
Yálà o dúdú tàbí o pupa,
Eje ká nífẹ̀ẹ́ ara wa.
Ìwo ìyàwó nífẹ̀ẹ́ ọkọ rẹ,
Bàbá àti ìyá ẹ̀ fẹ́ràn gbogbo àwọn ọmọ yín dọ́gba,
Ìwo oga fẹ́ràn ọmọ ìṣe rẹ dáradára,
Ìwo ọmọ ìṣe mọn jẹ oga rẹ lẹsẹ.
Ibi tí ìfẹ́ bá wà,
Ayò, ìdùnnú, ìgbéga, orire kìí jìnà sí bẹ,
Eje ká nífẹ̀ẹ́ ara wa,
Ìfẹ́ dùn ó dára ó ṣì dùn ju oyin lọ.....
Oríkì Ẹ̀rìn Òsun
Ọmọ eléwé ladogba òróró maro,
Ẹ̀rìn wagunwagun
Ewá w'Ẹ̀rìn logun eniti yíò wá Ẹ̀rìn logun kowa àpò ide kolowa ọfà,
Bàbá kòníbon ajíperin nílé,
karo ń lè mọ wọn lójú ogun ẹni Ẹ̀rìn mọ jẹ́ ta l'ọfà tikoku titi ọjọ́ ale afori wowe lobisu Ẹ̀rìn mọ jẹ́ lọmọ
Igi kan igi kan toya dina l'Ẹ̀rìn,
Nipopo olowe koje ki ọmọ elẸ̀rìn,
oroko kòjé kí Ìwòfà elẸ̀rìn orodò,
Ènìyàn mélòó nani yio gegi oro naa,
Olowe wọn ní kí wọn wá,
Abuké méje,
Arọ méje,
Adití méje,
Abuké ngegi lọ apá kan ń dùn karara,
Apá kan ń dùn kororo,
kinni kan ndun winrinwinrin níkùn igi,
oro naa ja nipopo olowe arara ngegi lọ apá kan ń dùn karara, Apá kan ń dùn kororo,
kinni kan ndun winrinwinrin níkùn igi arara base dùn le lomori wogbo, Owadi elékẹta ototo adití tí kò gbó t'ayé tí kò gbó tọrùn sebi oun logegi ọ̀rọ̀ náà nipopo olowe,
kinni wọn ba nínú igi wọn ba osahin wọn ba ọkà bàbà ìbọn oje eku eyan tokanrin nílé tápà nílé ọmọ afowuro dáná kúlíkúlí....